Godfatherism: Ṣé ọ̀rọ̀ bàbá ìsàlẹ̀ nínú òṣèlú lè dópìn bí El-Rufai ṣe sọ?

Lẹ́yin ti Gomina Ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai ni awọn ara ipinlẹ Eko le yọwọ awọn baba isalẹ kuro ninu oṣelu Ipinlẹ Eko, onimọ kan, Ọjọgbọn Tunde Fatunde ti ṣe alaye bi iru igbesẹ yii ṣe le yọri si rere.
Ọjọgbọn naa to jẹ olukọ ni ile iwe fasiti Ipinlẹ Eko ni bo tilẹ jẹ pe oju bọrọ ko ṣee gbọmọ lọwọ ekurọ nitori owo yanturu ti wọn n na lori oṣelu ni orilẹede Naijiria, oun to ṣeeṣe ni.
Ọjọgbọn Fatunde sọ fun BBC Yoruba wi pe, El-Rufai gan to n bẹnu atẹ lu ọrọ baba isalẹ ni oṣelu, baba isalẹ lo ran an lọwọ lati denu oṣelu, ati wi pe, ọrọ naa kii ṣe ti Ipinlẹ Eko nikan.

Oríṣun àwòrán, Tunde Fatunde
Ni Ipinlẹ Eko, ọpọ ni o ti n fẹsun kan gomina Ipinlẹ naa nigba kan ri, Oloye Bola Tinubu wipe oun ni baba isalẹ gbogbo gomina to ti de ipo naa lati igba to ti kuro ni ijọba.

Oríṣun àwòrán, APC
Bẹẹ si ni iroyin kan nigba ti Gomina Ipinlẹ Imo, Rochas Okorocha fa ana rẹ silẹ wipe oun ni oun ti lẹyin. Ko fi pamọ wipe oun ni baba isalẹ rẹ.

Ni Ipinlẹ Delta, iroyin fẹsun kan gomina Ipinlẹ naa Ifeanyi Okowa wipe, gomina Ipinlẹ naa nigba kan ri, James Ibori ni baba isalẹ rẹ.

Àwọn ọna ti ọjọgbọn Fatunde ro pe Naijiria fi le yọ ọwọ awọn baba isalẹ ninu oṣelu ree:
1. Eto ẹkọ
Ninu ọrọ rẹ, ọjọgbọn naa ni owo ti orilẹede Naijiria n na si eto ẹkọ to le ro awọn ọmọ Naijiria lagbara ti kere ju.
O ni, " Eni to ba ran ni niṣẹ laa bẹru ni ọrọ baba isalẹ. To ba ti ọ lẹyin lati de ipo tan, o gbọdọ san owo pupọ lati san an fun un pada. Owo yii si re, owo ilu ni, eyi to yẹ ki a na si mimu igbe aye idẹrun ba ara ilu. Ti eto ẹkọ ko ba yanranti, ọrọ baba isalẹ ko le tan ninu oṣelu."
2. Awọn oninu 're gbọdọ fọwọsowọpọ
Ọjọgbọn ni ti ọdọ oloṣelu to fẹ yii ọrọ oṣelu Naijiria pada si rere ba fẹ de ipo lai fi ti awọn baba isalẹ ṣe, ẹni bẹẹ gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu awọn to ni ọkan bii tirẹ.
O ni, "Mimu ayipada de ba bi a ṣe n ṣe oṣelu ni Naijiria kii ṣe oun ti ẹnikan ṣoṣo le ṣe. A gbọdọ gba ọwọjọ ṣe ni."












