Ta bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run. Yorùbá gbọdọ̀ wẹ ara rẹ̀ mọ́ lọ́wọ́ ègún àti èpè - Akintoye

Ọjọgbọn Banji Akintoye
Àkọlé fídíò, Banji Akintoye: Èpè ará ijọ́un ta tà sóko ẹrú òyìnbó ló ń ja Yorùbá

Olori ẹgbẹ to n ja fun idasilẹ orilẹ-ede Oduduwa, Ọjọgbọn Banji Akintoye, sọ pe oun tọrọ aforiji lọwọ awọn ọmọ ilẹ Yoruba ti wọn ta si oko ẹru lasiko owo ẹru to waye ni ọpọlọpọ ọdun sẹyin.

Ninu fidio kan to ti ba BBC Yoruba sọrọ, Akintoye sọ pe Ẹmi Mimọ sọ fun oun pe ẹlẹda awọn baba nla Yoruba ti wọn ta si oko ẹru awọn oyinbo alawọ funfun, n fi iya jẹ awọn ọmọ Yoruba.

Bakan naalo ni eyi lo si tun fa aisi idagbasoke, ilọsiwaju ati iṣọkan fun wọn.

Ọjọgbọn Akintoye sọ pe pupọ ninu awọn eeyan naa lo gégún fun iran Yoruba to n bọ lẹyin wọn nitori ibaṣepọ ibi to waye laarin awọn olori ẹya Yoruba lasiko naa.

Awọn ẹru Yoruba naa lo ni wọn tun gegun fun awọn oniṣowo lati orilẹ-ede Portugal ati Netherlands to wa si Africa fun rira ẹru ni ọdun 18th century.

Awọn ẹru ti wọn ta fun oyinbo alawọ funfun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Oriṣiriṣi ifiyajẹni ni awọn ti wọn ta si oko ẹru koju

Akintoye, to jẹ onimọ nipa ìtàn sọ pe o ṣe koko ki ilẹ Yoruba ṣe iwẹnumọ fun awọn ègún ati èpè ti wọn fi wọn ge ọhun, ki wọn to o le gbadun oju rere Ọlọrun, iṣọkan ati ilọsiwaju.

O ni "lootọ ni iṣẹlẹ naa ti pẹ, ṣugbọn bí ẹni to ṣu ba yagbẹ, ẹni to ko igbọnsẹ naa ko le gbagbe lailai."

Lẹyin gbogbo alaye yii, a sọ tọkan-tọkan wa pe ki ẹ dakun ki ẹ dariji awọn baba nla wa to ta yin si oko ẹru."

Akintoye sọ pe lootọ lo ṣeeṣe ki inu ṣi ma a bi ẹlẹda awọn ti wọn ta si oko ẹru, tabi ki wọn ṣi ni iporuru ọkan lẹyin ọpọlọpọ ọdun.

O i ṣugbọn ki wọn jọwọ dariji 'awa ti a jẹ awọn arọmọdọmọ awọn to ta yin'.

Bi òwò ẹru ṣe waye nilẹ Africa

Awọn ẹru ti wọn n ko lọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Pupọ ninu awọn ẹru naa lo ma n ku ki wọn to ko wọn de ilẹ Yuroopu

Akọsilẹ iwe itan Encyclopaedia Britannica sọ pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn eeyan ni awọn oyinbo alawọ funfun ra ninu owo ẹru ni ilẹ Africa, ti ko yọ Naijiria silẹ.

Bi irinajo awọn ẹru naa si ṣe ma n lọ re e, paapa nilẹ Yoruba:

  • Eti okun nilu Eko, ni awọn oyinbo alawọ funfun to fẹ ra ẹru ma n duro si
  • Awọn ọmọ Yoruba to jẹ olokoowo ẹru yoo ko ẹru wa fun wọn lati oriṣiriṣi ilu nitosi ati ọna jinjin
  • Ilu Badagry nipinlẹ Eko ni wọn ti ma n ta awọn ẹru naa fun awọn to fẹ ra wọn
  • Niṣe ni wọn ma n so ẹru meji papọ ni ọwọ ati ẹsẹ ki wọn o ma ba salọ
  • Wọn tun le fi okun irin so ọrun wọn pọ lọ sinu ọkọ oju omi
  • Lati eti okun ti awọn oyinbo duro si ni wọn o ti ko wọn wọ inu ọkọ oju omi, nibudo kan ti wọn n pe ni 'ikorita aremabọ' titi di oni

Eyi ni apapọ ẹru ti wọn ko ni Africa lọ si America ati Europe laarin ọdun 16th century si 18th century

Obitibiti miliọnu eeyan ni wọn ko l'ẹru nilẹ Africa
Àkọlé àwòrán, Bi miliọnu mẹfa ẹru ni wọn ko ni Iwọ oorun Africa ti Naijiria wa

Itan sọ pe pupọ ninu awọn ẹru naa lo ma n kú ki wọn to ko wọn de orilẹ-ede Yuroopu ti wọn n ko wọn lọ