Àwọn ọkùnrin wá kọ̀ láti ṣe- Ìdí tí àwọn obìnrin ṣe n tọ́jú ibòjì okú ni abúle kan

Oríṣun àwòrán, Empics
Kò sí ẹni tó le ròó pé, àwọn obìnrin ní yóò ma tún ibòjì òkú ṣe.
Sùgbọ́n èyí ní nǹkan ti ó n ṣẹlẹ̀ ní àbúlé kan ní ìpínlẹ̀ Kano
"Tí a bá sọ fún àwọn ọkùnrin láti ṣe é, kí wọ́n gé kóríko, wọn kò ni dáhun, nítorí ìdí èyí ni à ṣe ń ṣee fúnra wa.
- Àwọn ojíṣẹ́ Ọlọ́run tó yí Buhari ká kò bá a sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀- Afenifere
- Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbẹ́jọ́ Baba Ijesha
- Mo kúrò ni ṣọ́ọ́ṣì kan nígbà tí Pásítọ̀ ń bú Buhari - Femi Adesina
- Gómínà díbọn lọ ilé ìwòsàn, òṣìṣẹ ìlera tó gba rìbá N10,000 wọ gàù
- Ọwọ́ tẹ àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba méjì tó ta ọmọ aláàrùn ọpọlọ ní N1m l'Ondo
Nǹkan tí Hajiya Raliya Yahaya, tó jẹ́ adarí àwọn obìnrin tí wọ́n pè ni (Kungiyar Matar Musulumi) ni Kano ṣàlàyé fún akọròyìn BBC pé wákàtí mẹ́rin ni àwọn fi máa n lọ ṣiṣẹ́ ni itẹ́ òkú lópin ọ̀sẹ̀.

"lópin gbogbo rẹ̀,ibojì òkú náà ni gbogbo wa yóò darí sí, nítorí náà o dàbi ìgbà tí a n ra ara wa lọ́wọ́ ni"
Láti bi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn ló ni àwọn obìnrin mẹ́wàá kan ti kó àra wọn jọ tí wọ́n si fi ọjọ̀ sátide àti Aiku wọn sílẹ̀ láti lọ tọ́jú ibòjì okú láàrin aago méje àárọ sí aago mọ́kànlá ọ̀sán.
Wọ́n yóò gbálẹ̀, ro gbogbo koríko to ba wà níbẹ̀àti gbogbo ìdọ̀tí.
Bí wọ́n se bẹ̀rẹ̀
Hajiya Raliya tọ pàdánù ọkọ rl ni odùn díẹ̀ ṣẹyìn lo kórajọ ps pllú àwọn obìnrin mííràn nínú ẹgbẹ náà ti àwọn obìnrin tó ku to ti gbààyè lọ́wọ́ ọkọ wọn láti jade lọ ṣe iṣẹ́ náà.

"Èmí nikan ni ọkọ̀ mí kú, gbogbo àwọn obìnrin mẹ́sàn tó kú ló n gba àa[yè lọ́wọ́ ọkọ wọn kí wọ́n tó jáde wá, tí ọkọ wọ́n ko bá fún wọ́n láàyè, wan ko le jáde"
"Ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀. àwọn ọkùnrin kọ̀ọ̀kan máa n wá láti woran, sùgban nígbà míírà wan le ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ díẹ̀ kí wan tó lọ"
O ṣàlàyé pé àwọn ọkùnrin ṣe àkíyèsí pé àwọn obìnrin náà n ṣe nǹkan ti ọkàn wọ́n fẹ́ ni wọ́n ṣe gbà wọ́n laáàyè, àti pé òn mọ̀ pé èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́run.
"Ìwọ ti ẹ̀rù bá n bá, má bẹ̀rẹ̀ rárá..."
Lórí àwọn irinṣẹ́ ti wọ́n ń lò, adari wọn ni wọ́n máa n ya lọ́wọ́ àwọn ọkọ wọn ni
"Ìpèníjà tó lágbára jù fún wa ni pé kò sí ọ̀gbà tó yí ibòjì okú náà káọ̀pa oníru'rú ẹrànko si ló máa n wọ ibẹ̀ láti bàá jẹ́, nígbà míírà lọ́ja sátide, à máa n lo àsìkò tó pọ̀ láti yọ igbé ẹṣin kúrò nínú ibòjì.

Akọ̀ròyìn BBC Mansur Abubakar to fọ̀rọ̀ wá Hajia Raliya lọẹ́nuwò, ṣọ pé àwọn obìnrin náà kìí bẹ̀rù tàbi pé wọ́n ń ronu lílá àlákálà nítorí pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ ni ibòjì òkú.
"Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni mo tí n sọ fún àwọn obìnrin náà pé, tí ẹ̀ru bá n bà wọ́n kí wọ́n má wulẹ̀ darapọ̀ mọ ẹgbk náa nítorí mo mọ̀ pé kìí ṣe gbogbo ènìyàn ló bá lára mu láti m''a ṣe iṣẹ́ nibi ti òkú wà.
Sugbọ́n ó wá padà fí ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ìgbà tí àwọn ọkùnrin kọ láti se ni àwọn ṣe ń ṣe é.
"Bí àwọn ọkùnrin wa bá faramọ láti máá ṣe lónìí, à ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀ láti lọ máá tọ́jú ilé àti ẹbí wa













