Abuja Protest: À ń ṣe ìwádìí lórí àwọn obìnrin tí wọn mú nítorí aso péńpé

Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fẹ̀sì lórí ìfẹ̀honu han tí awọn kan ń ṣe lárọ satide oni lóri mímú ti àwọn ọlọpàá mu awọn obinrin ti wọn ni wọn wọ aṣọ pénpé lọ si ode ijo ní ìlú Abuja.
Usman Umar to jẹ kọmisọna ajọ ọlọpàá FCT sọ pe àwọn ko ni jọkọ fọwọleran lóri ọ̀rọ̀ náà àti pé àwọn yoo tusu de isalẹ ikoko pẹlu'ajo tó n dabo bo ayika nilu Abuja láti mọ idi ti wọn fi ń mu àwọn olbinrin satimọle.
"A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lóri ọ̀rọ̀ naáà à ó mu ẹni náà a ó sì fi jofin"

Oríṣun àwòrán, Twitter
Àwọn aja fẹtọ ọmọ ènìyàn ti gbà ìgboro pẹ̀lú ìfẹhonu han nílu Abuja ti ṣe olú-ìlú orilẹ̀-èdè naijiria lóri ọ̀rọ̀ bi ọlọpàá ṣe ń mú àwọn obinrin sátìmọle, wọn a tún dóju tiwọn nítori pé wọn wọ aṣọ pénpé lo si ilé ijo tàbi ilé ìtura.
Awọn afẹhonu han ọhun tí wọn wọ aṣọ dúdú bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn láti Old Parade ground nílu Abuja lọ si ile iṣẹ ọlọpàá FCT.
Bakan náà ni àwọn afẹhonu han náà kó akole orisirisi lọ́wọ́ ti wọn kọ ọ̀rọ̀ bíi "obinrin ni mi, bó ba ṣe wumi ni mo ṣe le múrà"
Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọbinrin ti àwọn ọlọpàá mú náà sàlàyé pe wọn fi ipá ba àwọn lòpọ̀ nígbà ti àwọn wà ni ahamọ.

Ní ti àwọn ajàfẹto, wọn ni mímu wọn si atimọle kìí ṣe ǹkan ti o ba ofin mú àti pé wọn ń fi ọwọ pa ẹtọ àwọn obinrin náà lóju ni

Ọkan nínú àwọn to jáde wa ni ajàfẹtọ obinrin Aisha Yesufu, ó sàlàye pé ìdí ti òun fi jáde wa ni pé o ti tó gẹ

" O dà bi ẹni pe ti ènìyàn ba ti jẹ obinrin, ọ̀ràn ní oluwa rẹ̀ dá, wọn kan máà ṣe obinrin báṣubaṣu, obinrin a maa rìn lọ lọ́san gangan, ọlọpàá a si jú ènìyàn si inu ọkọ̀, a wá ń gbọ pe àwọn ènìyàn ti wọn ń mu yìí, àwọn ọlọpàá a maa fi ipá ba wọn lò pọ̀ ki wọn to tú wọn silẹ̀. Aisha ló s]ọ èyí di mímọ.

Obinrin míràn to tún jáde fún ìfẹhonu han náà sọpe "ọ̀rs yìí ti toju ṣú wa" ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ si obinrin lórill -èdè Naijiria kò dára, a fẹ kí ńkan yí pada, à fẹ ki ọlọpàá máa dáàbò bo obinrin.
" A o le rin a ò lé rimu mi, a o le wọṣọ, a lé lọ si ilé ijo, ọlọpaáà to yẹ ko dáàbò bò wá àwọn gan-an ló ń fipá báwa lòpọ, a fẹ ki àwọn ọmọ Naijiria mọ pe ẹ̀tọ́ obinrin náà ni ẹ̀tọ́ ọmọniyan, kò sí ìyàtọ ninu gbogbo ẹni to ń rin ni títì"













