Baba Ijesha rape case: Ilé ẹjọ́ ti sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ Kejìlá oṣù yìí

Baba Ijesha ni ile ẹjọ

Igbẹjọ Baba Ijesha ti n tẹsiwaju nílé ẹjọ gíga to n gbọ ẹsun ifipabanilopo to wa ni Ikeja, niluu Eko.

Ikọ olupẹjọ mu ẹlẹri kan wà ṣiwaju adájọ lati sọ ohun ti oju rẹ tó nípa igbẹjọ náà lónìí.

Ẹlẹri ọhun to jẹ ọlọpaa, ASP Wahab Kazeem sọ pe oun loun ṣe ìwádìí ẹsun ti wọn fi kan Bàbá Ijesha.

Kazeem ni awọn gba ohun afurasi silẹ lórí ìwé ati lori fidio ti wọn fi ẹrọ ilewọ ya.

Ọ ni ìwádìí awọn fi hàn pé ọmọ kékeré ti ọjọ ori re ko ju mẹrinla lọ ní Baba ijesha fi ọwọ kan.

Baba Ijesha gunlẹ si ile ẹjọ

Ọ fi kun pe afurasi, ìyẹn Baba Ijesha jẹ́wọ́ fún àwọn pe lóòtọ ni oun fi ọwọ kan ọmọ naa lọnà tí kò tọ.

ASP Kazeem sọ níwájú ilé ẹjọ náà pé, ẹlòmíràn, ti wọn pe orúkọ rẹ ni Abigael so fún àwọn pe Baba Ijesha ba oun ṣe aṣemáṣe nigba ti oun wa ni ọmọ ọdún méjìlá, ṣugbọn Baba Ijesha ni irọ ni ẹsun náà.

O fi kun pe awọn ṣe ìwádìí ẹsun Abigael yíì lọ sí ilé tí afurasi naa n gbe tẹlẹ lagbagbe Ajah, nílùú Eko, ti ẹni tó ní ilé ọhun sí sọ pé lootọ ni Baba Ijesha n gbe ile naa tẹlẹ.

Princess ni ile ẹjọ

Ìkọ olupẹjọ ti fi ọrọ ti onile Baba Ijesha ni Ajah kọ, to fi mọ ọrọ arabinrin Abigeal ati ọrọ Baba Ijesha lelẹ gẹgẹ bíi ẹrí, ìyẹn exhibit nile ẹjọ náà.

Ṣugbọn agbẹjọro Baba Ijesha sọ pé kò yẹ ki ilé ẹjọ gba ọrọ naa wọlé nítorí onibara oun kọ ọrọ naa lẹyìn tí àwọn ọlọ́pàá tí kọkọ lu ni ilubara.

Ewe, ile ìjọ ti gba ọrọ naa wọlé gẹgẹ bíi "Exibit K."

Princess gunlẹ si ile ẹjọ

Leyin náà ni ikọ olupẹjọ ṣàfihàn fọran kan níwájú adájọ, ninu fọran náà ni wọn ti n fi ọrọ wa afurasi lẹnu wò, nibi ti afurasi ti n sọ pé "Mo fi ọwọ kàn ọmọ náà."

Ṣugbọn olori agbẹjọro Baba Ijesha, Babatunde Ogele ni ẹrí náà ko l'ẹsẹ nilẹ nítorí agbẹjọro afurasi kò sí níbi tí wọn ti n fi ọrọ wa lẹnu wò, eyiti ko ba òfin mu.

Lẹyinorẹyin, adájọ Oluwatoyin Taiwo to n gbọ ẹjọ náà ti sun sí ọjọ Ẹtì, ọjọ kejìlá, oṣù yìí ki àwọn olupẹjọ le mu awọn ẹlẹri to kù wá, tii ṣe awọn ọlọpaa to kọkọ n ṣe iwadii ọrọ náà.