"Yóò tó ọjọ́ méjì tí Tobi àti Arewa ti kú, kí ọlọ́pàá tó wá gbé òkú wọn"

Àwọn olóògbè

Oríṣun àwòrán, KWARA POLICE

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ KWASU, ti ṣàlàyé ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì tí wọ́n ṣàdédé bá òkú wọn nínú yàrá.

Orukọ awọn akẹkọọ naa ni Tobiloba Daniel àti Arewa Abayomi .

BBC News Yorùbá kàn sí ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Kwara tó wà ní Malete láti fìdí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà múlẹ̀.

Ní ìgbà tí a dé Jamlat Hostel ní agbègbè Sàfàrí ní ìlú Malete, níbi tí wọ́n ti bá òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nínú yàrá, ọ̀pọ́lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ni kò sí nílé níítorí ìdánwò tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́.

‘O to ọjọ meji ti awọn mejeeji ti ku sinu yara, ki ọlọpaa to wa’

Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé nínú ilé tí wọ́n ti bá òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà, Boluwatife Ali ṣàlàyé pé nínú yàrá ni òun wà, tí òun ṣàdédé gbọ́ tí wọ́n ń já ilẹ̀kùn yàrá kan.

Boluwatife ní nígbà tí òun jáde láti mọ́ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ ni òun ri wí pé àwọn ọlọ́pàá ló ń já ilẹ̀kùn yàrá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

“Nígbà tí mà á fi súnmọ́ ibẹ̀, ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ òórùn, ni mo ri wí pé àwọn méjéèjì tó ń gbé ibẹ̀ ló ti kú.”

“Kò sí ẹni tó le ṣàlàyé pé báyìí ni nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nítorí a ò mọ̀ nǹkankan, a kàn ṣá à gbọ́ wí pé wọ́n ti kú ni.”

“Ní àárọ̀ ọjọ́bọ̀ tí àwọn ọlọ́pàá dé, tí wọ́n tó já ilẹ̀kùn ni a tó gbọ́ òórùn léyìí tó túmọ sí pé ó ṣeéṣe kí wọ́n ti kú sínú fún bí ọjọ́ méjì tí àwa kò mọ nǹkankan”

Ilẹ̀kùn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n já

‘Akẹkọọ obinrin lo gba ile, amọ eyi ọkunrin maa n wa wo nibẹ’

Ẹlòmíràn tí òun náà tún bá àwọn ikọ̀ ìròyìn wa sọ̀rọ̀, Adejọyan Hakeem ní lásìkò ìdánwò báyìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń kó kúrò ní ilé wọn láti lọ kàwé nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ tàbí lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ wọn tó bá súnmọ́ ìtòsí ọgbà ilé ẹ̀kọ́ wọn.

Hakeem ní inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ KWASU níbi tí òun ti lọ ṣe ìdánwò ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹẹ̀dógbọ̀n, oṣù Kẹjọ ni ìròyìn kan òun lára wí pé àwọn ọlọ́pàá wà nínú ọgbà ilé àwọn.

Ó ní àwọn tí àwọn jọ ń gbélé ló pe òun pé àwọn wà ní àgọ́ ọlọ́pàá nítorí ìròyìn ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn olóògbé náà pẹ̀lú àwọn ará ilé yóòkù, ó ní òun ní ìgbàgbọ́ wí pé ọmọbìnrin náà ló gba ilé ṣùgbọ́n àwọn máa ń rí ọkùnrin náà papọ̀ mọ ní gbogbo igbà.

Ó fi kun pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wọlé ní ìpín kejì sáà tí àwọn wà yìí ni kò ṣe sí ìbáṣepọ̀ tó lọ bẹ́ẹ̀ láàárín wọn àti àwọn ará ilé yòókù.

A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà – Fásitì KWASU

Nígbà tí ikọ̀ BBC News Yorùbá tún kàn sí Agbẹnusọ ilé ẹ̀kọ́ KWASU, Dókítà Saeedat Aliyu, ó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣàwàrí àwọn ohun tí wọn mọ̀ nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Aliyu ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà, òun kò lè sọ ní pàtó wí pé nǹkan báyìí ló ṣẹlẹ̀ àmọ́ iṣẹ ti ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.

Àwọn ọ̀rẹ́ ti kò rí akẹgbẹ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ ló wá fi ọ̀rọ̀ tó àgọ́ ọlọ́pàá létí - Ọlọ́pàá Kwara

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ní nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ àwọn olóògbé ri wí [‘e àwọn kò rí àwọn akẹgbẹ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ ni wọ́n wá gfi tó àgọ́ ọlọ́pàá létí.

