Lateef Adedimeji weds Bimpe Oyebade now: Àwa fúnra wa ti dájọ́ ìgbéyàwó wa sọ́ná lóòtọ́ kí gbogbo "bloggers" lọ sẹ́mpẹ́

Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Lateef Adedimeji ati Adebimpe Oyebade ti jọ fi aṣọ igbeyawo ya fọto ri.
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ohun to n tan lọdun eegun, irọ ni abi ootọ, Ṣé awọn Lateef Adedimeji ati Bimpe Oyebade tun n gbe wa mọra ni?

Ko si awuye wuye kankan mọ pe oṣere Lateef Adedimeji ati ẹni ti wọn jọ n pe ara wọn ni ọrẹ ti fẹ so okun ifẹ wọn pọ bayii.

Gbajumọ oṣere meji laarin awọn oṣere fiimu yoruba ti wa sọ gbangba bayii pe awọn ti da ọjọ igbeyawo sọna lẹyin ọpọlọpọ ariyanjiyan to ti bẹ silẹ lori igbeyawo wọn.

Kii ṣe laarin awọn mejeji o bikoṣe laarin awọn ololufẹ wọn!

Àkọlé fídíò, Bí mo ṣe káa sára tí mo gbé òkú ọmọ sínú ọkọ̀ lọ ṣe iṣẹ́ apanilẹ́rìín láì fihàn - Woli Agba Ayo Ajewole
Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Adebimpe Oyebade

Gẹgẹ bi iroyin ṣe tun n fọn kiri ori ayelujara bayii nipa igbeyawo wọn amọ ti kii ṣe ọrọ ẹnu lasan lọtẹ yii amọ pẹlu iwe ipeni sibi ayẹyẹ lo mu ki awọn eeyan bẹrẹ si ni gba pe lootọ ni o.

Nigba ti o n ba BBC Yoruba sọrọ laarọ yii, Lateef Adedimeji ni "kii ṣe tuntun ko si ki n ṣe iroyin ofege pe a fẹ ṣe igbeyawo, awa funra wa ti fii sita fun awọn taa fẹ fi sita fun".

Àkọlé fídíò, 'Wọ́n gba irun abẹ́ wa, irun abíyá wa, a lọ búra, ilé "Nylon" la tún ń gbé ni Mali fi ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó'
Lateef ati Adebimpe

Oríṣun àwòrán, Adebimpe Oyebade

Adedimeji ni nitorinaa ẹni to fi iwe ipeni sibi ayẹyẹ igbeyawo awọn sita kan ṣe ohun to pe e lasan ni amọ kii ṣe tuntun".

Bo tilẹ jẹ pe Adedimeji ni oun ko tii ṣe tan lati ba awọn oniroyin sọrọ lasiko yii amọ ki awọn eeeyan maa foju sọna funrawọn.

"Iwe ipe wa yoo tẹ awọn to ba yẹ ko wa lọwọ. Naijiria to jẹ orilẹede ti ko lofin lo faa ti awọn eeyan ṣe n gbe nkan to wu wọn jade lọna to wu wọn".

Bakan naa ninu fidio kan ti ọkan lara awọn ojugba iyawo, Bimpe Akintunde fi sita, o n fi orukọ ọwọ rẹ han ti ẹni to fi sita naa si n kii ku oriire.

Ọpọlọpọ eebu ati ija gidi lo ti gori ara wọn lori ayelujara ati lojukoroju laarin awọn to fẹran lati maa wo ere itage awọn ololuf mejeji yii.

Awọn ololufẹ wọn a maa beere pe, ṣe o ṣeeṣe ko jẹ pe wọn ti ṣe igbeyawo ni tootọ?

Lọpọ igba naa si ni oniruuru aworan ti jade ti Bimpe ati Lateef ti wọ aṣọ igbeyawo, yat fun eleyii, ọpọ igba ni wọn ti ṣafihan bii pe wọn jẹ lọkọ laya ni tootọ amọ bi eeyan ba bi wọn, wọn a ni irọ ni.

"Bii ẹgbọn lasan ni Lateef jẹ si mi", eyi ni ọrọ to ti jade lẹnu Bimpe Akintunde ri nigba ti eeyan ba bii pe ki lo wa laarin wọn.

Fun apẹrẹ lori ifọrọwanilẹnuwo ti Bimpe ti ṣe pẹlu BBC Yoruba ri, o ni oun ko fẹ sọ ohunkohun nipa ibeere ti ọpọ awọn to n wo o beere lọjọ naa.

Fun apẹrẹ, laipẹ yii ni Bimpe Akintunde ṣe ọjọ ibi rẹ to jẹ pe fidio ti Lateef fi sita lowurọ kutu fihan pe inu ile kan naa ni wọn ti jọ ji ti awọn eeyan si n ba wọn ṣe ajọyọ.

Yatọ fun eleyii, ọpọlọpọ aworan ati fidio ipolowo ọja ni awọn mejeeji ti ya ninu eyi ti wọn a di mọra wọn gbagi tabi sunmọ ara wọn pẹki pẹki bii ọkọ atiyawo.