Wo irin, ọ̀kọ̀, ìbọn àti àdá tí Ogedengbe Agbogungboro fi ń jagun àti àga tó fi ń wo ọ̀tá

Ogedengbe ati awọn ohun ijagun rẹ
Àkọlé fídíò, Ogedemgbe Agbogungboro: Kó tó lọ sójú ogun, ojú rẹ̀ yóò pọ́n bíi ẹ̀jẹ̀

Ogedengbe Agbogungboro: Kó tó lọ sójú ogun, ojú rẹ̀ yóò pọ́n bíi ẹ̀jẹ̀

Ti a ba n sọrọ itan ilẹ Ijesa ati Yoruba lapapọ, itan naa ko le pari lai sọ ipa ribiribi ti akọni ọkunrin kan, Ogedengbe Agbogungboro ko lati gba ilu naa ati ilẹ Yoruba silẹ lọwọ ogun.

Ni aye atijọ, ọkan lara awọn alagbara ti okiki wọn kan pupọ ni akọni ọkunrin naa, to si n ba awọn ologun olokiki bii Basọrun Oluyole nilẹ Ibadan ta kangbọn.

Ọdun 1910 si ni Ogedengbe Agbogungboro jade laye eyi to ti pe ọdún mejilelaadọfa (112) bayii.

Ni ipari osu Keje ọdun 2022, ni awọn idile Ogedengbe Agbogungboro se iranti ọdun mejilelaadọfa naa ti akọni to sẹdasil wọn jade laye.

Idi si ree ti BBC Yoruba fi gba ilu Ilesa lọ, lati wo bi ayẹyẹ iranti naa se waye, ka si wo awọn ohun manigbagbe ti Ogedengbe Agbogungboro se fun il Ijesa ati Yoruba lapapọ.

Itan to rọ mọ ibi ati igbe aye Ogedengbe Agbogungboro:

Nigba to n salaye bi wọn se bi Ogedengbe Agbogungboro fun BBC Yoruba, Oluọdẹ ilu Owode-Itori, Oloye Ojo Elijah ni ifa ti kede saaju nigba ti iya Ogedengbe loyun rẹ pe wọn ko gbọdọ bi ọwọ naa sile baba rẹ.

O ni ile iya rẹ ni Itori ni ki wọn bi Ogedengbe Agbogungboro si nitori pe akọni ọmọ ni.

O si le ni ẹni ọdun mtadinlogun ki Ogedengbe Agbogungboro to maa bẹr si jagun nigba ti ogun bẹrẹ lagbegbe naa.

Agbara to ni yii si lo ni o fi gba ilẹ Ijesha silẹ ati il Yoruba lapapọ lọwọ ogun.

Ogedemgbe Agbogungboro

Oríṣun àwòrán, Ogedemgbe Agbogungboro children

‘Orisarayibi ni orukọ akọni naa, inagijẹ lasan ni Ogedemgbe Agbogungboro’

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, ọkan lara awọn arọmọdọmọ Ogedengbe Agbogungboro, Ọmọọba Tayo Ogedengbe salaye igbe aye baba nla rẹ naa fun wa.

Ọmọọba Ogedengbe ni Owode Itori gan ni ilu Ogedengbe Agbogungboro, itori ija ẹkẹ to maa n ja ni wọn se sọ ni Ogedemgbe.

Orisarayibi gan ni orukọ Ogedengbe Agbogungboro amọ nitori pe o maa n gbe eeyan ni Ogedengbe lati la onitọun mọlẹ lasiko ija ẹkẹ ni wọn fi sọ ni inagijẹ naa.

O fikun pe ọdun mtadinlogun ni akọni naa ti n jija ẹkọ, to si maa n bori ọpọ akọni ọkunrin ninu ija naa eyi to mu ki okiki rẹ pọ kaakiri il Ijesa nigba naa.

“Osu mẹta ni Ogedengbe yoo fi wa ninu ile lati dira ogun, ti ko si ni da si ẹnikẹni.

