Eid-Al-Fitr: ìjọba Nàìjíríà ti kéde ìsinmi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú

àwọn musulumi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Eid-Al-Fitr: ìjọba Nàìjíríà ti kéde ìsinmi lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun àti Ọjọ́rú

Ile iṣe ijọba apapọ to n risi ọrọ abẹle Naijiria kede isinmi fawọn eniyan.

Wọn kede pe ko ni si iṣẹ ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrin, oṣu yii ati ni ọjọ karun un, Ọjọru ọsẹ yii.

Georgina Ehuriah to jẹ akọwe agba ajọ naa lo kede isinmi yii lorukọ ijọba apapọ.

Bakan naa ni akọwe agba yii parọwa fawọn ẹlẹsin Islam pe ki wọn ma yọ ayọ ti ko yẹ lasiko yii.

O ni ki wọn lepa ifẹ, alaafia àti iṣokan fun ogo Naijiria lapapọ.

Àkọlé fídíò, 'Mo ń ṣa ike jọ láti san owó ilé iwé ọmọ mẹ́ta'

Ehuriah sọrọ lori ifarada ki idagbasoke le de ba Naijiria lasiko iṣejọba aarẹ Buhari tuntun yii.

Aawẹ Ramadan jẹ ọkan lara opo marun un ẹsin Islam.

Ehuriah parọwa pé ki wọn sa fun ọrọ ikorira ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu aarẹ Buhari ninu iṣejọba tuntunt yii.

Ile iṣẹ ijọba apapọ yii tun paṣẹ pe ki awọn oṣ\iṣẹ eleto aabo Naijiria fọwọsowọpọ ṣiṣẹ papọ lasiko ọdun itunnu aawẹ yii.

Àkọlé fídíò, RAMADAN: Onímọ̀ ẹ̀sin sọ nípa isẹ́ láádá àti làádà