Obìnrin tó bá Ẹkùn jà torí pé ó fẹ́ gbé ọmọ rẹ̀ farapa yánna-yànna

aworan iya ati omo ti ẹkun ṣe ikọlu si

Obinrin kan ni agbegbe Madhya Predesh lorilẹede India lo ti dero ile iwosan lẹyin to gbiyanju lati doola ẹmi ọmọ rẹ, lọwọ ẹkun to fẹ pa jẹ.

Archana Choudhary lo fi ọwọ mu ẹranko naa, ko to di pe awọn araalu ba da si ija naa.

Lọwọlọwọ bayi, Iya ati ọmọ naa, ọmọ osu mẹẹdogun, wa ni ile iwosan.

Iṣẹlẹ naa waye lọjọ Aiku ni ẹnu ibode Bandhavgarh nibi ibudo ẹranko naa.

Oṣojumikoro to ba ileeṣẹ BBC sọrọ ni ẹranko naa ti gbe ori ọmọ obinrin naa si ẹnu, ni iya rẹ ba saare lati dola ẹmi ọmọ rẹ.

Sugbọn o ni se ni ẹranko naa tun kọlu iya naa pẹlu.

“Ẹkun ti gbe ori ọmọ ṣenu, to si n wọ lọ, ki iya rẹ to wọ ija pẹlu ẹranko naa.

“Ariwo rẹ sita ni awọn olugbe yoku gbọ ti wọn fi jade sita lati ran lọwo, ti gbogbo wa si bọ sita lati le ẹranko lọ pẹlu igi ati okuta.”

‘Iya gbọgbẹ ni ọna ọfun, ọmọ fara pa ni ori’

Awọn ti isẹlẹ naa soju wọn sọ siwaju pe iya ọmọ naa ni ẹkun maa se lese ni ọna ọfun, ti ọmọ rẹ si farapa ni ori.

Dokita Misthi Ruhela ti ilu Jabalpur, to se ayẹwo iya ati ọmọ ni, ipo ti iya ọmọ naa wa ko dara rara nitori ọgbẹ ti Ẹkun naa fun pọ gan ni.

Sugbọn o ni ọmọ wa ni alaafia, ti iya ati ọmọ si ti bẹrẹ si ni maa gba itọju

Idunkoko awọn ẹkun lo ti fa ọpọlọpọ awuyewuye ni awọn agbegbe kan lorilẹede India.

Ajọ to n ri akoso igbo ọba ni o jẹ ipenija fun awọn lati sawari Ẹkun to sa wọ aarin ilu naa.

Osise ajọ, naa, Sanjeev Srivastava sọ fun ileeṣẹ BBC pe, awọn ti ṣe eto lati ri pe awọn sawari ẹranko naa lati dena irufẹ iṣẹlẹ naa.

Ẹranko àmọ̀tẹ́kùn ya wọ aarin ìlú, ọ̀rọ̀ di bóò o lọ o yàgò

aworan amotekun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nise ni ọrọ di koni ile gbe ile rẹ lẹyin ti amọtẹkun ya wọ agbegbe Karnataka, lorilẹede India.

O ti to ọjọ mẹtadinlogbọn ti awọn olugbe agbegbe naa ti bẹrẹ lati sawari ẹranko ọhun , ti o si ti ṣe eeyan lese ni ariwa agbegbe Karnataka.

Awọn olugbe agbegbe naa ni ọpọ igba ni awọn ri ẹranko ọhun to si ti mu ibẹru bojo ba pupọ lara awọn.

Ileeṣẹ to risi amojuto igbo lorilẹede India ni awọn ti ran akọsẹmọsẹ nipa eranko toto ọọdurun si agbegbe lati sawari amọtẹkun naa pẹlu igbagbọ lati dapada si ninu igbo to ti wa sugbọn igbinyanju wọn ko ti fẹ ẹnu re sọrọ.

Iṣẹlẹ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ alatako n sọ pe o waye lẹyin ti minisita to n ri si amujuto igbo fi ipo silẹ.

aworan amotekun

Oríṣun àwòrán, Karnataka Forest Department

Ọkan lara awọn osisẹ ileeṣẹ to n ri si amujuto igbo, Vijayakumar Gogi sọ fun BBC pe ogunlọgọ awọn osisẹ igbo ni wọn ti wa ni ayika agbegbe naa lati sawari amọtẹkun ọhun.

Amọtẹkun naa ni wọn sapejuwe gẹgẹ bi ẹranko to tiju sugbọn iroyin laipe ti safihan bi awọn eranko naa se bẹ wọ awọn agbegbe kan wo ninu igbinyanju wọn lati sawari ounjẹ. 

Sanya Gubbi, onimọ nipa ẹranko ti wa rọ awọn olugbe agbegbe naa lati ma ṣe foya ati pe ti wọn ba fi ara balẹ fun ẹranko, o ṣeṣe ki o ma ṣe ẹnikẹni ni ijamba.

Gubbi ni koko niki a pe akeyesi awọn si iwuwasi ẹranko to ṣe ọpọlọpọ anfani fun wọn lati ba ẹranko gbe.