"Nǹkan kò ní rọgbọ, bí ààrẹ tuntun bá wá láti àríwá ní 2023"

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ kan to n ja fun idagbasoke agbegbe Niger Delta, Pan Niger Delta Forum, PANDEF, ti ṣeleri pe awọn ko ni gba ki Aarẹ Naijiira tuntun wa lati Ariwa lọdun to n bọ.
Akọwe apapọ fẹgbẹ naa, Ken Robinson, lo fi ọrọ naa lede lasiko ti awọn adari ẹgbẹ ọhun ṣabẹwo si oludije sipo Aarẹ fẹgbẹ oṣelu SDP, Ọmọọba Adewole Adebayo niluu Abuja.
PANDEF ni awọn ti ṣetan lati ṣa awọn eeyan jọ kaakiri ẹkun Niger Delta lati kọju ija si iyanjẹ ti Ariwa n ṣe si Guusu Naijiria.
Robinson ni ijọba to wa lode yii ko naani awọn ẹya Guusu Naijiria, ati pe mẹrinla ninu awọn adari ileeṣẹ eto abo to wa ni Naijiria ni ẹya Ariwa n dari, nigba ti mẹta pere wa lati Guusu.
Nnkan ko ni rọgbọ ni Naijiria, ti ipo Aarẹ ba tun lọ si ẹkun Ariwa
O fi kun pe meje ninu ipo to ṣe pataki ninu ajọ NNPC ni awọn eeyan Ariwa di mu, nigba ti ẹya Guusu ni mẹrin pere.
O ni “A o ko ara wa jọ ti ipolongo ibo ba ti bẹrẹ, a o si ba awọn ọlọpọlọ pipe ni Ariwa sọrọ.
A jẹ ki wọn mọ pe Aarẹ to n bọ gbọdọ wa lati Guusu.”
“Kii ṣe pe a n dunkooko mọ ẹnikẹni o, amọ a ti ba ọọfisi ijọba orilẹ-ede Denmark sọrọ, to fi mọ ti ilẹ Gẹẹsi.
Ati sọ fun wọn pe nnkan ko ni rọgbọ ni Naijiria, ti ipo Aarẹ ba tun lọ si Ariwa.”
Robonson fi kun pe, ipade ẹgbẹ naa pẹlu awọn oludije sipo Aarẹ lati Guusu ko ṣẹyin afojusun awọn, lati ri pe oludije tootọ lo di Aarẹ lọdun to n bọ.
Ẹwẹ, oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu SDP, Ọmọba Adewole Adebayo sọ pe ipade oun pẹlu ẹgbẹ PANDEF jẹ ọkan lara awọn ọna ti oun fi n ja fun iṣọkan Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ọmọ ọdún méjìdínlógún bómi lọ torí ó fẹ́ dóòlà Màlúù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdọmọkunrin kan ti orukọ rẹ jẹ, Adamu Musa lo ti padanu ẹmi rẹ nigbati o gbiyanju lati dola ẹmi ọkan lara awọn maluu to da kiri.
Ijọba ibilẹ Buji ni ipinlẹ Jigawa ni isẹlẹ naa ti waye.
Oṣojumikoro ni iṣẹlẹ naa lo waye ni ọjọ Satide ni agbegbe Unguwar niluu Buji.
O ni ọdọmọkunrin naa, ẹni ọdun mejidinlogun padanu ẹmi rẹ lẹyin to bọ sinu omi adagun lati dola ẹmi maluu to yọ sinu odo naa nigba ti o da awọn Maluu kiri.
Agbẹnusọ ajọ NSCDC, CSC Adamu Shehu ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Musa ni: “ajọ naa gbọ si iroyin ọhun to waye ni deede aago mẹta ọsan, pe arakunrin kan ko awọn maluu rẹ lọ si oko lati lọ jeun.
“Sugbọn ọkan lara awọn maluu bọ sinu odo adagun to wa ni tosi ibi oko to ti fẹran jẹko.
“ Kete ti arakunrin naa ri pe maluu oun ti bọ sinu odo adagun ni o gbinyanju lati dola ẹmi maluu naa sugbọn oun gan lo ba isẹlẹ naa lọ.”
Shehu fikun pe arọ ọjọ aiku ni wọn ri oku ọkunrin naa.
O ni isẹ ti bẹrẹ lati ṣe ayẹwo lori oku naa, ki wọn to gbe fun awọn obi rẹ lati sin.















