Wo iye ìgbà tí ìjọba àpapọ̀ tí yáwó lábẹ́ àkóso Buhari

Ààrẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Ní ọdún 2015 nígbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò fi gba àkóso lọ́wọ́ ìjọba àná, $7.35 bn ni gbèsè ilẹ̀ òkèrè jẹ́.

Sùgbọ́n nigba tó ma fi di oṣù kejìlá ọdún 2016 , gbèsè náà ti di $7.84 bn.

Ní ìpárí ọdún 2017, gbèsè náà padà sí bílíọ̀nù 7.35 dọ́là ṣùgbọ́n tó ma fi di oṣù Kejìlá ọdún 2018 gbèsè náà ti di $21. 04 bn.

Ní ọdún 2019 ló di $23.11 bn tó sì tún fò di $28.57 bn ní ọdún 2020.

Níbò ni Nàìjíríà ń lọ lórí ọ̀rọ̀ gbèsè ni ohun tí àwọn ènìyàn ń bèèrè báyìí.

Ijọba apapọ tun fẹ ya trilliọnu mkanla naira ni 2023

Ìjọba Nàìjíríà ti kéde wí pé ní òun yóò yá tírílíọ̀nù mọ́kànlá náírà ní ọdún tó ń bọ̀.

Bákan náà ni wọ́n ní ó ṣeéṣe kí àwọn tún ta àwọn ohun ìní orílẹ̀ ede yìí kan láti lè rí pwó fi ṣe àwọn iṣẹ́ tó wà nínú àbá ìsúná ọdún 2023.

Mínísítà fún ètò ìsúná Nàìjíríà, Zainab Ahmed ló kéde ọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Ajé ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ ọdun 2022 nígbà tó ń ṣe àtúpalẹ̀ bí wọ́n yóò ṣe ná owó fún ọdún méjì láti ọdún 2023 sí 2025.

Ahmed ṣàlàyé pé tí Nàìjíríà bá sì ń ṣe ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù fún gbogbo ọdún 2023, owó tí Nàìjíríà ma nílò láti le mú kí wọ́n ṣe àmúṣẹ àwọn ohun tó wà lórí àbá ìsúná jẹ́ tírílíọ̀nù mẹ́tàlá dín díẹ̀.

Ó fi kun pé tí ìjọba bá mú àdínkù bá ìgbà tí wọ́n yóò ṣe ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún di àárín ọdún owó tí ìjọba ma nílò jẹ́ tírílíọ̀nù mọ́kànlá lé díẹ̀.

Ó síwájú pé owó ìrànwọ́ tí ìjọba ń ṣe lórí epo bẹntiróòlù yóò tírílíọ̀nù mẹ́ta lé ọwọ́ mẹ́ta ní ọdún tó ń bọ̀.

Gbese Naijiria

Kí ni àwọn ènìyàn ń sọ lórí ẹ̀yáwó tí ìjọba tún ń gbèrò yìí

Ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ lórí ayélujára
Ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ lórí ayélujára

Ní kété tí ìjọba ti kéde wí pé àwọn nílò láti yá owó mìíràn ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ti fi igbé bọnu lórí ayélujára wí pé ṣe gbèsè kọ́ ni yóò pa Nàìjíríà run báyìí.

Àwọn ènìyàn ní ní ṣe ló yẹ kí ìjọba wá ọ̀nà l;ati tán gbogbo ìṣòro tó ń kojú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà dípò yíyá owó ní gbogbo ìgbà láìsí ohun tí wọn yóò fi hàn fun.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn ló ń sọ wí pé ṣe èyí kìí ọ̀nà láti tún fi ìwà àjẹbánu tó ń fi ojoojúmọ́ gbokùn si ní Nàìjíríà.

Bákan náà ni àwọn mìíràn ní ìgbésẹ̀ yìí yóò túnbọ̀ mú kí owó náírà já kulẹ̀ sí ní ọjà àgbáyé.