Mó fẹ́ fi owó ọkọ̀ ìyá mi tí mo fẹ́ tà, ta tẹ́tẹ́ ni - Afurasí

Samuel Owolabi tó jí ọkọ̀ ìyá rẹ̀ gbé lati wá tà ní Eko

Oríṣun àwòrán, POLICE/TWITTER

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko ti nawọ́ gán ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n kan, Samuel Owolabi fẹ́sùn wí pé ó fẹ́ ta ọkọ̀ ìyá rẹ̀.

Ṣaájú ni agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko Benjamin Hundeyin ti kọ́kọ́ fi ìròyìn náà sórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ lọ́jọ̀ Ìṣẹ́gun, ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kẹjọ ọdún 2022 nípa ọmọkùnrin náà.

Nínú àtẹ̀jáde tí Hundeyin fi léde ló ti ṣàlàyé ní kíkún bí Owolabi ṣe gbé ọkọ̀ ìyá rẹ̀ láti ìlú Ibadan láti wá tà ní ìpínlẹ̀ Eko.

Hundeyin ṣàláyé wí pé Owolabi ni àkọ́bí ọmọ tí ìyá rẹ̀ bí nínú ọmọ mẹ́ta tí ìyá náà bí.

Ó ní agbègbè Ijora Badiya ní ìpínlẹ̀ Eko ni ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ̀ Owolabi nígbà tí ọkọ̀ tó gbé wá tà láti Ibadan dédé yọnu lójijì.

Ó fi kun pé ni òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ Àìkú ni Owolabi fi ìlú Ibadan sílẹ̀ láti wá ta ọkọ̀ náà sí ìpínlẹ̀ Eko láì gba àṣẹ lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ tàbí ẹnikẹ́ni.

Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní nǹkan bí aago mẹ́sàn-án òwúrọ̀ ni ọkọ̀ náà dédé yọnu ní agbègbè Ijora Badiya tí Owolabi sì sáré lọ pe àwọn tí yóò ba wọ ọkọ̀ náà kúrò lójú pópó.

Àkọlé fídíò, Olaiya Igwe: Ilà ójú mi, ló wà lójú ìyá MC Oluomo, ọ̀gá àti àbúrò mi ni – Olaiya Igwe

Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ Owolabi?

Hundeyin tẹ̀síwájú pé nígbà tí awakọ̀ tó wá Owolabi wọ ọkọ̀ kúrò lójú lọ sí inú Ijora Badiya wí pé ara rẹ̀ kò lélẹ̀ pẹ̀lú bí ó ṣe ń wòyín wọ̀hún ni awakọ̀ náà kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá Ijora Badiya.

Awakọ̀ náà ni òun fura sí Owolabi wí pé ọwọ́ rẹ̀ kò mọ́ pẹ̀lú ọkọ̀ tí òun ba wọ́ kúrò ní títì ni òun ṣe fi tó wọ́n létí.

Ó ní lẹ́sẹ̀ kan ni àwọn ọlọ́pàá Ijora Badiya kán sí ọ̀nà láti nawọ́ gán Owolabi àti ọkọ̀ tí wọ́n sì kó àwọn méjéèjì lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá.

“Bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ti mu Owolabi ló jẹ́wọ́ wí pé ọkọ̀ ìyá òun ni ọkọ̀ náà ní Ibadan tí òun gbé wá sí ìpínlẹ̀ Eko láti wá tà.”

“Àwọn ọlọ́pàá ló wá pe ìyá Owolabi láti bèèrè bóyá ó mọ ibi tí ọmọ rẹ̀ àti ọkọ̀ rẹ̀ wà ṣùgbọ́n tó ní òun kò nǹkankan nípa bó ṣe rin ìrìnàjò dé Eko.”

Bákan náà ni Hundeyin tún ṣàlàyé pé ìyá ọmọ náà ni òun kò fun láṣẹ láti ta ọkọ̀ òun tí àwọn ọlọ́pàá sì ránṣẹ́ sí láti wá gba ọkọ̀ rẹ̀ ní Eko.

Mó fẹ́ fi owó tí mo bá rí níbi ọkọ̀ ìyá mi tí mo fẹ́ tà ta tẹ́tẹ́ ni

Nígbà tí Owolabi ń ṣàlàyé òun tó fẹ́ fi owó tó bá rí níbi títa ọkọ̀ náà ṣe, ó ní òun fẹ́ fi ta tẹ́tẹ́ Baba-Ijebu.

