Agbebọn tó lé ní ogójì, fipá bá obìnrin kan ṣoṣo lòpọ̀ ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo
Àwọn obìnrin tí agbébọn fipá bá lòpọ̀ ti bímọ tó lé ní 500,000 ní ìpínlẹ̀ kan ṣoṣo

Oríṣun àwòrán, AFP
Iwadi ti awọn agbaagba lẹkun ariwa Naijiria se ti fihan pe awọn ọmọ ti awọn obinrin ti awọn agbebọn fipa ba lopọ bi, lati ipinlẹ Katsina de Zamfara ti to idaji miliọnu .
Ọkan lara awọn agbaagba naa nipinlẹ Katsina, Ọmọwe Bashir Kurfi, lo fidi abọ iwadi naa mulẹ fun BBC lasiko ifọrọwerọ kan.
Ifọrọwerọ naa lo da lori isoro eto aabo to n koju awọn ipinlẹ to wa lẹkun ariwa Naijiria, paapaa, ipinlẹ Zamfara ati Katsina.
Ọmọwe Kurfi ni abọ iwadi ọhun lo da lori awọn iroyin tawọn gba lati awọn abule ti isoro aabo yii kan lati awọn ọdun ti agbebọn ti n bawọn wọya ija.
O ni oun sọ fun ọpọ awọn obinrin lati mu ootọ ọrọ wa nipa irufẹ awọn eeyan to fi tipa ba wọn lopọ.
Iwadii wọn naa si lo sisọ loju rẹ pe awọn abule bii Batsari, Dutsenma, Kankiya, Chiranci, Funtua, Safana ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ni isoro aabo nipinlẹ Katsina.
Ọmọwe Kurfi ni "Awọn ijọba lo n fi ọrọ nipa awọn eeyan to n se atipo pamọ, wọn ko si fẹ sọrọ nipa wọn.
Amọ ojoojumọ lawọn agbebọn n ko ogun ja awọn abule yii, ti wọn si n sọ ọpọ eeyan di alainile lori mọ.
Koda, ọpọ awọn ijọba yii ni ko ni ibudo fawọn asatipo, to si jẹ pe ọdọ ọrẹ ati ẹbi ni ọpọ wọn n fi ori pamọ si.”

‘Isoro aabo kọja ero ẹda, agbebọn ogoji fipa ba obinrin kansoso lopọ lẹẹkan naa’
Nigba to n tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ, Ọmọwe Kurfi ni bi isoro eto aabo to mẹhẹ yii se kanka si, kọja ero ẹnikẹni.
“Bi awọn agbebọn ba se wọnu ile kan, se ni wọn n mu awọn obinrin, to fi mọ awọn iyawo ile.
Wọn yoo kan pe baale inu ile naa ni, pe ko mu awọn aya, ọmọbinrin ati aburo rẹ lobinrin jade.
Se ni awọn agbebọn yii yoo si fi tipa ba awọn obinrin yii lopọ lasiko ikọlu naa,ka ma tiẹ mẹnuba iwa isekupani ọlọgọọrọ ati iwa ipa sawọn obinrin.
Obinrin kan tiẹ wa, ti awọn ọkunrin to le ni ogoji fipa ba lopọ lasiko kan soso.
Wọn maa n lo ọkada to le ni ọgọrun lati fi kọlu abule kan soso pẹlu awọn ohun ija oloro to lagbara.
Ibeere to si yẹ ka maa bi ara wa ni pe bawo ni wọn se n ko awọn ohun ija yii wọle pẹlu awọn oogun oloro ti wọn n mu.”
















