Ìfaradà àti ìrẹ́pọ̀ ni àwọn olùgbè Okooba n pè fún lẹ́yìn tíjà bẹ́ sílẹ̀ láàrin Olórò àti Kristieni níbẹ̀

Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kò ṣẹlẹ̀ rí láti 100 ọdun ti a ti ń gbé Orò ní OkoOba- Otun Olórò

awon oloro ati soosi oko oba

Awon olori adugbo Puposhola Oko-Oba, ti edeayede ti sele laarin awon olujosin ile ijo and onisese ti se ekunrere alaye oun ti o sele ni oru ojo isegun ni agbegbe naa.

Olori agbegbe naa, Akande Omolayo so fun BBC Yoruba pe awon onisese ti lu agogo pe oro yoo jade ni oru ojo Isegun to kọja.

Ati pe ki enikeni mase wa ni ita rara ni gbogbo oru ọjọ naa.

Sugbon bi oro ti jade, won ri i pe isin n lo ni Truth and Spirit Prophetic Church, to wa ni agbegbe Sanni Taiwo Lawal Street, Gbirinmi, Oko-Oba.

Kini o tun wa ṣẹlẹ̀?

Awon oniṣẹṣe si ni ki Pasito ijọ Truth and Spirit Prophetic Church ati omo ijo ti ilekun won.

Kaka ki won ti ilekun, okan ninu awon olujosin mu agbon, o si sọ mọ ori ikan ninu awon ti o gbe oro naa.

Akande so pe eyi fa ariwo ni adugbo, eje bere si ni jade lori arakunrin naa ti wọn si sare gbe e lọ sile iwosan.

O ni pe ile iwosan bi mefa ti won gbe e lo ladugbo si ko.

Ijo ati Oloro

Bawo ni ọ̀rọ̀ ṣe wa jasi ibi to de duro bayii?

O so siwaju pe nigba ti awon olopaa de, won gbe arakunrin naa lo lati toju ẹ sugbon emi bo lenu re ki wọn to de ile iwosan ijoba.

Igbakeji oloro ti gbogbo iṣẹlẹ naa soju rẹ salaye pe awon oloro fe doju ija ko awon omo ijo ati Pasito wọn, sugbon awon ko gba won laaye ki alaafia le jóba.

awon oloro ati soosi

Kini awon Oniṣẹṣe sọ lori iṣẹlẹ naa?

Okan ninu awon onisese ti o je Otun ilu naa sope iru isele beẹ ko sele ri ni agbegbe naa lati ogorun un odun seyin ti won ti n gbe Oro.

O salaye ipa ti oun gege bi olori onisese ko lati dekun ipaniyan ti awon oloro naa ko ba se leyin ti won se iku pa okan lara won.

Tani Hakeem ọmọ ọkunrin to ṣalaisi naa?

Ologbe to ba iṣẹlẹ yii rin je ẹni odun meedegbon.

Baba oloogbe naa ro ijoba ki won sewadii oro naa daadaa.

Ki won si fi iya to tọ je awon to jebi ọrọ naa.

O tun beere fun iranlowo ijoba nitori oloogbe nikan ni o n toju oun gege bi agbalagba.

aworan ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Èèyàn kàn pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn Olórò àti Krìstìẹ́ni kọlù àrà wọ̀n nípínlè Eko

Edeayede kan waye laarin awọn olujọsin Oro ati awọn kristẹni kan ti o si ṣekupa eeyan kan ni ipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin lo kede ọrọ naa lori opo ayelujara Twitter lọjọbọ ọsẹ yii.

Hundeyin ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti awọn kristẹni ṣe isọji lọwọ.

“O fihan gbangban pe ẹsun ipaniyan ti a si mu ọkan lara awọn afurasi.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Awọn olujọsin Oro ti ṣe ikede pe awọn yoo gbe Oro ni oru mọjumọ.

Nigba ti wọn de ile jọsin naa, wọn ni ki awọn ọlujọsin pa ina, ki wọn dojubolẹ, sugbọn wọn kọ, ti o si jẹ idi ti ija fi ṣelẹ laarin wọn.

Ija naa lo si ṣekupa eeyan kan nibẹ.