Mali sex slave returnee: Báàlù la rò pé a máa wọ̀ lọ Mali, ìrìn òṣù kan gbáko lá rìn láti Togo dé Mali

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'

Ọ̀jà Bùtíìkì ní Ọ̀rẹ́-ẹ̀gbọ́n-ọ̀rẹ́ mi tí mo ń bá sọ̀rọ̀ lórí fóònù ní òun yóò mú mi lọ máa tà ní Mali amọ́..."

Irọ n gori irọ ni wọn fi mu Omolara Abiyeye atawọn ọdọbinrin kan lọ ṣe owo aṣẹwo ni orilẹede Mali.

Omolara Abiyeye sọ iriri rẹ nibi owo aṣẹwo ti wọn mu u lọ ṣe ni Mali fun BBC Yoruba.

Omolara Abiyeye

Arabinrin yii ni ọrẹ ẹgbọn ọrẹ oun kan ti oun ti maa n ba sọrọ lori foonu lo sọ fun oun pe wọn nilo awn eeyan ni Malaysia lati maa ta ja aṣọ.

Amọ o ni ẹni naa jẹ ko di mimọ fun oun pe wọn ti ti ẹnu ibode Naijiria ti awọn yoo gba kọja nitori Covid-19 torinaa Togo lawọn yoo kọkọ gba lọ.

Ọmọlara ni ọkunrin dẹrẹba to wa ọkọ to n ko wọn rin lo sọ ọrọ kan to mu oun bẹrẹ si ni fura ni ede Pidgin pe "Ọlọrun yoo ṣọ ẹ o".

Lootọ lo ni ẹni ti wọn n pe ni "Manager" fi ọja kan han awọn to ni awn yoo ti maa ta ọja amọ wọn tun ko awọn lọ si abule kan ti wọn fi ọra kọ ile to si ni awọn lawọn yoo san owo rẹ.

Obinrin to ko wọn lọ pada sọ fun Omolara pe kii ṣe Malaysia lo n lọ kii sii ṣe ja lo n lọ ta bi ko ṣe iṣẹ aṣwo ni Mali.

"Àwa la máa ṣíṣẹ aṣẹwó láti san owó yàrá táa ń gbé, oúnjẹ tí wọn ń fún wa àti owó tí wọn fi rà wá láti Nàìjíríà".

Ó ni pẹlu Condom ati Wipe ti ọkunrin yoo lo lati ba awọn sun, owo ara awọn lawọn fi n ra a.

"Bi wọn ba ba ẹ sun nibẹ yẹn lai da oje nkan mọkunrin wọn si ẹ ninu ara, wọn a gba owo wọn pada koda ọga wa ko le ṣe nkankan afi ko tun lu ẹ.

Lati ilu kan si abule mii ni wọn n gbe e lọ lati ṣe iṣẹ aṣẹwo titi to fi lo ọdun meji ki ọkunrin kan fi ran an lọwọ lati sa lọ.

Obinrin ti wọn lọ fi ṣowo ẹru

Omolara ni ọkunrin ti oun n fẹ ni Naijiria ki oun to lọ naa ni oun fẹ pada nigba ti oun de amọ ọrọ awọn ti kun fun ija ati asọ bayii tori pe aṣiri nkan ti oun lọ ṣe ni Mali ti tu sii lọwọ.

O n bẹbẹ fun iranwọ latọdọ ẹnikẹni to ba le ran an lọwọ ni tootọ tori iya lo gbee de idi to fi lọ si Mali ko si fẹ ki iya yii kan naa jẹ awọn ọmọ rẹ.