Nítorí gbọnmọ-gbọnmọ ìkọlù rògbòdìyàn tó ń wáyé l'Osun, ìjọba, ọlọ́pàá ránṣẹ́ ìkìlọ̀ sí àwọn olóṣèlú, ọlọ́kọ̀ èrò

Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọsun

Oríṣun àwòrán, Gboyega Oyetọla/twitter

Ijọba ipinlẹ Ọsun ti paroko ikilọ ranṣẹ si awọn to n lulu ogun ati ikọlu rogbodiyan ni ipinlẹ naa.

Ijoba ni pe ki wọn lọ ti ọwọ ọmọ wọn b’ọṣọ nitori oun ṣetan lati mu ki wọn jo si ilu naa funra wọn.

Oniruuru iṣẹlẹ ikọlu ati rogbodiyan lo ti n waye ni tẹle n tẹle ni ipinlẹ Ọṣun lẹnu lọwọlọwọ yii.

Lara rẹ ni bi wahala to bẹyọ lẹyin ipade oloselu kan nilu Ẹdẹ ninu eyi ti ọpọ ẹmi ba lọ pẹlu ikọlu si iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun at’awọn ikọ to n ba a kọwọrin laipẹ yii.

Awọn oloṣelu ọlọkọ ero wa lara awọn to n huwa idaluru l’Ọṣun – Ileeṣẹ ọlọpaa

Aworan olopaa kan

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Osun ti kede ikilo.

Won ni pe gbogbo awọn eeyan, paapaa julọ awọn oloṣelu at’awọn ọmọlẹyin wọn pẹlu awọn ọlọkọ ero nipinlẹ Ọṣun gbodo so ewe gbejẹ mọwọ.

Ati pe awọn ti wọn n da wahala silẹ lẹyin eto idibo gomina to waye nipinlẹ naa laipẹ yii gbodo sinmi nitori pe bi wọn ko ba tọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ, wọn yoo fi ẹnu fẹra bi abẹbẹ.