Lagos bulding collapse: Mo gbàdúrà kí Ọlọrun tu gbogbo ẹbí Osibona nínú - Abiodun

Oríṣun àwòrán, Prince Dr. Dapo Abiodun - MFR
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti ṣabẹwo si oloye Emmanuel Osibona, to jẹ baba to bi Femi Osibona to kọ ile alaja mọkanlelogun to da wo niluu Eko.
Abiodun lo kede ọrọ naa loju opo Facebook rẹ, to si fi aworan bo ṣe baba agba naa kẹdun iku ọmọ rẹ lede.
O ni "Lalẹ ana ni mo ṣabẹwo si Baba Ijọ Our Saviour's Anglican Church to wa ni Ikene, oloye Emmanuel Osibona, to jẹ baba oloogbe Olufemi Adegoke Osibona."
- Ṣé lóòtọ́ ni Lateef Adedimeji àti Bimpe Oyebade fẹ́ ṣègbéyàwó lọ́tẹ̀ yìí lóòtọ́? Lateef bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀
- Ọmọ Nàìjíríà ẹ múra sílẹ̀, ǹkan yóò le ju báyìí lọ lọ́dún 2022 - Primate Ayodele sọ tẹ́lẹ̀
- Ẹ má ṣe ẹ̀dà ọ̀rọ̀ mi o àmọ́ ṣe ó dáa yín lójú pé Nàìjíríà yóò ṣì wà lọ́dún 2023? - Adeboye
- ''Mo ti gbàdúrà fún àànú láti r'ọ́run wọ̀ lẹ́yìn tí mo wà lábẹ́ ilé tó wó ní Ikoyi fún ọjọ́ kan''
- Ọwọ́ tẹ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba méjì tó ta ọmọ aláàrùn ọpọlọ ní N1m l'Ondo
- Àwọn ọkùnrin wá kọ̀ láti ṣe- Ìdí tí àwọn obìnrin ṣe n tọ́jú ibòjì okú ni abúle kan
- Aláàfin Oyo mú àyọ̀ bá àwọn ọmọdé méjì tí wọ́n jí gbé, bó ṣe fojú wọn kàn òbí wọn rèé
- Bí èsì ìbò gómìnà ṣe ń jáde lọ́wọ́ ní Anambra
- Erin wó! Orí Adé kan ti wàjà l'Oyo
- Sanwo-Olu ṣèlérí ìrànwọ́ owó fún ètò ìsìnkú tó dára f'àwọn tí ilé alájà 21 wó pa ní Ikoyi
"Ọgbẹni Osibona ni alaṣẹ ileeṣẹ Fourscore Homes to jade laye lẹyin to ha sabẹ ile alaja mọkanlelogun to da wo naa."
Abiodun tẹsiwaju pe "Mo ba Baba kẹdun lori iṣẹlẹ ibi naa, mo si tun gbadura pe ki Ọlọrun tu oun atawọn mọlẹbi ninu lori iṣẹlẹ laburu naa."

Oríṣun àwòrán, Prince Dr. Dapo Abiodun - MFR
Ti ẹ ko gbagbe, ọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdun 2021 yii ni ile naa dawo, to si wo pa nnkan bii ogoji eeyan, bo tilẹ jẹ pe wọn ri awọn eeyan gbe jade labẹ ile ọhun laaye.
Lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ ni ọpọ oṣiṣẹ to n ṣiṣẹ ninu ile naa lasiko to da wo, to fi mọ Femi osibona to ni ile naa.
Lẹyin ti ile ọhun dawo, ọpọ eeyan lo sọ pe igb akeji Aarẹ, Yemi Osibanjo lo ni ile ọhun lẹyin to ra ile rẹ lọwọ baba olowo, Micheal Ade Ojo ti ọpọ mọ si Elizade.
Ṣugbọn Osibanjo ati Elizade ti sọ pe awọn ko mọ nnkankan nile naa, ati pe awọn kọ ni wọn ni.
















