Tẹ bá sún mi kan ògiri, màá yà kú ni dípò kí... - Olori Silekunola

Oríṣun àwòrán, Ooni of Ife Instagram
Olori Naomi Silekunola Ogunwusi, ti o tun jẹ iyawo fun Ooni tí ilé ife, Oba Adeyeye Ogunwusi, ti paroko ọrọ sita lori awọn ilakọja rẹ ninu igbeyawo.
Olori Ogunwusi ninu ọrọ rẹ ni ti wọn ba hu awọn ohun to ti kọja lọ sita, ti wọn si sun oun kan ogiri, oun yoo ya padanu ẹmi oun ni dipo ki ..., ti ko si pari ọrọ rẹ.
Olori Naomi Silekunola lo kọ awọn ọrọ yii soju opo ayelujara Instagram rẹ, to si bu ẹnu atẹ lu bi isejọba Naijiria ṣe kuna lati daabo bo awọn obinrin.
Olori naa tun koro oju si bawọn obìnrin ko ṣe ni anfani si nkan ti o sapejuwe gẹgẹ bi ẹtọ ọmọniyan.
"Ko yẹ ki wọn maa se ẹlẹya tabi dẹru ba obinrin kankan.
Ki obinrin kuro nile ọkọ nitori iwa ipa ati ọyaju ko yẹ ko gba ẹtọ ati ọ̀wọ̀ to ni bii obinrin ati ọmọniyan.”
Olori Naomi wa mẹnuba isẹlẹ kan to waye si igbakeji Kọmisana ọlọpaa ni ẹkun kẹtadinlogun (Zone 17) ileesẹ ọlọpaa nilu Akure.
Isẹlẹ naa to fi se apẹẹrẹ iwa ipa ninu igbeyawo lo sọ pe o jẹ fidi ẹri mul pe ilana isejọba ti kuna nidi didaabo bo ẹtọ awọn obinrin.
Olori Naomi wa n beere pe se iha ti wọn kọ si iwa yii tumọ si pe bi obinrin kan ba kuro ninu igbeyawo, o yẹ ko lọ ku ni?
O wa seleri pe oun yoo mu ẹkunrẹrẹ iroyin wa nipa awọn iriri oun lori ọrọ naa.

Oríṣun àwòrán, queen_silekunolanaomi_ogunwusi
Ajinde mi pada loju oorun yoo buru pupọ - Olori Silekunola
Ọpọ eeyan to ka ohun ti Olori Silekunola kọ yii, ti pupọ ninu wọn si jẹ obinrin lo n gbarata lori iriri rẹ ninu igbeyawo.
Bakan naa ni wọn n kan saara si pe akọni ni, to si ni igboya lati sọrọ sita lori iriri rẹ́.
Ọpọ awọn eeyan yii naa si lo gba pe ko yẹ ki obinrin joko sinu iwa ipa, ilokulo ati ipaya nile ọkọ, se lo yẹ ki wọn jade kuro nibẹ.
Amọ ọkan lara awọn eeyan to sọrọ naa jẹ aburo Olori Silekunola, to si fesi lori oun ti ẹgbọn rẹ kọ.

Oríṣun àwòrán, queen_silekunolanaomi_ogunwusi
Simi Oluwaseyi, lero rẹ ni ko yẹ kí obìnrin kankan doju kọ gbogbo ila kaka ti olori naa ti lakọja nile ọkọ.
Simi ni “ Ko si obinrin kankan to yẹ ki wọn hu ida kan ninu ọgọrun ohun to la kọja si, tabi to n la kọja lọwọ.
O tiẹ gbiyanju lati ni ifarada pupọ, o si ti yẹ ko to gẹẹ bayii, asiko ti to ta ji aja to n sun.
o wa rọ olori naa pe asiko ti to lati sọrọ síta.
Olori Silekunola Ogunwusi wa fesi pada pe ajinde pada oun naa yoo buru pupọ nitori ti wọn sun oun kan ogiri, oun yoo ya ku ni dipo...
O wa dupẹ lọwọ Simi atawọn ololufẹ rẹ yoku pe wọn duro ti oun gbọin gbọin lasiko ti oju ogun le, o ni wọn ko mọ oun to n lọ amọ sibẹ, Ọlọrun yoo jẹ olododo di oun.

Oríṣun àwòrán, queen_silekunolanaomi_ogunwusi
Ki lo ti waye sẹyin laarin Ooni Adeyeye Ogunwusi ati Olori Silekunola?
Ọdun 2018 ni Ooni Ile Ife, ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi gbe Olori Naomi Silekunola niyawo lẹyin ti igbeyawo rẹ pelu Olori Zeynab daru.
Igbeyawo naa si seso ọmọkunrin kan soso, eyiun Ọmọọba Tadenikawo Ogunwusi.
Ọmọ bibi ilu Akure, nipinlẹ Ondo ni Naomi Silekunola,tii se ajihinrere, to si jẹ iyawo kẹta fun Ooni Ile Ife.
Ọdun mẹta gbako ni Ooni ati Olori naa lo papọ, ki igbeyawo naa to ni ijakulẹ.
Ọjọ Kẹtalelogun osu Kejila ọdun 2021 ni Olori Silekunola kede loju opo Instagram rẹ pe oun ti kuro ni aafin oodua nile Ife, ti oun si ti kuro ninu igbeyawo oun.
Olori naa ko salaye ohun to se okunfa ipinu rẹ ju pe oun n lọ, ti ikede naa si ba ọpọ eeyan lojiji.
















