Sẹ́nétọ̀ Dino Melaye kéde láti dupò gómìnà Kogi

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye
Sẹ́nétọ̀ to n ṣoju ẹkun Ila Oorun ipinlẹ Kogi nile igbimọ aṣofin agba, Dino Melaye ti kede pe oun yoo du ipo gomina ipinlẹ Kogi ninu idibo oṣu kọkanla.
Sẹnetọ Dino kede eyi ninu fidio to fi sita loju opo instagram rẹ pe oun yoo fidi gomina Yahaya Bello to wa lori alefa bayii janlẹ ninu idibo to n bọ̀.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
Lọjọ abamẹta ni Dino kede eyi ni ẹkun idibo rẹ ni Ayetoro ipinlẹ Kogi nibi ti ba awọn ọmọ ẹgbẹ Peoples Democratic Party pade.
Dino ninu ọrọ̀ rẹ ni ju gbogbo ẹ lọ "mo ti bi Ọlọ̀run leere" yoo si sọ ọ di ṣiṣe fun oun lati di gomina ipinlẹ Kogi.
Eyi n hande pẹlu bi Dino ṣe ṣẹṣẹ wọle gẹgẹ bi sẹnetọ fun igba keji ninu idibo to kọja ti wọn yoo bura wọle fun.










