Ìjọba kéde pé wọn tí gbà ohùn ìjà tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Àjọ to n risi amojuto ohun ija lorilẹede Naijiria ti kede pe awọn ti gba ohun ija orisirisi to to ẹgbẹrun mẹta lọwọ awọn ọdaran pẹlu ìranlowo awọn ọmọ ologun ni Ipinlẹ Delta.
Ajọ naa ni ohun ija naa ni awọn ọdaran kan fi n jale epo rọbi ni abule Fatakwal, tí awọn ọmọ ologun orilẹede Naijiria si koju wọn, tí wọn sì gba ohun ija naa laarin ọdun mẹfa.
Lara awọn ohun ija nani, AK47, FN type, Berreta, G3, Pump ati awọn ìbọn mìíran.
Ninu atẹjade kan ti ajọ naa fi sita, alaga fun ajọ naa, Ọgagun fẹyinti Dikko Abba ni pẹlu awọn ọmọ ologun, awọn ọlọpaa ati awọn ajọ mìíran to risi idabo orilẹede
Naijiria lo wa ni bẹ nígbà ti ajọ tẹ wọgba awọn ohun ija naa ni Fatakwal.

Oríṣun àwòrán, others
Dikko ni bi awọn ṣe gba ohun ija naa lo jẹ ọkan lara isẹ ti ijọba ran awọn, tí awọn sì ti mu wa si musẹ.
O ni ẹtọ ajọ ni lati ripe wọn gba gbogbo awọn ija tí wọn lọwọ awọn ọdaran kakiri lorilẹede Naijiria.
"Erongba ti wọn fi da ajọ yii silẹ ni lati gba gbogbo ohun ija ti ko ba ofin mu, kí wọn si fi pamọ."
Ọgagun Abba Dikko wa dupẹ lọwọ awọn araalu to ṣísẹ pọ pẹlu ajọ láti rí pe awọn ohun ija ti ko ba ofin mu bọ sì ọwọ ajọ naa.













