Babatunde Fashola: Àwọn alájẹbánu gba owó fún isẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná

Oríṣun àwòrán, WIKIPEDIA
Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, SERAP ti ri iwe gba lati ọwọ Minisita fun ọrọ isẹ ati ile gbigbe, Babatunde Fashola to fi orukọ awọn ile -ise to gba owo, amọ ti wọn ko lati se isẹ naa.
Ninu atẹjade ti Ajọ SERAP gbe lede, Kolawole Oluwadare ni Fashola fi sọwọ si wọn gẹgẹ bi ilana ofin to rọ mọ ‘Information Act’ ti orilẹede Naijiria to fọwọ si wi pe ti ọmọ Naijiria ba bere iwadii kikun lori isẹlẹ, wọn gbọdọ fi lede.
Iwe ti wọn fi ransẹ si wọn naa fihan wipe "Pow Technologies Limited" to kalẹ si ilu Abuja kọ lati ko irinsẹ ti wọn fi n se ayẹwo ina ninu ile ati kaakiri ile isẹ NAPTIN ti wọn san miliọnu mọkandinlogoji fun ninu miliọnu mẹtadinlaadọrun, amọ ti wọn kọ lati ko irinsẹ naa wa.
Gẹgẹ bi ile isẹ to n risi ọrọ ile gbigbe ati isẹ se sọ, ọdun 2014 ni wọn ti gbe isẹ naa fun wọn, ti o si jẹ pe mẹtala ninu mọkandinlogun isẹ ti wọn gba ni wọn se.
Ajọ SERAP naa ni awọn ni asẹ lati ri iwe naa nitori asẹ ti awọn gba lati ile ẹjọ giga ni ilu Eko ni Osu Keji, ọdun 2019.









