Ọlọ́pàá, Amotekun, Fijilanté yawọ inú igbó l‘Ogun, wọ́n dóòlà èèyàn mẹ́ta, mú afurasí ajinigbé mẹ́ta

Afurasí ajínígbé mẹ́ta jí èèyàn mẹ́ta gbé l‘Ogun, ṣe méjì léṣe

Awọn afurasi ajinigbe mẹta

Oríṣun àwòrán, Ogun state police

Ileesẹ ọlọpaa ti kede pe ọwọ oun ti tẹ afurasi ajinigbe mẹta ninu igbo nla kan lopopona Imeko-Iwoye si Ketu.

Bakan naa ni wọn doola awọn eeyan mẹta tawọn afurasi ajinigbe ọhun ji gbe wa sinu igbo naa.

Awọn afurasi ajinigbe naa ni Aliu Abubakar, tii se ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ati Umaru Tujur, tii se ẹni ọdun mẹrinlelogun.

Afurasi kẹta ni Yau Isah tii se ẹni ọdun mẹẹdọgbọn.

Ọwọ ọlọpaa tẹ awọn afurasi ajinigbe naa nigba ti agọ ọlọpaa Imeko gba ipe kan lọdọ araalu.

Awa ọlọpaa, ọdẹ ibilẹ ati fijilante la doola èèyàn mẹta lọwọ ajinigbe

Awọn ọlọ̀paa naa gbọ pe awọn afurasi ajinigbe, ti wọn lo to to mẹjọ niye pẹlu ohun ija oloro lọwọ wọn, ti gbegi da oju ọna Termac si Iwoye, ti wọn si n yinbọn soke lakọ lakọ.

Awọn afurasi naa ni wọn lo se Bode Ogunleye ati Muhammad Basa lese, ti wọn si ji Alhaji Fatai Abdulsalam, Dauda Orelope and Rafiu Isah gbe lọ.

Ni kete tawọn ọlọpaa si gba ipe itara naa, ni ọga ọlọpaa to wa ni Imeko ko awọn osisẹ rẹ pẹlu awọn Maotekun lọ sibẹ.

Bakan naa ni atẹjade ọlọpaa naa ni awọn ọdẹ ibilẹ, Fijilante atawọn ọdọ Yoruba ati Fulani ya wọnu igbo naa lati wa ajinigbe atawọn eeyan ti wn ji gbe.

Nigba ti ọwọ yii dun wọn, awọn ajinigbe ọhun fi awọn eeyan ti wọn ji gbe silẹ pẹlu ọkada kan ti ko ni nọmba lara silẹ.

Awọn afurasi ajinigbe mẹta

Ọlọpaa ri kọkọrọ ọkada ati ada mẹta gba lọwọ lara awọn afurasi ajinigbe

Ileesẹ ọlọpaa ni awọn ti doola ẹmi awọn eeyan ti wọn ji gba naa lai fi ara pa, ti wọn si tun tẹsiwaju lati se awari ibi ti awọn ajinigbe ọhun sa lọ.

Lẹyin o rẹyin, ileesẹ ọlọpaa ni wọn ri awọn afurasi ajinigbe naa ni ibuba ti wọn sa lọ si.

Lara awọn ohun tawọn agbofinro ri lara awọn afurasi ajinigbe naa ni kọkọrọ ọkada pẹlu ada mẹta.

Kọmisana ọlọpaa ti wa pasẹ pe ki wọn gbe awọn afurasi ajinigbe mẹtẹẹta naa lọ si ẹka to n gbogun ti iwa ijinigbe to wa labẹ ẹka ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ.

Àwọn agbébọn palẹ̀mọ́ ogójì èèyàn lásìkò irún Jimoh ní Zamfara

Aworan awọn agbebọn

Oríṣun àwòrán, others

Pẹlu ibẹru ati ifoya ni awọn olugbe agbegbe Zugu ni ijọba ibilẹ Bukuyum ni ipinlẹ Zamfara fi n gbe lati bi ọjọ diẹ sẹyin.

Lẹyin ti awọn adijunjale ṣe ikọlu si mosalasi Juma nigba ti wọn bẹrẹ irun kiki, ti wọn si ji awọn eeyan gbe lọ.

Iroyin to tẹ ileeṣẹ BBC lọwọ se afihan pe awọn adigunjale ṣe ikọlu si mosalasi naa ni dede ago kan si ago kan abọ, ti wọn si ji ọpọlọpọ eeyan gbe lọ.

Lafikun, awọn adijunjale naa tun yawọ inu ọja, ti wọn si awọn eeyan miiran lọ.

Apapọ awọn eeyan ti wọn jigbe lọ ni igbagbọ wa pe wọn jẹ mẹrinlelogoji

Osejumikoro ati olugbe agbegbe naa ni yato si awọn eeyan ti wọn gbe, awọn adigunjale naa tun gbe ounjẹ ati nkan miiran lọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, sugbọn wọn ko kede eye eeyan ti awọn ajinigbe naa gbe lọ.

“Awọn adigunjale gbe ounjẹ, foonu awọn eeeyan ati bẹbẹlọ.”

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko ti gbọ ohun kohun lati ọdọ awọn ajinigbe naa sugbọn iwadi n lọ lori iṣẹlẹ naa.

“Wọn ti wa ni aimọye igba , ẹlẹkẹrin re.''

Awọn olugbe agbegbe naa ni awọn adigunjale naa fi ibọn wọn pamọ si abẹ asọ wọn ki wọn wọ ninu mosalasi nigba ti imamu fẹ bẹrẹ wasi jimọ.

Ọkan lara awọn to wa nibi iṣẹlẹ naa ni ki n ṣe igba akọkọ re ti awọn adigunjale yoo ṣe ikọlu si agbegbe naa.

“Wọn ti wa ni aimọye igba , ẹlẹkẹrin re.''

Lẹyin ti wọn gbe gbogbo awọn eeyan ni awọn ọlọpaa de.

Osejumikoro miiran ni awọn afurasi agbebọn naa ni awọn ko mọ pe wọn gbe ibọn dani, ti awọn si ro boya olujọsin ni wọn.

“Ẹnikẹni ko ri pe wọn gbe ibọn dani tori pe a ro boya wọn gba adura ni.

“Sugbọn kete ti wọn imamu bẹrẹ wasi ni wọn bẹrẹ sini si na bolẹ.

“Awọn eeyan miiran ni lati gba oju fereṣe jade ti wọn si ko awọn miiran wọ ninu igbo lọ.

Bayii, pupoọ lara awọn olugbe agbegbe naa lo ti fẹsẹ fẹ kuro .