Neymar: Agbábọ́ọ̀lù Brazil kọ ẹ̀sùn ìfipábanilòpọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbajugbaja agbabọọlu orilẹede Brazil, Neymar ti ni irọ ni ẹsun ti wọn fi kan pe oun fipa ba obinrin kan lo in Paris.
Gẹgẹ bi iroyin to wa latọdọ ọlọpaa, obinrin naa fẹsun kan pe lasiko tawọn mejeeji pade ara wọn ni olu ilu orilẹede France, Paris lẹyin ti wọn ti jọ n sọrọ lori ayelujara ni ṣẹlẹ naa waye nile itura tawọn de si.
Ni Paris ni Neymar ti gba bọọlu fun ikọ agbabọọlu Paris St-Germain (PSG).
Ẹwẹ, agbẹnusọ fun Neymar fi ọrọ sita pe agbabọọlu naa fi gbogbo ẹnu kọ ẹsun naa pe oun ko mọ nipa rẹ.
Neymar ti wa ni orilẹede Brazil to n ṣe igbaradi pẹlu ikọ orilẹede naa fun idije Copa América.
Ki ni ẹsun ti wọn fi kan an?
Gẹgẹ bi iwe akọsilẹ to wa lọdọ ọlọpaa, obinrin naa ti wn ko darukọ rẹ pade Neymar loju opo Instagram ti Neymar si dabaa pe ki wọn jọ pade ni Paris.
O ra tikẹti rẹ lati Brazil lọ si France o si gba yara fun ni ile igbafẹ Hotel Sofitel Paris Arc Du Triomphe.
"Nigba ti Neymar de si ile igbafẹ naa ni ọjọ ikẹẹdogun oṣu kẹta, o daju pe o ti mọti yo" gẹgẹ bi obinrin naa ṣe sọ.
Lẹyin ti wọn ọrọ tubi n nubi ati didi mọra ẹni gbagi, o de ibi kan ti ọeọ ti Neymar n gbe wa le to si wa fi ipa ba obinrin naa lajoṣepọ lọna ti ko nifẹ si". Ohun ti iwe akọsilẹ ọlọpaa sọ ree.
Ki ni esi Neymar?
Lyin ti ẹsun yii gbilẹ kan, agbẹnusọ agbabọọlu naa fi ọrọ sita pe: " gbogbo ẹnu la fi kọ ẹsun yii ailẹsẹ nlẹ yii ati bi awọn oniroyin ṣe fẹ ẹ loju lọna odi."
Baba agbabọọlu naa, Neymar dos Santos sọ lori ẹrọ amohunmaworan Band TV ni Brazil pe "panpẹ gbaa ni."
Njẹ Neymar ti ṣe tan fun Copa América?
Wn ti yọ ọmọ ọdun mẹtadinlọgbọn agbabọọlu ọwọ iwaju naa gẹgẹ bi akọgun ẹgbẹ agbabọọlu Brazil lori ọrọ to ni ṣe pẹlu jijẹ iya ẹṣẹ kan laipẹ.
Awọn alaṣẹ agbabọọlu France paṣẹ ko ma kopa ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta tori pe o gba ololufẹ ere bọọlu kan lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu Rennes na PSG bolẹ ninu aṣekagba idije Coup de France loṣu to kọja.
bakan naa ni wọn ti ba a wi fun awọn aṣemaṣe mii.
Neymar ni lati dawọ igbaradi durọ lọjọ aje nigba to fi orokun ṣeṣe bi o tilẹ jẹ pe ko pọ pupọ.














