Bose Okeowo: Àárẹ̀ kékeré ló sọ mi dí aláàbọ̀ ara yìí ṣùgbọ́n...
Mi kò kọ́ iṣẹ́ ayaworan yii, funra mi ni mo kọ ara mi niṣẹ- Bose Okeowo
Bose Okeowo to jẹ akanda ẹda to n yaworan ni BBC ba lalejo bayii.
Bose salaye ni kikun ohun to sọ ohun di alaabọ ara.
Koda, o menuba ibanujẹ ti ipenija yii ti funun ko to di ayaworan ti igba oju n mọ bayii.
Bose ni oun ko kọ iṣẹ ayaworan nibikibi bikoṣe pe ẹbun Olorun lo jẹ.
O sọ bi oun ṣe nifé lati maa ya awón eeyan pataki lawujọ nitori pe iṣẹ aworan yiya naa ti sọ oun di ẹni pataki.

Bose Okeowo gba awọn akanda bii tirẹ nimọran pe ki wọn tẹpa mọṣẹ, ki wọn ṣawari talẹnti ti Olorun fun wọn, ki wọn si ṣamulo ẹbun won.
Grace Okeowo ati Okeowo Oladeji to jẹ iya ati baba Bose Okeowo naa ba BBC Yoruba sọrọ.
Koda, Oba ilu Ọtun naa gboriyin fun Bose pe ko jẹ ki aabọ ara dii lọwọ lati gbe ogo ara rẹ ga.
- Sanwo-Olu buwọ́lu ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún Eko ṣe lẹ́yìn rògbòdìyàn EndSARS
- Bí àwọn kan tí ń ní àtimọ̀lé tí wọ́n sọ olorin Nazir sí ní Kano ni ọwọ́ kan òṣèlù ní àwọn mii ní...
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
- Èèyàn 223 míràn ló lùgbàdì coronavirus ní Nàìjíríà lánàá
- 'Èmi Oluwatoyin Abosede Aya Kolawole Ajeyemi ń sọ fún yín pé mo ti dé "bus stop" sinimá lọ́dún yìí'



