Sola Allyson: Wo ohun tí Sola Allyson sọ nípa Dudu Heritage olówó orí Bimbo Oshin tó jáde láyé

Oríṣun àwòrán, thesolaallyson
Gbajugbaja akọrin ẹmi, Sola Allyson ti darapọ mọ awọn ọmọ Naijiria to n ṣe idaro iku ọkọ Bimbo Oshin, iyẹn Ola Ibironke, ti ọpọ eeyan mọ si Dudu Heritage.
Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instagram rẹ lo ti ṣedaro oloogbe ọhun.
Sola sọ pe ọpẹlọpẹ Dudu Heritage ninu aye oun, ko ba si ẹni to n jẹ Sola Allyson lonii.
- Èmi tí wọ́n kọ́kọ́ pé ọkọ Bimbo kú gàn an ti di jálajála lórí ìròyìn burúkú náà- Jaye Kuti, ọ̀rẹ́ Bimbo Oshin
- Ta ni Ola Ibironke, ọkọ Bimbo Oshin to dólògbé?
- Sunday Igboho kò tíì bọ́ lọ́wọ́ wa, á fi ẹ̀sùn míì kàn-án - Malami
- "Màálù tó ya sójú pópó kọlu ọ̀kadà ọmọ mí, tó sì kú ní ìkómọ ọmọ rẹ ku ọ̀la"
- El-Rufai fẹ́ kó jàndùkú wọ apá Gúúsù ló jẹ́ kó tako òfin ìdaranjẹ̀ nígboro - Akeredolu
- Ọwọ́ Biola Fowosere tẹ afurasí olè tó kó fóònù àti owó rẹ̀
- Ìjọba ẹ má wòran, àjà ilé Aṣòfin tó ń jò le wó lé wa lórí - Aṣòfin sọ̀rọ̀ ṣókè!
- Ọ̀run yóò ya bọ́ tí ààrẹ kò bá wá láti ẹ̀kùn gúúsù Nàíjíríà - Joe Igbokwe
- Wo èèwọ̀ mẹ́wàá to fi lè bọ́ lọ́wọ́ ewu iná gáàsì
Akọrin ẹmi naa ṣalaye pe Dudu Heriage lo sọ ohun di gbajumọ lẹyin to gbe awo orin oun, "Eji Ewuro" jade lọdun naa lọhun.
O ni "Lẹyin ti mo wo ẹyin wo, o han gbangba pe eto Ọlọrun ni bi mo ṣe pade oloogbe naa."

Oríṣun àwòrán, thesolaallyson/Instagram
"Lootọ ni mo ti n kọrin nigba naa fun nnkan bii ọdun marundinlogun, ṣugbọn aye ti su mi, nitori nnkan ko lọ bo ṣe yẹ ko maa lọ."
"Mo pade Lanre to n ṣiṣẹ fun oloogbe nigba naa ninu ọkọ akero lati agbegbe Obalende si Ogba... wọn si fun ni iṣẹ lati kọ orin to wa ninu fiimu agbelewo Eji Ewuro, eyi ti Bimbo Oshin gbe jade."
Lootọ o wu mi ki n kopa ninu fiimu naa gẹgẹ bii oṣere, ṣugbọn wọn ni orin ni mo maa kọ.
Lẹyin ti mo kọ orin naa, ni Dudu Heritage sọ pe mo gbọdọ ṣe orin ọhun sinu awo ti awọn eeyan yoo maa gbọ laaye ara wọn.
Lati igba naa wa ni irawọ mi ti tan."
Sola sọ siwaju si pe, bo tilẹ jẹ pe awọn alabaṣiṣẹ Dudu Heritage ko fọwọ si igbesẹ naa, ṣugbọn o kọ si wọn lẹnu, o si ti oun lẹyin titi ti oun fi di ẹni ti aye n gbọ lonii.

Oríṣun àwòrán, thesolaallyson/Instagram
Gẹgẹ bii ohun ti Sola sọ, ọpọ awọn to gbiyanju lati ran oun lọwọ lasiko naa lo n fi ilọkulọ lọ oun, ṣugbọn ti Dudu Hertiage yatọ.
O ni "Ẹyin nikan ni ko fi ilọkulọ lọ mi bi awọn akẹgbẹ yin miran ṣe n ṣe, eyi to mu ki n yago fun wọn, eyi si jẹ ki n bu iyi fun yin pupọ."
"Ọlọrun lo yin lati jẹ ki irawọ mi buyọ, ti ọpọ eeyan si mọ mi si Sola Allyson, Eji Owuro lonii... mi o le gbagbe yin lailai."
Sola Allyson pari idaro naa pẹlu adura pe, ki Ọlọrun jẹ ki oloogbe naa ri aanu gba, lẹyin naa lo ni oun ko ni gbagbe oore ti Dudu Heritage se ninu aye oun titi lai.


















