Àbúrò Fayose kó rí ajínigbé kankan, ìròyìn ìbẹ̀rù ló fi f'ọkọ̀ rẹ̀ kọlu nǹkan - Ọlọ́pàá

isaac Fayose ati ọkọ rẹ to ni awọn agbebọn naa kọlu

Oríṣun àwòrán, Isaac fayose/ instagram

Àkọlé àwòrán, Isaac Fayose ati ọkọ rẹ to ni awọn agbebọn naa kọlu

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun ti ṣalaye pe, Isaac Fayose aburo gomina ana ni ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayoṣe ti ṣalaye otitiọ ọrọ nipa ohun to ṣẹlẹ gan.

Islẹ naa lo waye lasiko irinajo rẹ lopopona maros Gbongan si Ife eyi to fi soju opo ayelujara rẹ.

Isaac Fayose sọ pe awọn afurasi ajinigbe kọlu ohun atawọn eeyan kan lagbegbe Gbọngan nipinlẹ Ọṣun.

Amọ atẹjade kan ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yemisi Opalola, fi sita sọ pe, lakọkọ naa, ko si ẹnikẹni to fi iroyin ikọlu kankan to ọlọpaa ipinlẹ naa leti.

O tun ni bẹẹ ni kii ṣe Gbọngan ni ibi ti arakunrin naa juwe pe iṣẹlẹ naa ti waye.

Fayose ko le sọ asọdaju pe isẹlẹ ijinigbe waye- Ọlọpaa Osun

Atẹjade naa ni aburo gomina ana naa ko le sọ ni asọdaju pe iṣẹlẹ ijinigbe kankan waye lasiko irinajo rẹ.

O ni irokuku ojo lo gbọ to fi da omi inu agbada nu nipa isẹlẹ ajinigbe naa.

“Nigba to de agbegbe kan lẹyin ikọja odo Aṣejirẹ, ni ati maa dojukọ Ibadan lẹnu irinajo rẹ naa lati Ekiti si ilu Eko.

O ri awọn arinrinajo kan ti wọn n yi ori ọkọ wọn pada fun ibẹru ikọlu awọn ti wọn ro pe wọn jẹ adigunjale.

Nibi ti oun pẹlu ti n gbero ati yi ori ọkọ rẹ pada lo ni ijamba ọrọ ranpẹ kan ti waye.”

Ileeṣẹ ọlọpaa Osun ni Isaac Fayose funrarẹ ko fi oju ri awọn to n pe ni ajinigbe, bẹẹ ni ko si ẹnikẹni to fi ara ṣeṣe tabi ti wọn ji gbe.

Isaac Fayose ni agbebọn kọlu ọkọ oun, jí ọ̀pọ̀ èèyàn gbé lọ ní márosẹ̀ Ibadan sí Gbongan

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn agbebọn ti kọlu Isaac Fayose, to jẹ aburo gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri, Ayọ Fayoṣe.

Gẹgẹ bi akọsilẹ to fi si oju opo ayelujara rẹ gbogbo, Ọgbẹni Isaac Fayoṣe ṣalaye pe agbegbe ilu Gbongan ni ipinlẹ Ọṣun lopopona marosẹ, ibadan si Ifẹ ni ikọlu naa ti waye.

O ṣalaye wi pe lootọ ko si ẹnikẹni to padanu ẹmi rẹ lasiko ikọlu awọn agbebọn naa amọ wọn ji ọpọ awọn arinrinajo gbe lasiko ikọlu naa.

Gẹgẹ bi aworan to fi si oju opo Instagram rẹ, ọkọ ayọkẹlẹ rẹ bajẹ pupọ pẹlu bi o ṣe ni awọn agbebọn naa ṣe ikọlu si ọkọ rẹ.

Aworan Isaac Fayose ati ọkọ rẹ to bajẹ

Oríṣun àwòrán, isaacfayoseoriginal_

Ọlọpaa kii ṣe ẹmi, Facebook kii ṣe agọ ọlọpaa - ọlọpaa Ọṣun fesi fun aburo Fayose

Ninu ọrọ rẹ, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọṣun SP Yẹmisi Ọpalọla ṣalaye pe ko si iroyin nipa isẹlẹ naa niwaju ileeṣẹ ọlọpaa.

Opalola ni Isaac Fayose ko fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti.

“Mo ti ba ọga ọlọpaa agbegbe ilu Gbọngan sọrọ o si ni pe ko si ẹnikẹni to fi iroyin iṣẹlẹ bẹẹ to awọn ọlọpaa leti.”

Ọkọ Isaac Fayose to ni wọn kọlu

Oríṣun àwòrán, isaac fayose/ instagram

Amọṣa alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun ni awọn ti bẹrẹ iwadii lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan.

O ni ọgbẹni Fayoṣe ko fi iroyin ohun to ṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti, ori ayelujara lo gbe ẹjọ lọ.

“Awa (Ọlọpaa) kii ṣe ẹmi ti yoo lee mọ ohun to n ṣẹlẹ nibi gbogbo ati nigba gbogbo.

Oju opo Facebook kii ṣe agọ ọlọpaa. A nilo lati ṣi fi ọrọ wa aburo Fayose lẹnuwo nipa iṣẹlẹ naa.

Idi ni pe ọpọ ibeere la nilo lati bii ṣugbọn ti a ko ni le maa bi loju opo Facebook rẹ.”