Femi Adesina: Afenifere àti Ohaneze Ndigbo fún Adesina lésì bó ṣe fi Buhari wé Awolowo, Azikwe

Oríṣun àwòrán, Femi Adesina
Awọn oniruuru ẹlẹgbẹjẹgbẹ ni Naijiria lo ti n fun oludamọran si Aarẹ Buhari, Femi Adesina lesi, lori bo se ni araalu nifẹ Buhari ju Awolowo ati Azikwe lọ.
Lara awọn ẹgbẹ to fun Adesina ni esi ọrọ rẹ pada ni Afenifere ati Ohanaeze Ndigbo.
Ọjọ Ẹti ni Femi Adesina kede fun araye pe awọn araalu nifẹ aarẹ Muhammadu Buhari pupọ, ti ero tuulu si maa n jade lati yẹ si nigba kuugba to ba se abẹwo si agbegbe kan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Bimbo Oshin ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọkọ rẹ̀ sọ fun un kó tó kú
- Ta ni Ola Ibironke, ọkọ Bimbo Oshin to dólògbé?
- "Mo ti pa ọmọdé mẹ́wàá, mo sì ń mu ẹ̀jẹ̀ wọn"
- Agbébọn jí ìbejì ọba gbé àti èèyàn mẹta míì ní Kwara
- Àlàyé rèé lórí ohun tí ojú mi rí ní àhámọ́ - Chiwetalu Agu
- Mompha pàdánù èròjà olówó ìyebíye mọ̀kànlá sọ́wọ́ EFCC
- Ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ ràn mí lọ́wọ́ ló fi ìlọ̀kulọ̀ lọ̀ mí, àyàfi Dudu Heritage nìkan
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
Bakan naa lo ni ifẹ tawọn ọmọ Naijiria ni si Buhari yii wọ to bẹẹ gẹ, ti ko si asaaju kankan tẹlẹ ni Naijiria tabi ninu ẹya kọọkan ti wọn nifẹ rẹ bii Buhari to wa lori aleefa yii.
Ninu awọn ti Adesina ni wọn ko ni okiki ati ẹran ifẹ lara to aarẹ Buhari ni Obafemi Awolowo, Nnamdi Azikwe, Sheu Shagari, Aminu Kano to fi mọ MKO Abiola.
Afenifere ni ọmọ ọsan to n ko ponpo ba iya rẹ ni Femi Adesina:
Nigba to n fesi si ohun ti Femi Adesina sọ naa, ẹgbẹ Afenifere ni Adesina sọrọ yii lati mu ki awọn araalu tubọ se odiwọn isesi ati ijọba Buhari ni.
O ni ọmọ ọsan to n ko ponpo ba iya rẹ ni Adesina, ọrọ rẹ yii si lo le se okunfa sisọ oko ọrọ si aarẹ lati ọdọ awọn araalu.
Wọn wa sọ fun Adesina pe ero tuulu to n ri lasiko ti aarẹ n kọja naa ko jade lati ki kaabọ amọ wọn fẹ ko ri awọn ni ati iya nla to n jẹ wọn labẹ isejọba Buhari.
Wọn wa se apejuwe Femi Adesina pe iwa agabagebe lo n hu pẹlu bo se fi aarẹ Buhari we Awolowo, Azikwe atawọn asaaju miran nilẹ Naijiria.
Adesina n fi oorun we iku ni to ba fi Buhari we Awolowo ati Azikwe:
Ẹgbẹ itẹsiwaju ọmọbibi ilẹ Igbo lorileede Naijiria,Ohanaeze Ndigbo,ti bẹnu atẹ lu agbẹnusọ aarẹ Buhari, Femi Adesina, pẹlu bo ti ṣe ṣafiwe Buahri pẹlu awọn to ja fun ominira Naijiria.
Ohanaeze sọ pe afiwe yi da bi ẹni fi oorun we iku ati pe o dabi ki a fi Idi Amin ti Uganda we Winston Churchill ilẹ Gẹẹsi.
Akọwe ipolongo Ohanaeze, Mazi Okechukwu Isiguzoro to fi atẹjade yi sọwọ ni awọn wọnyi ko ṣe fi we pẹlu Buhari lọna kọna.
O ni o ṣeeṣe pe Adesina n san ọna ti iṣẹ ko fi ni bọ mọ lọwọ rẹ ni nitori pe Femi Fani Kayode ko ti darapọ mọ APC.
Atẹjade naa sọ pe ''Tọwọtọwọ la fi n ranti ipa ti Azikiwe, Awolowo ati awọn baba nla wa mi ko lati ri pe Naijiria di amuyangan nilẹ Afrika''
O fi kun pe ''Wọn ṣapa wọn laiṣe oju ṣaaju,lilo ipo ni ilokulo tabi yiyawo laini idi eyi taa mọ ijọba Buhari si lati ọdun 2015 to de ori oye''
Ohanaeze ni Adesina ko kuna wi pe Buhari ju awọn wọn yi lọ nitori ọrọ aje Naijiria dẹnu kọlẹ lẹmeeji labẹ akoso rẹ.
Ati pe ijọba Buhari lo sọ Naijiria di olu ilu awọn ti oṣi ohun iṣẹ ta julọ lagbaye.
Ẹgbẹ naa wa ni yatọ si Buhari, awọn olori ilẹ yi ṣaaju bi Awolowo ati Azikwe n sanna bi eto ẹkọ ọfẹ ati awọn ilana mi to mu ayedẹrun yoo ṣe rinlẹ lasiko wọn.
Wọn ni lai fabada, ki Adesina maṣe fi Buhari we awọn asaaju yii nitori apejuwe wọn yoo dabi ẹni fi iku we oorun ni.