Ó ní òun ti kọ́kọ́ jí owó tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà láti ta tẹ́tẹ́ náà tí òun kò sì jẹ rí.

 Hundeyin ní ìwádìí ń tẹ̀síwájú lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Bàbá ọkùnrin tó kú níbi ìjà àwọn olórò àti ṣọ́ọ̀ṣì l’Eko kígbe fún ìdájọ́ òdodo

Akeem Adebisi

Oríṣun àwòrán, AKEEMZY FB

Bii awọn ọjọ mii ni ọjọ Aje, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii ri loju Akeem Adebisi nigba to ji kuro nile rẹ laarọ kutu, ṣugbọn ko mọ pe ọjọ naa ni oun yoo ri aye mọ.

Akeem, ẹni ọdun mẹẹdọgbọn naa wa lara awọn ti yoo ṣe oro lọjọ naa, o si wa lara awọn to kede pe oro yoo jade.

Koda, oun funra rẹ gan lo n lu aago ikilọ fun eeyan adugbo pe wọn ko gbọdọ jade lalẹ ọjọ naa nitori pe oro fẹ jade.

Amọ alẹ ọjọ ti oro yii jade gan ni oun funra rẹ fi aye silẹ.

Bi Akeem Adebisi ṣe kagbako iku ojiji - Baalẹ Oko Ọba

Awọn eeyan ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, amọ ti wọn ko fẹ ki BBC kede orukọ wọn ṣalaye fun wa pe, bi wọn ṣe n gbe oro naa lọ ladugbo Oko Oba ni wọn ṣakiyesi pe isin iṣọ oru kan n waye ninu ṣọọṣi kan ladugbo naa.

Wọn ni ijọ naa kii ṣe aimọ, ọpọ awọn to si wa ladugbo naa lo mọ pe wọn maa n ṣe iṣọ oru lemọlemọ.

Bi iṣọ oru naa ṣe n lọ, awọn ọmọ ijọ kan wa niwaju ile ijọsin ọhun nitori aye ti ko to ninu ile ijọsin naa.

Baale adugbo ọhun, Oloye Razak Alamude ni awọn to n gbe oro sọ fun awọn ọmọ ijọ ki wọn wọle sinu ṣọọṣi amọ wọn kọ jalẹ.

Akeem Adebisi

Oríṣun àwòrán, TSPM

Ibi ti fa ki n fa naa ti n lọ lọwọ ni ọrọ di iṣu ata yan yan, ti wọn si kọju ija si ara wọn.

Baale Alamude sọ pe “Ohun to fa ija laarin awọn ọmọ ijọ ati awọn to n gbe oro niyẹn o.”

“Agbọn atawọn nnkan mii ni wọn sọ lu Adebisi to fi ṣubu lulẹ.

Oru ni iṣẹlẹ naa waye, to ba jẹ pe ọsan gangan ni boya yoo gbiyanju lati doola ara rẹ.

Ile iwosan marun un ọtọtọ ni a gbe ọkunrin naa lọ, ti wọn si kọ ọ ki wọn to ni ki a maa lọ si ile iwosan LUTH.

Sugbọn a ko ti de ibẹ to fi dakẹ.”

 Mo n fẹ idajọ ododo - Baba oloogbe

Wasiu Adebisi, to jẹ baba oloogbe naa ti sọ peAkeem yii lo n gbọ bukata idile awọn lati igba ti iyawo oun ti dagbere faye ni nnkan bii ọdun mẹsan sẹyin.

O ni “Akeem ni ọmọ mi kẹta, iṣẹ aranṣọ lo si n ṣe.”

“Ọmọ daadaa ni, gbogbo eeyan lo si fẹran rẹ ladugbo, ṣugbọn ohun ti mo fẹ bayii ni idajọ ododo lori iku rẹ.”

A ti fi ṣikun ofin mu pasitọ ijọ atawọn mẹsan an mii – Ọlọpaa

Lasiko ti akọroyin BBC Yoruba ṣabẹwo sile ijọsin naa, o ṣakiyesi pe ile ijọsin ọhun ko tobi rara, ko si le gba ọpọ ero.

Lara awọn nnkan ta tun foju ganni ni afọku igo, afọku agbọn ati ẹjẹ ninu ile ijọsin ọhun.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, koda awọn ti fi ṣikun ofin mu oludasilẹ ile ijọsin naa, Wolii obinrin Mercy Noka, to fi mọ awọn eeyan mẹsan an miran.