Tinubu àti APC, tẹ bá nítìjú ni, ẹ kò ní ṣàbẹ̀wò sí Jonathan - PDP

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọgbọnjọ,oṣù Kẹjọ ọdún 2022 ni olùdíje sípò Ààrẹ lábẹ́ àsíà ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Bola Ahmed Tinubu ṣe àbẹ̀wò sí ààrẹ àná, Goodluck Jonathan.
Tinubu, igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima àti àwọn gómínà ẹgbẹ́ òṣèlú APC márùn-ún mìíràn ni wọ́n ṣe àbẹ̀wò sí Jonathan ní ilegbe rẹ̀.
Àwọn gómínà tó kọ́wọ̀ọ́rìn pẹ̀lú Tinubu ni Abdulrahman Abdulrasaq ti Kwara, Bello Matawale ti Zamfara, Atiku Bagudu ti Kebbi, Simon Lalong ti Plateau àti Dapo Abiodun ti Ogun.
Kókó ohun tí àbẹ̀wò náà dá lé lórí ni wọn kò sọ síta àmọ́ èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ìpàdé náà dá lé ọ̀rọ̀ ìdìbò ọdún tó ń bọ̀.
Ẹ̀tànjẹ lásán lẹ bá lọ sọ́dọ̀ Jonathan - PDP
Bakan naa ni PDP tun bu ẹnu àtẹ́ lu olùdíje sípò Ààrẹ APC, Bola Tinubu àti igbákejì rẹ̀, Kashim Shettima.
O ni ìwà ẹ̀tàn lásán ni àwọn méjéèjì hù pẹlu abẹwo ti wọn se si Jonathan.
Agbẹnusọ fẹ́gbẹ́ PDP, Debo Ologunagba lo pasamọ awọn ọrọ yii loju opo Twitter rẹ.
Ologunagba ní pẹ̀lú bí Tinubu ṣe sọ onírúurú ọ̀rọ̀ irọ́ àti bó ṣe tako ìṣèjọba Goodluck Jonathan nígbà náà kí wọ́n tó gba ìjọba lọ́wọ́ rẹ̀, kò sí ẹni tí yóò gbàgbọ́ wí pé ó le ṣe àbẹ̀wò sí ilé rẹ̀.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Ologunagba nínú oríṣiríṣi nǹkan tó kọ sórí ayélujára Twitter rẹ̀ ní Tinubu àti igbákejì rẹ̀ kò finúfẹ́dọ̀ ṣe àbẹ̀wò sí Jonathan, bíkoṣè nítorí ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀.
Ó ní kò sí ohunkóhun tàbí àrà tí Tinubu àti Shettima yóò fi àwòrán tí wọ́n yà pẹ̀lú Jonathan dàá nítorí àwọn ènìyàn kò ní torí rẹ̀ dìbò fún wọn.
Ó fi kun pé Tinubu ń wá gbogbo ọ̀nà láti tún orúkọ àti ara rẹ̀ tó ti bàjẹ́ tán lójú àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ṣe ń tọ gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tí wọ́n ti ṣe àṣeyọrí lọ.
Ologunagba tẹ̀síwájú pé nítorí náà Tinubu àti igbákejì rẹ̀ Shettima àti àwọn àgbààgbà ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣe pa ìtìjú tì láti bá Goodluck Jonathan ya àwòrán.
Ó ní nígbà tí Jonathan ń ṣe ìjọba tí ohun gbogbo ń yọrí sáyọ̀, àwọn àgbààgbà tó ń ba ya àwòrán lónìí ni wọ́n ń pẹ̀gàn tí wọ́n sì ń bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba rẹ̀ nígbà náà nítorí ìmọ̀tara ẹni nìkan tó ń bá wọn jà nígbà náà.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Agbẹnusọ PDP náà ohun kan ṣoṣo tó bá àwọn APC nígbà kò ju bí wọ́n ṣe máa gba ìjọba lọ láì bìkítà láti ro bí wọ́n yóò ṣe ṣèjọba náà.
Ó ní ìpinnu wọn nígbà náà ló sọ Nàìjíríà sóko ìparun tí Nàìjíríà ń lọ báyìí.
Bákan náà ló fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà kò ì tíì gbàgbé gbogbo ipa tí Tinubu àti àwọn ènìyàn rẹ̀ kó nlórí bí wọ́n ṣe sọ̀rọ̀ òdì sí ìjọba PDP lábẹ́ ìdarí Jonathan nígbà náà ní èyí tó fẹ́ẹ̀ sọ orílẹ̀ èdè yìí sóko ìparun.
Tinubu ṣàbẹ̀wò sí Jonathan

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK
Ọgbọ́n tí mo dá rèé tí mo fi yanjú aáwọ̀ ASUU lórúmọ́jú - Jonathan

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ tẹlẹri ní Naijiria, Goodluck Jonathan ti ṣalaye bi oun ṣe fopin si iyanṣẹlodi oloṣu mẹrin lasiko iṣejọba rẹ.
Jonathan ni alẹ ọjọ kan ṣoso ni oun ripe awọn olukọ pada si ẹnu iṣẹ, lẹyin ti gbogbo igbiyanju miran ti ja si ofo.
O ṣalaye pe ọna ti oun gbegba ni lati pe gbogbo awọn alẹnulọrọ to fi mọ awọn alaṣẹ ẹgbẹ awọn olukọ ASUU ọhun.
'' Bí mo ṣe fòpin sí ìyanṣẹ́lódì ASUU rèé ''
Jonathan ni oun gbe igbesẹ yii nitori awọn akẹkọọ to ti wa ni ile fun oṣu mẹrin.
Jonathan ni bi o tilẹ jẹpe oun lo pe ipade naa, ti oun si pejọ sibẹ pẹlu igbakeji aarẹ ati minisita fun eto ẹkọ, ipade naa ko pari titi di aarọ ọjọ keje.
‘’Awujọ wa yii lagbara, ti o si gba ọpọlọpọ ọgbọn ati suuru, ti a si n sọrọ nipa iyanṣelodi ẹgbẹ ASUU lọwọ.’’
Nigba naa, iyanselodi osu mẹrin lo n lo lowo, ti opolopo igbimo si ti joko lori iṣẹlẹ yii amọ ti ko si ọna abayọ.
‘’Olotu ijọba wa ni ijoko, ti a ti ṣepade naa amọ ti ko ni ojutu titi di aago marun un ọjọ keji, ki a to yanju awọn ipenija naa, ti wọn si wọgile iyanṣẹlodi ọhun.
Labẹ iṣejọba aarẹ Buhari, awọn akẹkọọ wa ni iyanṣẹlodi lati Ọjọ Kẹrinla, Oṣu keji, ọdun 2022,
Ohun ti wọn si n beere ni ki ijọba mu gbogbo adehun ti wọn ṣe pẹlu wọn ṣe.
Amọ titi di asiko yii, gbogbo ọna lati fopin si iyanṣẹlodi ohun lo jasi pabo.
















