Kidnapping in Ekiti: Àwọn ajínigbé kó sí gbaga ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti

Ekiti kidnapping

Oríṣun àwòrán, ASP Sunday Abutu

Ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri iṣẹlẹ pajawiri, RSS, ni ipinlẹ Ekiti ti fi ṣikun ofin mu okunrin kan, Ogunyemi Bunmi, ti wọn fẹsun kan pe oun ini olori awọn ajinigbe ni ipnlẹ naa.

Nigba to n ṣi aṣọ loju eegun afurasi naa atawọn afurasi mii, alukoro ileeṣẹ ọhun, ASP Sunday Abutu sọ fun awọn akọroyin pe ilu Ikere Ekiti ni ọwọ ti tẹ afurasi ọhun, to jẹ ọmọ oloye kan niluu Ado-Ekiti.

Abutu sọ pe afurasi naa jẹwọ ni agọ ọlọpaa pe oun lo wa nidi ijinigbe oniṣowo epo bẹntiro kan, Alhaji Suleiman Akinbami niluu Ado-Ekiti, ati aya olori awọn wọnlẹ-wọnlẹ ni ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Osalusi Dapo, to fi mọ ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Olowo Bolaji niluu Ipoti-Ekiti.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ yé tan ara yín, èmi mo ni aṣọ 100 yard tó jábọ́ lát'ọ̀run táwọn ará Ondo ń ya mọ́ ara wọn lọ́wọ́'

Afurasi ọhun mu awọn agbofinro lọ si ibi ti oun atawọn ẹmẹwa rẹ n fi ori pamọ si, to tun jẹ ibi ti wọn maa n ko awọn ti wọn ba ji gbe pamọ si.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa fi kun pe ikọ afurasi naa jẹwọ pe awọn lo ji oloye kan, Ajayi Abiodun gbe.

Oloye naa jade laye lasiko to n gbiyanju lati moribọ lọwọ awọn ajinigbe ọhun to si fo jade kuro ninu ọkọ nigba ti wọn gbe lọ sinu igbo kan ni ipinlẹ naa.

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole

Abutu kede orukọ awọn ọmọ ikọ ajinigbe naa gẹgẹ bii Banji Akeem ti apẹle rẹ n jẹ Yellow; Jimoh Dele, ti wọn n pe ni Dele Detim; Johnson, ti wọn n pe ni Yellow Okada ati Dayo Igwe to ti na papa bora.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, ileeṣẹ ọlọpaa ti n ṣiṣẹ takun-takun lati mu awọn ọmọ ikọ naa to ti na papa bora ati lati fọ ipinlẹ naa mọ.

Lara awọn ohun ti wọn ri gba lọwọ awọn ajinigbe ọhun ni ibọn ibilẹ, ọta ibọn ati ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan.

Lẹyin naa lo gba awọn araalu nimọran lati maṣẹ dakẹ gbera ti wọn ba kofiri iwa ọdaran lagbege wọn.

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'