Femi Adesina: Àwọn pásítọ̀ mííràn ti sọ orí pẹpẹ di ibi ti wọ́n ti ń ba ìjọba l'Órúkọ jẹ́

Bí mó ṣe kúrò ni ilé ìjọsin kan nítórí pé Pásítọ̀ ń bú ààrẹ Muhammadu Buhari-Femi Adesina

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina/ Facebook

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì fún ààrẹ Muhamadu Buhari lórí ìròyìn àti ìpolongo, Femi Adesina ti ṣàlàyé bi òun ṣe kọ láti ma lọ sí ilé ìjọsin kan nílú Abuja nítorí bí pásítọ̀ náà ṣe n tako ààrẹ Buhari.

Pásítọ náà n ba ààrẹ Buhari lórúkọ jẹ́ lásìkò tó n wàásù, mo si kẹyin si lilọ si sọọsi rẹ.

Adesina sọ èyí nínú ọ̀rọ̀ àpilẹkọ tí o pe àkọ́lé rẹ̀ ni " This Kumuyi is simply different" èyí tí o maa n kọ ni ọ̀sọ̀ọ̀sẹ.

Nǹkan ti o kọ ọ̀rọ̀ naa le lórí ni adari àti olùdásílẹ̀ ijọ Depper Life Bible Church Pásítọ̀ William Kumuyi, to ni o maa sọ òótọ́ nípa bi onígbàgbọ́ ṣe yẹ ki o máa ṣe si ìjọba orílẹ̀-èdè wọn

Ó sọ bi Kumuyi ṣe sọ nígbà kan pe "Ti o ba gba jesu gbọ ni tòótọ́, o ni kóríra alábágbé rẹ, tábi ki o má ni ìkóríra sí àwọn tó wà ni ìjọba nítórí wọ́n ko ṣe nǹkan ti wọn jẹ́jẹẹ́ lásìkò ìpòlongo ìbò, nítorí náà, kí wọ́n máa ba nǹkan iní ìjọba jẹ́.

Àkọlé fídíò, Mesach Oyediran: Ọba ni Dafidi tó ń lu dùùrù, tó sì kọ sáàmù, ta ni èmi tí kò ní le yin

Adesina sọ pe, ìhà ti Kumuyi wà yìí tako iwa ọ̀pọ̀ àwọn adarí ìjọ mííràn, ti wọ́n maa n lo ipò wọn láti ba orúkọ ìjọba jẹ́, tí wọn a si tun máá fi ọ̀rọ̀ wọn ru àwọn ọmọ ìjọlaya soke láti hùwà ipá sí ìjọba.

Láti fi ìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀, Adesina sọ ìrírí rẹ̀ lásìkò kan tó lọ sí ilé ìjọsìn kan ní Abuja ati bi òun ṣe kúrò kúrò lásìkò ìsìn nítorí pé pásítọ̀ náà n bú ààrẹ Buhari.

Adesina ni, ọ̀pọ̀ àwọn oníwààsú ti sọ ilé ìjọsin di ibi ti wọ́n ti n polongo ìrunú àti ibínú sí awọn alásẹ. Wọ́n a maa wàásù ìròyìn òfégè lọ́sẹ̀-ọ̀sẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Mo mọ nǹkan tí mò n sọ, Mó n lọ sí ilé ìjọsìn kan nílùú Abuja láti ọdún 2015 si 2018, títí ti pásítọ̀ ìjọ náà fi ri ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ ìránṣẹ́ tí yóò má wó ìjọba Buhari lulẹ̀.

Ọjọ́ Aiku si ọjọ́ Aiku, gbogbo ìgbà lo máa n tako ààrẹ Muhammadu Buhari, mo ṣa n fara mọ nítori pe ó jẹ́ ẹ̀ka ìjọ tí mo ti ń lọ fún odidi ọgbọn ọdún.

Àkọlé fídíò, Sunday Igboho Herbalist: Agbófinró mẹ́fà ló wọ́lé wá gbé ọmọ mi láì mọ́ ibi tó wà

Nígbà tí o di ọjọ kan, o bá se àṣejù, wọ́n ji àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ Dapchi gbé, ko wá sí orúkọ tí pásítọ̀ yìí kò pé ààrẹ Muhammadu Buhari, ó bá ni lọ́kàn jẹ́ láti má gbọ́ pé orí pẹpẹ nínú ìjọ ni irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ tí n jáde.

Mo fara dàá titi, mo ròó pé ṣe bí ìwásùú ló yẹ kí ó jẹ́, mo wá lọ sí ilé, mo ròó títí pé kí ni ìjọ Ọlọ́rùn ń yí sí.

" Tí ẹ o bá gbàgbé, wọ́n rí àwọn ọmọ Dapchi gbà padà láàrín ọ̀sẹ̀ mẹ́fà, yàtọ̀ sí Leah Shribu àti àwọn díẹ̀ kan. Ó ba ni nínú jẹ́, sùgbọn ààyè ọ̀pẹ́ sì yọ náà.

Ní ọ̀ṣẹ̀ tó tẹ̀lé, mo lọ si sọ́ọ̀si, mó ń reti láti gbọ́ nǹkan ti pásítọ̀ yóò sọ, pẹ̀lú irú àwọn ọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ tó tí sọ ni ọjọ́ Aiku tí ó kọjá nígbà ti àwọn ọmọ náà sì wà nínú ìgbèkùn.

Sùgbọ́n nǹkan tí ó jọmí lójú ni pé, pásítọ̀ yìí kò sọ ọ̀rọ̀ kan nípa àwọn ọmọ tí wọ́n ri gbà pada yìí, nǹkan ti ó burú ni."

Bí ó bá jẹ́ onígbàgbọ́ nítòótọ́, tó ni ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi, kò ní yọ̀ nínú ìkóríra sí ọmọnikejì rẹ, tàbí kóríra àwọn tó wà ní ìjọba.

Adesina wa ṣe àpèjúwé pásítọ̀ Kumuyi bí pásítọ tí kìí fárí apá kan, dá apákan sí.

Àkọlé fídíò, Ooni: A kìlọ̀ fún Sunday Igboho pé kó dákẹ́ àmọ́ kò gbọ́, èébú ló ń bú wa