Iléẹjọ́ gíga Kenya fìdí ìbò tó gbé William Ruto wọlé múlẹ̀

Oríṣun àwòrán, William Ruto
Ileẹjọ to ga ju lorilẹede Kenya ti kede William Ruto gẹgẹ bi aarẹ tuntun to jawe olubori ninu ibo naa.
Bakan naa lo tun wọgile ẹjọ ti alatako rẹ, Raila Odinga, to lulẹ ninu ibo aarẹ, gbe wa si ile ẹjọ lori esi idibo aarẹ naa.
Raila Odinga ati awọn miiran tako ibo to gbe William Ruto wọle, ti wọn si kesi ileẹjọ pe ko yii esi ibo to gbe aarẹ tuntun naa wọle pada.
Lọjọ kẹẹdogun osu kẹjọ ọdun 2022, ni ajọ eleto idibo lorilẹede Kenya (IEBC) kede William Ruto gẹgẹ bi olubori ibo aarẹ naa.
Ọjọ marun un si ni wọn fi ṣe ayẹwo esi ibo naa to waye lọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ, ki wọn to kede esi ibo naa.
Ruto, ẹni ọdun marundinlọgọta lewaju Raila Odinga pẹlu ibo miliọnu meje o le ẹgbẹrun mẹrindinlọgọsan ati mọkanlelogoje, 7, 176, 141
Ẹbẹ mẹjọ ni ileẹjọ tẹwọgba lọwọ Raila Odinga, ti wọn si wọgile gbogbo ẹ patapata.
Adajọ agba nilẹ Kenya, Martha, ni pupọ lara awọn iwe ti awọn olupẹjọ fi sọwọ sile ẹjọ naa lo jẹ ayederu.
Martha wa kede pe ko si ẹri to yanranti pe wọn tọwọ bọ esi ibo naa .
Koome ni Aarẹ tuntun William Ruto ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan ati pe esi idibo to gbe wọle pegede.















