Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí tó jí tírélà ìrẹsì gbé ní Ibadan

Afurasi naa ati ọkọ irẹsi to ji gbe

Kele ofin ti gbe afurasi ẹni ọdun mẹtadinlogun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Jolly Iyoha lori ẹsun wi pe o lẹdi apo pọ pẹlu awọn eeyan kan lati ja ọkọ ajagbe to n ko irẹsi lọ si ilu Akurẹ, ipinlẹ Ondo gba. Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ lo ṣe afihan awọn afurasi ti wọn nawọ gan ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to n bẹ ni agbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan.

Alukoro ileesẹ ọlọpaa n'ipinlẹ Ọyọ, Adewale Oṣifẹṣọ ṣe alaye fun awọn oniroyin wi pe iroyin to ọlọpaa leti nipa awọn ẹgbẹ ọdaran kan, ti wọn maa n ja ọkọ nla gba. ti wọn si n dari awọn ọkọ naa lọ si ibomii. Eleyii lo si mu ki ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iṣẹ iwadii titi ti wọn fi ni anfani lati ṣe awari ọkan ninu wọn.

Lẹyin ti kele ofin gbe Jolly Iyoha, wọn ba apo irẹsi aadoje(130) ti iye owo rẹ le Milliọnu mẹrin naira (#4,680,000) ninu ọkọ ajagbe ti wọn ja gba. Alekun iṣẹ iwadii fi idi rẹ mulẹ wi pe, ilu Akurẹ ni ọkọ ajagbe naa n ko ẹru lọ lati ipinlẹ Kano, ki awọn ọdaran naa to jaa gba.

Afurasi naa ati ọkọ irẹsi to ji gbe

Bakan naa ni afurasi ti wọn mu ṣe alaye wi pe awọn ti n gbero lati lọ ta awọn irẹsi naa ni ilu Okene n'ipinlẹ Kogi. Agbegbe Alakia ni wọn ti mu afurasi naa niluu Ibadan ti o si ti jẹwọ lori ẹsun ti wọn fi kan an.

Lọwọlọwọ bayii, ileeṣẹ ọlọpaa n gbọ tẹnu rẹ gẹgẹ bi iṣẹ iwadii ṣe n tẹsiwaju.