Udeh Meshack Otobo ni ọmọ Benue to n dín àkàrà tà ní Ofa, Ososgbo, Ilorin àti Ife fi n pawó wọlé

Àkọlé fídíò, Udeh Meshack Otobo ni ọmọ Benue to n dín àkàrà tà ní Ofa, Ososgbo, Ilorin àti Ife fi n paw

Sé Lóòtọ́ ni pe Udeh omo Benue yii n lo aisiki àwon onibara rẹ pẹlu akara to n ta?

Nigba ti BBC Yoruba gbọ nipa arakunrin kan ti aye n pe ni akara Yahoo ni a bọ sita titit ti a fi wa a kan ni Ofa ni ipinle Kwara.

Kini o ṣokunfa orukọ akara yahoo ti won n pe ọmọ Benue yii ni Ofa, Ile Ife, Osogbo ati Ilorin?

Udeh Meshack Otobo ni ọmọ Benue to n dín àkàrà tà ní Ofa, Ososgbo, Ilorin àti Ife fi n pawó wọlé

Bawo lo ṣe n din akara rẹ to fi yatọ si ti awọn to ku?

Udeh Meshack Otobo salaye ona to fi n din akara rẹ fun BBC yoruba.

Awọn onibara Alakara Yahoo bii Morenikeji, Omobolanle, Shukura, Abubakar ati awon mii ba BBC sọrọ ni kikun.

Opọ awọn onibara Otobo salaye pe nitori imọtoto rẹ ni awọn se n ra akara rẹ to si fi n ta sii.

Wọn gba awọn ọdọ nimọran lati ronu ohun ti wọn le fi atẹlẹwọ wọn ṣe yatọ si iṣẹ ijọba.

Nitori pe airi iṣẹ se lo gba igboro kan lasiko yii.

Otobo naa sọrọ lori afojusun rẹ fun ọjọ iwaju.