Oju rẹ yoo pn bii ẹjẹ, yoo si gbe kaun si ẹrẹkẹ kọọkan eyi to fi maa ro awọn oogun rẹ lagbara bii igba ti eeyan ba n saaji batiri.

Ọkan Ijesa si bal pe awọn ni Ogedengbe Agbogungboro lati doju kọ ogun yowu ti wọn ba gbe ti awọn.”

Ogedemgbe Agbogungboro

BBC Yoruba ri ile, ibọn, irin, ọkọ, ada ati Ijokoo ti Ogedengbe Agbogungboro ninu ile rẹ:

Lasiko ayẹyẹ iranti naa ni awọn arọmọdọmọ Ogedengbe Agbogungboro se afihan awọn eroja ti akọni naa lo nigba to wa loke eepẹ.

Lara awọn eroja ijagun Ogedengbe Agbogungboro ta fi oju ri ni irin, ibọn, ọkọ, ada ati aga to fi maa n joko lati wo awọn ọta lati orere nigba ti ogun ba n bọ.

“Ibọn danku ti baba n lo ree, ko to di pe oyinbo ko ibọn Ak47 de, bo si se n jagun niwaju, ni yoo tun maa jagun bọ ni ẹyin.

Ori aga yii naa si lo maa n joko si lati ri awọn ọta to n gbe ogun bọ lati ọkankan nitori ori oke ni ile rẹ wa.

Ogedengbe Agbogungboro jagun ni Ibadan, Igbajọ, kii si se Ilesa nikan lo ti jagun amọ idi ogun Kiriji lo pari ogun jija si.

Awọn ohun eelo Ogedemgbe Agbogungboro

‘Ogedengbe Agbogungboro lo maa n se oogun funra rẹ, ko ni babalawo to n se oogun fun‘

Awọn idile Ogedengbe Agbogungboro tun sọ fun BBC Yoruba pe akọni naa lo maa n fi ọwọ ara rẹ se oogun abẹnu gọngọ to maa n lo lati jagun.

Wọn ni ko ni babalawo to maa n ba se oogun gẹgẹ bii awọn akọni miran.

Bakan naa lo ni awọn iyawo kankan kii ba Ogedengbe Agbogungboro gbe amọ wọn n gbe ni agboole rẹ to wa ni adugbo Anaye nilu Ilesa.

Sugbọn wọn ni inu oko mọlẹbi naa to wa ni Itori ni baba naa n gbe.

Ibọn ti Ogedengbe Agbogungboro lo

‘Ogedengbe Agbogungboro se bẹbẹ fun ilu Ibeju-Lekki’

Bakan naa ni wọn sọ fun BBC Yoruba pe akọni ọkunrin yii tun ni nnkan se pẹlu adugbo Ibeju-Lekki.

Wọn ni ọkunrin naa sisẹ ribiribi nibẹ, ti wọn ko si le gbagbe rẹ titi di oni yii.

Ipari ogun Kiriji ati iku Ogedengbe Agbogungboro lọdun 1910:

Nipari, a ri gbọ pe Ogedengbe Agbogungboro fi ogun jija si yin ogun Kiriji.

Dun 1886 si ni Ogedengbe Agbogungboro fi ọwọ bọ iwe adehun pẹlu awọn oyinbo amunisin ati ilu Ibadan pe ogun naa ti wa sopin.

Koda awọn ọmọ Ogedengbe Agbogungboro gan tun de ibudo ti wọn ti tọwọ bọ iwe adehun lati fi opin si ogun Kiriji nilu Imesi-Ile eyi ti BBC Yoruba naa ko gbẹyin nibẹ.

Awọn ọmọ Ogedengbe Agbogungboro wa seleri pe awọn yoo tun ile baba naa kọ si ti igbalode ko le jẹ ibudo tawọn arinrinajo afẹ yoo maa peju si.