Anthony Joshua vs Andy Ruiz: Págà! Andy Ruiz já ìràwọ̀ Anthony Joshua

Joshua, Ruiz ati adari ija

Oríṣun àwòrán, Al Bello

Àkọlé àwòrán, Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Ruiz fi ẹsẹ kan Joshua mọlẹ lai le dide.

Erongba abẹṣẹ ku bi ojo ọmọ ile Gẹẹsi ati Naijiria, Anthony Joshua, lati fi irawọ kun irawọ rẹ nilẹ Amẹrika lo ti ja si pabo.

Joshua to ti gba ami ẹyẹ to ga ju lagbo ere idaraya ẹṣẹ kikan lagbaye lẹẹmẹta ọtọọtọ fidirẹmi, to si jẹ iya ajẹbolori lọwọ ẹni ti ko to o, Andy Ruiz lasiko ti wọn koju ara wọn ni Madison Square Garden lọjọ Abamẹta.

Ẹẹmẹrin ọtọọtọ ni Ruiz fi ẹsẹ kan Joshua mọlẹ lai le dide. Eyi lo si mu ko gba ami ẹyẹ nla mẹta, World Boxing Association, International Boxing Federation and World Boxing Organization.

Bawo lọrọ ṣe waye?

Ninu ija alagbara naa, Joshua lo kọkọ fi ẹyin Ruiz lelẹ ni ipele kẹta ija wọn, amọ ko pẹ ni Ruiz gba ani ẹṣẹ kan ni iwaju ori, eyi to mu ki oju Joshua pooyi ran-in. Igba ti yoo fi bọ sipo pada, Ruiz tun ti fi ẹṣẹ mi doju rẹ bolẹ.

Àkọlé fídíò, Sekinat Quadri ọmọ ọdun meje ajẹsẹ to fẹ dabi Anthony Joshua

Eyi mu ki ariwo sọ gee laarin awọn oluworan bi ẹgbẹrun mọkandinlogun to wa ni papa ija naa. Kayeefi!

Anthony Joshua

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ija naa gan an kii ṣe ti Ruiz. Ọsẹ mẹfa sẹyin lo gba lati ja lẹyin ti ẹni to yẹ ki oun ati Joshua jọ ja, Jarrell Miller kuna ayẹwo oogun oloro ti wọn ṣe fun un.

Igba ti ija wọn naa wọ ipele keje, Joshua tun balẹ gbi nigba ti ẹṣẹ ba a. Ko tii pe iṣẹju kan, Joshua tun ṣubu yakata lai le dide.

Ka to ṣẹju pẹ, adari ija ti fọn feere poo! Ija pari! Joshua ti fidirẹmi sọwọ alatako ti gbogbo eniyan ti foju eniyan yẹpẹrẹ wo nitori bo ṣe jẹ ẹni sisanra.

Ruiz to jẹ ọmọ orilẹede America ati Mexico, ninu ọrọ to sọ lẹyin idije naa sọ pe "ala mi ti wa si imuṣẹ bayii. Koda, mi o tii gbagbọ pe mo ti mu ala naa ṣẹ.''

Andy Ruiz

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Lati kekere ni wọn ti maa n fi Ruiz ṣe yẹyẹ nitori bo ṣe sanra.

Lati kekere ni wọn ti maa n fi Ruiz ṣe yẹyẹ nitori bo ṣe sanra, amọ bayii, o ti 'd'oju ti awọn ẹlẹgan, ti ọrọ rẹ si di ẹni ti a ro pe ko le pagọ, to kọ ile alarinrin.'

Bawo ni ọrọ naa ṣe ri lara Anthony Joshua?

Ṣe bi ẹyin naa mọ pe ko ṣẹni ti yoo ṣe, ti ko ni dun.

Amọ Anthony Joshua ti sọ pe 'Haa, akọni ọkunrin lo fidi mi janlẹ. Lara irinajo rẹ naa ni iṣẹgun yii jẹ, ṣugbọn , ao maa wo ibi ti yoo ba a de.''

Oun ni akọni lasiko yii, mo n pada bọ toro-toro.

"Ipadabọ mi yoo dabi ti abijawara bi ẹkun.''

Aṣoju Joshua, Eddie Hearn ti sọ pe oun yoo gbiyanju lati jẹ ki ija mii o waye laarin awọn mejeeji nilu London, ninu oṣu Kọkanla tabi Ikejila.

O ni 'ohun to ṣẹlẹ yii yoo mu irẹwẹsi ba a (Joshua), ṣugbọn, irawọ rẹ yoo pada tan. Eyi wa da lori ti ija mii ba waye laarin wọn, to si bori.''