Bí ìṣẹ̀lẹ̀ ọkọ̀ táńkà agbépo tó gbiná ṣe ṣẹlẹ̀ rèé...

aworan tanka agbepo

Ọkọ tanka agbepo tí gbina ni ẹnu ibode Olambe ati Matogun ni ìjọba ibilẹ ifo ni Ipinlẹ Ogun

Iroyin ni ọkọ tanka naa fẹ lọ ja epo bẹntirolu fun Ile epo kan ni agbegbe naa lo ṣubu lulẹ nitori ọna ti ko dara.

Kete to ṣubu lulẹ ni epo inu rẹ sì bẹrẹ si ni danu ko to gbina.

Osejumikoro to wa nibi iṣẹlẹ ni o to ile gbe mẹwa to jona bi ọkọ tanka naa ṣe gbina.

O ni "Ọpọ eeyan ti sa kuro nile tí awọn miiran si n wa ọmọ wọn kiri bayii.

"O to ile ati sọọbu mẹwa to gbina.

Alamojuto Ajọ to risi iṣẹlẹ pajawiri lorilẹede Naijiria, Ibrahim Farinloye, tí fi di iṣẹlẹ naa mule ninu atẹsita kan to fisita lọjọ Satide.

O ni dede ago meje arọ ni iṣẹlẹ naa waye tí ko si mu ẹmi kankan lọ.

"Ẹnikẹni ko padanu ẹmi tabi ki ẹnikẹni ṣe lese sugbọn ile mẹwa jona kọja ala.''

aworan tanka agbepo
aworan tanka agbepo
aworan tanka agbepo