Oluwo of Iwo land God Festival: Jumoke Odetola bá Oluwo pé Ọba Yorùbá kìí ṣe aláṣẹ ìkejì Orìṣà mọ́ látòní lọ

Oríṣun àwòrán, Oluwo of Iwo
Lara awọn eekan ti Oluwo tọka si pe wọn baa pe nibi ayẹyẹ Ọdun Ọlọrun Ọba to waye ni ilu Iwo ni Woli Samson Oluwamodede to jẹ gbajugbaja ni ilu Akure, awọn lọbalọba ilu, Jumoke Odetola to jẹ gbajumọ ọdọ oṣere fiimu Yoruba, atawọn ẹlẹgbẹ n jẹgbẹ latinu ẹsin Kristẹni ati Musulumi.
Oṣere Jumoke Odetola nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ sọ pe Ọdun naa jẹ pataki gan nilẹ Yoruba gẹgẹ bi eleyi ṣe jẹ akọja ewe ayẹyẹ naa.
O tun ṣalaye idi ti oun naa fi yan lati lọ yẹ Oba Abdulrasheed Akanbi si nibi ayẹyẹ ọhun pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹsin Kristẹni lo n ṣe.
"Lootọ ẹlẹsin Kristẹni ni mi amọ mo nigbagbọ ninu Mẹtalọkan bẹẹ si ni eredi fun ayẹyẹ yii naa ni pe ọkan ṣoṣo ni Ọlọrun Ọba.
O dara lati maa yin Ọlọrun pupọ, o da bii ki eeyan kan maa ṣeeyan loore ni ki ẹni naa ma wa mọ oore, inu oloore rẹ ko le dun".
Nibi eto yii la ti rii ti Oluwo ti Iwo gbe ẹrọ gbohun-gbohun to ṣẹṣẹ lo tan fun oṣere Jumoke Odetola pe ki oun naa kọ orin soke.
Bi awọn ẹlẹsin Islam ṣe n gbe Ọlọhun tobi lawn Kristẹni naa n sọ orin ogo nibi ayẹyẹ ọhun.
"Ọlọrun nikan la fẹ yin, Ọlọrun nikan la fẹ fọpẹ fun, ẹnikẹni to ba fẹ sọrọ níbi ko ma darukọ oriṣa kankan nibi o"!
Oluwo ti ilu Iwo ni oun kọ ni Ọba, Ọlọrun nikan ni Ọba, Ọlọrun nikan si ni awọn wa yin nibi ayẹyẹ Ọdun Olrun Ọba.
Oluwo n sọ eyi ninu ọrọ akọsọ rẹ nibi eto ayẹyẹ Ọdun Olọrun Ọba.
Ṣaaju nigba ti Oluwo kọkọ kede pe oun yoo ṣe ayẹyẹ yii, akọle to pee ni "Ọdun Olodumare" amọ nigba to ya, Oluwo yii pada si "Ọdun Ọlọrun Ọba" fun idi to jẹ wipe Kabiyesi nikan lo mọ.
O ni Ọba alade ko le maa jẹ igbakeji Ooṣa gẹgẹ bi awọn Yoruba ṣe maa n ki awọn Ọba nilẹ Yoruba. "Ko si alaṣẹ ikeji Ooṣa kankan, ẹru ni Ooṣa gbudọ jẹ fun Ọba".
Oluwo ni o maa n ṣẹlẹ tẹlẹ nilẹ Yoruba amọ kii ṣe isinsinyii mọ. O ni ṣe wọn o rii bi awọn ẹlẹsin Kristẹni ati Musulumi ṣe jọ joko papọ nibi ayẹyẹ naa pe ṣe ko dara bẹẹ ni.
Nipa igbinyanju lati rii pe isọkan wa larin awọn ọmọ Oduduwa lai wo ẹsin tabi igbagbọ ni o jẹ ọkan gboogi fun ibẹ̀rẹ̀ Odun Olorun Oba ni llu Iwo.

Ọpọ eniyan lo peju si ilu Iwo lati ba Oba AbdulRasheed Adewale Akanbi yọ Lara awọn to peju sibẹ ni awọn ẹlẹsin Kristẹni, Musulumi, ẹlẹsin abalaye, awọn lọba lọba, Pasitọ atawọn Alfa nla nla. Bakan naa gbajugbaja ọdọbinrin oṣere Jumoke Odetola wa nibẹ.Nibẹ naa lati ri awon ẹlẹsin Kristi, ẹlẹsin Musulumi ati esin Abalaye ti wọn jọ n kọ awọn orin Kristẹni ati Musulumi papọ.
















