Kété tí mo bí àwọn ìbejì ni ìṣòro bẹ̀rẹ̀ fún mi- Adeyinka Oladimeji 'Iya Ibeji'

Àkọlé fídíò, Iya àwọn aderinposonu ìbejì tí ọ̀pọ̀ mọ sì Twinz Love ṣàlàyé ìrìnàjò rẹ pẹlu awọn ọmọ rẹ

Arabinrin Adeyinka Oladimeji, iya fun awọn gbajugbaja adẹrinposonu tí ọpọ mọ sì Twinz Love salaye fun BBC News Yoruba lórí ọpọlọpọ ìlàkọjá to koju nigba ti o bi awọn ìbejì naa

Moyin ati Doyin ni wọn jẹ adẹrinposoun lori ayelujara, ti wọn si ma pa awọn ololufẹ wọn kẹrin pẹlu iwuwasi iya wọn.

Adeyinka Oladimeji salaye pe kete ti awọn ìbejì pe oṣu mẹta ni baba wọn ni ki awọn gbe wọn lo si ile ọmọ alainiyaa

Iya ìbejì tẹsiwaju pe ni ṣe ni awọn iya ati baba ọkọ oun kọ lati ba oun tọju ọmọ

Ti baba ìbejì sì ni bawo ni oun maṣe bí ìbejì nitori ọna atijẹ di pupọ nigba naa

O ni nígba tí wọn di ọmọ oṣu mẹta ni baba wọn gba oun ni iyanju pé kí awọn gbé ọmọ naa lọ sí ilé awọn ọmọ alaniya

Ọrọ pọ lẹnu iya ìbejì

Ẹ gbọ siwaju.