Àwọn jàndùkù yabo Aàfin, Ọba Ota Awori sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Other
Awọn janduku ti yabo aafin Oloto ti Oto Awori Kingdom, Oba Aina Kuyamiku ni agbegbe Ijanikin, ni ipinlẹ Eko.
Ọkan lara awọn to ṣoju rẹ to kan si BBC ni awọn janduku naa ni wọn yabo aafin ọba, Ọjọ Kẹẹdọgbọn, Oṣu Kẹjọ, ọdun 2022.
Ọba Aina Kuyamiku lo sa asala fun ẹmi rẹ lọwọ awọn janduku naa, amọ wọn ba awọn ọkọ ayọkẹlẹ to wa ninu aafin naa jẹ, lasiko ikọlu naa.
O ṣeeṣe ki ẹmi eniyan meji ti lọ si iṣẹlẹ naa – Osọjumikoro
Bakan naa ni iroyin gbe pe wọn jo awọn ile itaja lagbegbe naa, ti ikọ ọmọogun si ti wa nibẹ.
Ẹni to ba BBC sọrọ naa ni awọn ọmọ Ọtọ wa ka awọn ọmọ Ijanikin mọle, ti a si ti ri awọn eniyan to farapa ninu iṣẹlẹ naa.
O ni alẹ ọjọ satide ni iṣẹlẹ naa ti bẹrẹ to fi mọ ọjọ Aiku, amọ ti Ọjọba naa lo lagbara ju, ti ẹni naa si ni o ṣeeṣe ki eniyan meji ti gbẹmi mi.
Iṣẹlẹ naa waye ni ijọba ibilẹ Oto-Awori, ti o wa ni opopona Badagry si Eko.








