Yomi Shogunle di èro Nkalagu lórí ọ̀rọ̀ tó sọ lórí Twitter

Yomi Shogunle

Oríṣun àwòrán, Yomi Shogunle/Twitter

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Adari ẹka ileeṣe ọlọpaa to n boju to ẹhonu ara ilu, Yomi Shogunle ti di ero Nkalagu ni Ipinlẹ Ebonyi, nibi ti wọn gbe lọ si nigba ti wọń yọ kuro nipo ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Abuja.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Frank Mba sọ fun BBC Yoruba wipe ootọ ni pe wọn ti gbe Shogunlẹ lọ Nkalagu nibi ti yoo ti maa ṣe ọga ọlọpaa (area commander) ni ẹkun naa.

Mba sọ, "Wipe wọn ti gbe lọ Ebonyi kii ṣe ọrọ to le pupọ nitori wipe ipo nla naa ni wọn gbe lọ si ni Nkalagu."

Shogunlẹ ti ipo rẹ gẹgẹ bii ọlọpaa jẹ igbakeji kọmiṣọna (ACP), fesi lọna to bi awọn ara ilu ninu nigba ti iroyin jade nipa awọn obinrin ti awọn ọlọpaa kan mu lori ẹsun ṣiṣẹ owo nọbi ni Abuja ti wọn si fipa bawọn lọ po.

O ni aruwo lasan ni awọn ara ilu n pa lori ọrọ awọn ti ọlọpaa mu naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Àkọlé fídíò, ọ̀gá ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí SARS

Ṣugbọn kii ṣe igba akọkọ ree ti Shogunle yoo fẹnu kọ lori Twitter. Awọn ara ilu ti fẹjọ rẹ sun awọn alaṣẹ ọlọpaa titi ṣugbọn ko dẹkun lati maa kọ ọrọ ti yoo bi aye ninu lori Twitter.

Awọn igba miiran ti Shogunle kọ ọrọ to bi ọmọ Naijiria ninu lori Twitter

Oun to kọ sọri atẹ Twitter rẹ ree nipa Segun Awosanya ti gbogbo eniyan mọ si Segalink, ajafẹtọ kan ti o maa n gba ọpọ ọdọ silẹ nigba ti ọlọpaa ba mu wọn lọna aitọ.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Shogunle mu inu bi ọpọ ọmọ Naijiria nigba to sọ wipe lati yago fun wahala lọdọ awọn ọlọpaa, ki awọn ara ilu maa gbiyanju lati sọ ede oyinbo 'pidgin' dip ede oyinbo to dan mọran.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

Àkọlé fídíò, Segalink:ìkùnsínú pọ̀ láàrin àwọn agbófinró bẹ́ẹ̀ wọn kò ni agbẹnusọ