Sabaa Akintola: Pẹ̀lú ẹsẹ̀ kan, mo le gun kẹ̀kẹ́, lúwẹ̀ẹ́ tàbí rán aṣọ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ dókítà

Àkọlé fídíò, Sabaa Akintola: Pẹ̀lú ẹsẹ̀ kan, mo le gun kẹ̀kẹ́, lúwẹ̀ẹ́ tàbí rán aṣọ pẹ̀lú ẹ̀kọ́ dókítà

Yoruba ni ẹni ti yoo ga, ẹsẹ rẹ yoo tiirin, bẹẹ ni ọrọ ri fun akẹkọbinrin kan, Sabaa Akintola, to n kẹkọọ nipa imọ isegun nile iwosan UCH nilu Ibadan.

Sabaa, ti wọn ti ge ẹsẹ rẹ osi nigba to wa ni ọmọ ọdun mẹrin ni ọmuti kan lo kọlu oun niwaju sọọbu iya oun, eyi to run egungun ẹsẹ oun.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, akẹkọọbinrin naa ni ọpọ ipenija ati idẹyẹsi ni oun ri ni kekere nitori bi wọn se ge ẹsẹ oun amọ eyi ko di oun lọwọ lati kawe de ibi giga.

Sabaa, to n kẹkọọ nipa itọju eyin ni oun n lo ayederu ẹsẹ lati rin, ti ko si si ohun ti ohun ko le se gẹgk bi awọn abarapa yoku.

O fikun pe oun le ran asọ, oun le wa kẹkẹ, ti oun si tun n luwẹ pẹlu, yatọ si pe oun jẹ akẹkọ imọ isegun oyinbo.

Obinrin naa wa gba awọn eeyan to ni ipenija ara nimọran lati mase ri gbedeke kan nipa ohun ti wọn le se nitori pe wọn ni ipenija ara.