Ṣé lóòótọ́ ni ẹkùn gúúsù Nàìjíríà ń san N25,000, tí àríwá ń san N10,000 fún ìwé ìrìnnà?

Oríṣun àwòrán, NIS/TWITTER
Àwọn ọmọ Naijiria kan lawọn oju opo ayelujara ti bẹ̀rẹ̀ sí ní bu ẹnu àtẹ́ lu àjọ to n ri si wọle wọle ero lorilẹede yii (Immigration) lori iyapa owo iwe irinna lati ẹkun guusu si ariwa.
Ìròyìn kan tó ń lọ lórí ayélujára lo ni iyé owó tí àwọn tó bá fẹ́ gba ìwé ìrìnnà ní apá gúúsù Naijiria pọ̀ gidi gan ju ti apá àríwá lọ.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀ ni àwọn èèyàn kan lórí ìkànnì Twitter, figbe bọ nipa iyapa owo iwe irinna naa, ti wọn si n ju ibeere ransẹ si ileesẹ Immigration.
Awọn ọmọ Naijiria naa lo n beere pe kí ló dé tí owó tó wà lórí ẹ̀rọ ayélujára fún gbigba iwe irinna lẹkun guusu Naiiria se pọ pupọ ju iye ti awọn eeyan lẹkun ariwa n san lọ.
Wọn ni ìpínlẹ̀ bíi Ekiti, Eko, Ebonyi, Bayelsa, Ogun àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, ni owo gbigba iwe irina wọn pọ̀ ju owo ti wọn fi n gba iwe irinna ni Adamawa, Sokoto, Kaduna àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Oríṣun àwòrán, @franeb

Oríṣun àwòrán, @getKennethed22
Ko si iyatọ laarin iye owo ti ẹkun guusu ati ariwa n san lati gba iwe irina - Immigration
Amọ ileesẹ Immigration ti wa fesi lori ọrọ yii fawọn eeyan to n beere iyapa owo naa.
Ninu atẹjade kan ti ileesẹ Immigration fisita loju opo Twitter rẹ, ni idahun naa ti jade.
Ileesẹ naa ni irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni pé ìyàtọ̀ wà láàárín owó ti àwọn ènìyàn tó wà ní apá Gúúsù àti Àríwá ń san fún ìwé ìrìnnà yàtọ̀ síra.
Wọ́n ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ló ń gbé wá fún ẹni tó bá ti wá láti apá gúúsù ṣùgbọ́n tí iye yìí yàtọ̀ gédégédé sí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà to ń gbé wá fun ẹni tó bá wá láti apá àríwá.
Ẹ̀wẹ̀, àjọ Immigration nígbà tó ń fèsì sí àwọn ẹ̀sùn yìí ni ọ̀rọ̀ kò ríbẹ̀ rárá nítorí iye kan náà ni gbogbo ènìyàn ń san láti ìpínlẹ̀ kan sí ìkejì fún owó ìwé ìrìnnà àgbáyé.
Àtẹ̀jáde tí Immigration fi léde náà ló wà lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ níbi tí wọ́n ti ṣàlàyé òun tó fà á tí àwọn ìyàtọ̀ náà fi ń wáyé lórí owó tó wà lórí ayélujára.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun ni à ń lò fún apá gúúsù, ti àtijọ́ ló ṣì wà ní àríwá
‘Ipele ẹrọ ọtọọtọ meji la n lo lẹkun mejeeji amọ owo ta n gba ko yatọ’
Wọ́n ní ipele ìmọ̀ ẹ̀rọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àwọn ń lo láti fi gbé ìwé ìrìnnà jáde ṣùgbọ́n ìyẹn kò túmọ̀ sí wí pé owó tí àwọn tó wà ní apá gúúsù ma san ma yàtọ̀ sí iye tí àwọn tó wà ní àríwá yóò sa.
Ó ní lọ́dún 2019 ni àjọ náà ṣe ìfilọ́lẹ̀ ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun lórí ṣíṣe ìwé ìrìnnà lórí ayélujára, èyí tó jẹ́ àlékún ìmọ̀ sí èyí tí àwọn ń lò tẹ́lẹ̀ láti ọdún 2007.
Ó ní ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun yìí ló bí ṣíṣe ìwé ìrìnnà olójú ìwé méjìlélọ́gbọ̀n fún ọdún márùn-ún ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n (N25,000), tí ojú ìwé mẹ́rìnlélọ́gọ́ta fún ọdún márùn-ún jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì (N35,000) fún ọdún márùn-ún àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin (N70,000) fún ọdún mẹ́wàá.
Ó ní bí àwọn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní lo ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun yìí àwọn ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn ti Ikoyi, FESTAC, Abuja, Alausa, Port Harcourt, Kano àti Gwagwalada ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe àmúlò wọn.
‘Awọn ipinlẹ kan ko tii ma lo imọ ẹrọ tuntun nipa iye owo ti ni to fẹ gba iwe irinna yoo san’
Àtẹ̀jáde náà fi kun pé ìdí tí ìyàtọ̀ tí owó náà ń gbé wá fi yàtọ̀ ní pé àwọn ìpínlẹ̀ tó kù kò ì tíì máa lo ìmọ̀ ẹ̀rọ tuntun yìí tí ìgbésẹ̀ sì ti ń lọ lọ́wọ́ láti gbé àwọn náà sórí rẹ̀.
Bákan náà ló ṣàlàyé pé ní ti ìmọ̀ ẹ̀rọ tí àwọn ń ṣàmúlò tẹ́lẹ̀, ìyàtọ̀ máa ń wà nínú owó tí àwọn ènìyàn yóò san bí ọjọ́ orí wọn bá ṣe pọ̀ sí tàbí irúfẹ́ ìwé ìrìnnà tí wọ́n bá fẹ́ gbà.
Àmọ́ èyí tí àwọn ń lò báyìí kò ya ẹnikẹ́ni sọ́tọ̀ nítorí iye kan náà ni gbogbo ènìyàn ni àǹfàní láti san fún ìwé ìrìnnà tó bá fẹ́ gbà káàkiri gbogbo Nàìjíríà.
Ó wá rọ gbogbo àwọn tó ń gbé ìròyìn náà kiri lórí ayélujára láti jáwọ́ nínú gbígbé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ èyí tí wọn kò mọ ìdí rẹ̀.
















