Orí 'Nylon bag' ni mo ń sùn sí ní Mali tí mo ti n ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó kí ń to sá lọ sí Morocco- Abosede
Oju awọn ọmọbinrin to n rin irinajo lai mọ ohun to wa niwaju n ri to lasiko yii ni ero ọpọlọpọ.
Arabinrin Abosede to wa ni orile-ede Morocco bayii royin ohunt i oju rẹ ti ri to fun BBC Yoruba.
O salaye bi wọn se sọ pe ile Yuroopu ni wọn n mu oun lọ ki o to ba ara rẹ ni Mali.
- 'Ǹkan tí ẹ̀gbọ́n mi gangan ṣe fún mi ní Libya, mi ò kí ń lè sọ fún ìyá mi àmọ́ pẹ̀lú omíjé kíkorò ...'
- "$2,600 àǹtí mi ni mo jí láti lọ sókè òkun àmọ́ àbámọ̀ ló gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ mi"
- 'Tí wọ́n bá bá ẹ sùn tí wọn ò "release" wọ́n á gba owó wọn, àwa la ń ra Kọ́ńdọ́ọ̀mù tí wọ́n fi ń bá wa sùn ní Mali'
- Buhari dá orílẹ̀èdè Libya lẹ́bi fún ètò ààbò tó mẹ́hẹ l'Afrika
- Ó kéré tán, ogún ọkùnrin ló n bá mi sùn lójúmọ́- Adenike Olanipekun
- Azeez ló tà wá láti Nàìjíríà fún Michael ní Libya kí a tò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣẹ́wó lẹ́yìn ti mo ta ṣọ́ọ̀bù ọjà mi- Fatimah
O sọ bi o se bẹrẹ owo aṣewo ati bo ṣe gbọdọ maa san owo pada fun ẹni to muu wa.
Abosede royin bi oun se pada si Morocco leyin to sa kuro ni Mali.
Leyin o reyin o gba awọn ọdọbinrin bii tirẹ ni imoran pe ki wọn rọju ni Naijiria ti wọn wa nitori ko si nkankan nibi.
Sugbon Abosede sọ pe oun ko le pada si Naijiria mọ nitori o ṣi san bi oun se wa ni Morocco ju iya to wa ni Naijiria lọ.
O tun salaye pe nitori ọmọ oun ni oun ṣe n farada gbogbo iya yii.
O ni ọpọ igba ni oun ti ronu lati pa ara oun.