Wo bí òfin 'car park' tuntun tó bẹ̀rẹ̀ ní Eko ṣe kàn ọ́

Oríṣun àwòrán, Other
Ijọba ipinlẹ Eko ti bẹ̀rẹ̀ si ni gba owo ori lori awọn ọkọ tí wọn ba gbe kalẹ si ẹyin odi ile tabi ileeṣẹ nipinlẹ naa. Ẹyin odi naa ti wọn n pe ni 'set back' ni alaafo ilẹ̀ to gbọ́dọ̀ wa laarin ile ati oju ọna. Ọjọ diẹ sẹ́yìn ni awuyewuye kan waye lori ayelujara, nigba ti lẹta kan jáde sori ayelujara, ninu eyi ti ajọ LASPA fí n beere fun ẹgbẹrun lọ́nà ọgọrin Naira lori aye igbọkọsi kọọkan fun ọdun kan, lọwọ ileeṣẹ oúnjẹ kan. Lẹta naa sọ pe owo ori naa wa fun awọn aye igbọkọsi to wa nita ile oúnjẹ naa. Ọgbẹni Adebisi Adelabu to jẹ oludari ajọ LASPA, ṣalaye lẹyin awuyewuye naa pe owo ori tuntun naa ko kan awọn ọkọ tí wọn ba gbe kalẹ si inu ọgbà ile tabi ileeṣẹ.
Ninu ọrọ ti kọmisanna fún eto iroyin nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso, fi sita lori Twitter, lorukọ Adelabu, o ni
Ijọba ipinlẹ Eko da ajọ Lagos State Parking Authority (LASPA) silẹ ni ibamu pẹlu ofin ìgbòkègbodò ọkọ ti ipinlẹ naa ti wọn ṣe lọdun 2018. Oṣù Keje, ọdun 2021 si ni ijọba dá ajọ LASPA silẹ. Ofin naa gbé agbara wọ ìjọba lati ma ṣe akoso bi awọn araalu ṣe n paaki ọkọ wọn jakejado ipinlẹ naa. Ìjọba ni o jẹ igbesẹ to wa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n ṣe ni awujọ agbaye ati eto irinna ni ipinlẹ Eko.
Bakan naa lo sọ pe o jẹ ọna lati fi opin si bí àwọn eeyan kan ṣe n sọ ibi to ba wu wọn di ààyè igbọkọsi, ti wọn si n gba owo lọwọ awọn to n lo o.
Àwọn ojúṣe àjọ LASPA

Oríṣun àwòrán, Nairametrics
Wọn yii ni awọn ojuṣe ti ofin ipinlẹ Eko la kalẹ fun ajọ Lasgos State Parking Authority:
- Tọpinpin bi awọn ààyè igbọkọsi to jẹ ti ijọba ati aladani ṣe n pa ofin irinna mọ
- Gba owo ori lọwọ àwọn aaye igbọkọsi to jẹ ti aladani, àmọ́ to n gba owo lọwọ awọn to ni ọkọ. Èyí ko yọ awọn ààyè igbọkọsi ti wọn ko gba owo lori wọn silẹ, to fi mọ gbogbo ibi ti ajọ LASPA ba ri pe o jẹ aaye igbọkọsi.
- Fun ni ni iwe àṣẹ lati kọ ààyè igbọkọsi aladani (ileeṣẹ, banki, ile itura ati bẹẹ bẹẹ lọ) ati ti ijọba.
Ikede to wa lori ayelujara ajọ naa sọ pe ẹnikẹ́ni to ba fẹ ẹ fi aaye igbọkọsi ṣe oko-owo gbọdọ fi orúkọ silẹ lọdọ oun "nitori ko ṣe e ṣe ki o ma a ṣòwò lai san owó fun ìjọba'.