Agbẹnusọ ọlọpàá Kwara, Ajayi Okasanmi ní àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n wá wọn lọ sí ilé ló rí wí pé àwọn ènìyàn wà nínú yàrá náà nígbà tí wọ́n yọjú láti ojú fèrèsé.

Okasanmi ní nígbà náà ni àwọn lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún létí kí wọ́n tó lọ gbé òkú wọn.

Bákan náà ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wí pé ìwádìí ń lọ lọ́wọ́ láti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ láìpẹ́.

Kí ló fa ikú akẹ́kọ̀ọ́ takọ-tabo méjì tí wọ́n bá òkú wọn nínú yàrá ní Kwara?

Àwòrán bí wọ́n ṣe ń gbé òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sínú ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, SCREENSHOT

Gbogbo abiyamọ ayé, gbogbo wàhálà wa lórí àwọn ọmọ wa kò ní já sí asán.

Kí ni ohun tó ṣokùnfà ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ìpínlẹ̀ Kwara, KWASU ni adugbo Malete nilu Ilorin?

Awọn akẹkọọ naa ní wọ́n ṣàdédé bá òkú wọn nínú ilé ni, ìbéèrè yii si lo gba ẹnu àwọn ènìyàn.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà tí wọ́n wà ní ìpele kejì eto ẹkọ wọn ni orúkọ wọn ń jẹ́ Tobiloba Daniel àti Arewa Abayomi.

‘Awọn akẹkọọ mejeeji ko wa fun idanwo la se lọ wo wọn nile’

Ìròyìn ní Daniel àti Abayomi jẹ́ ọ̀rẹ́kùnrin àti ọ̀rẹ́bìnrin tí wọ́n jọ ń ṣe wọléwọ̀de.

Daniel àti Abayomi ń kàwé ní ìgbáradì fún ìdánwò wọn nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún kí wọ́n tó pinnu láti ma lọ sí ilé ìgbé wọn, èyí tó wà ní ìta ilé ẹ̀kọ́ náà.

Ẹ̀wẹ̀, nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ wọn kò rí wọn láti wá fún ìdánwò tí wọ́n gbáradì fún ní ọjọ́ kejì, tí wọn kò sì tún rí wọ́n nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà fún ọjọ́ méjì, ló mú ki wọn maa kọminú lórí ìdí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kò farahàn fún ìdánwò.

Nígbà tí wọ́n wá wọn nínú ọgbà tí wọ́n kò rí wọn, ni wọ́n wá rò ó láti wá wọn lọ sí ilé wọn.

Nígbà tí wọ́n dé ilé wọn ni wọ́n bá òkú àwọn méjéèjì lórí ìbùsùn níhòhò.

Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ní àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Daniel àti Abayomi tí wọ́n rí òkú àwọn wọ́n, fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà létí ní kíákíá.

A ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà - Fasiti KWASU

Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, Agbẹnusọ ilé ẹ̀kọ́ KWASU, Dókítà Saeedat Aliyu ní àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣàwàrí àwọn ohun tí wọn mọ̀ nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Aliyu ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ti gbọ́ sí ọ̀rọ̀ náà, òun kò lè sọ ní pàtó wí pé nǹkan báyìí ló ṣẹlẹ̀ àmọ́ iṣẹ ti ń lọ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.

Iṣẹ́ ti ń lọ láti fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà múlẹ̀ - Ọlọ́pàá Kwara

Bákan náà ni agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara, Ajayi Okasanmi ní àwọn ti gbọ́ sí ọ̀rọ́ ọ̀hún.

O ni iṣẹ́ sì ti bẹ̀rẹ̀ láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà.

Okasanmi ní nígbà tí àwọn ọ̀rẹ́ wọ́n bá òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà nínú ilé ni wọ́n lọ fi ọ̀rọ̀ náà tó àgọ́ ọlọ́pàá létí.

Ó ní àwọn ọlọ́pàá ló gbé òkú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kúrò nínú yàrá, tí wọ́n sì ti gbe wọn lọ sí ilé ìgbóòkúpamọ́ sí fún àyẹ̀wò.

Ó fi kun pé àwọn ma ṣe àyẹ̀wò láti mọ ohun tó ṣokùnfà ikú àwọn ọ̀dọ́ náà.