Kabex End SARS: Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó làmìlaaka tó wáyé nínú oṣù Kẹ́wàá ọdún 2020

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @thecableng

Oṣu kẹwaa ọdun 2020 jẹ oṣu kan ti ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ko lee gbagbe ninu itan nitori awọn iṣẹlẹ to waye ninu oṣu ọhun.

Lara awọn iṣẹlẹ manigbagbe naa ree:

Iwọde #EndSARS

Iwọde EndSARS bẹrẹ lẹyin ti fidio kan fa ori ayelujara ya lọjọ kẹta, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, eyii to ṣafihan bi awọn ọlọpaa SARS ṣe yinbọn fun ọkunri na niwaju ile itura Wetland, to wa ni Ugheli, ni ipinlẹ Delta.

Iṣelẹ naa lo ta epo si ifẹhonuhan EndSARS lori ikanni Twitter.

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @thecableng

Ṣugbọn nigba ti iyẹn ṣi n lọwọ, ni iroyin kan tun jade pe awọn oṣiṣẹ SARS tun ti pa olorin takasufe kan to jẹ ọmọ ogun ọdun, ti orukẹ rẹ n jẹ Daniel Chibuike.

Lẹyin naa ni awọn eeyan bẹrẹ iwọde kaakiri awọn ilu nla ni Naijiria ati loke okun, ti wọn si n ke gbajare si ijọba apapọ pe ko fi opin ẹka ileeṣẹ ọlọpaa SARS naa.

Àkọlé fídíò, AbdulQudus Bello ṣàlàyé bí òun ṣe dí aláàbọ̀ ara nítorí pọpọ́ọ̀fù àti ìbínú jàǹdùkù àdúgbò

Igba to di ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020 ni iwọde ita gbangba bẹrẹ ni pẹrẹwu, ti ọpọ awọn gbajumọ ni Naijiria ati kaakiri agbaye si n sọ pe wọn fi ọwọ si iwọde ọhun.

Ifẹmiṣofo ni Lekki Toll Gate

Ni nnkan bi aago mẹfa abọ ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni awọn ẹṣọ alabo ṣina ibọn bolẹ fun awọn oluwọde to kọ lati fi iloro naa silẹ lẹyin ti ijọba ipinlẹ Eko ti kede ofin konile-o-gble oni wakati mẹrinlelogun.

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @jharmo

Olorin takasufe kan, Dj Switch ka iṣẹlẹ naa silẹ loju opo Instagram rẹ, to si sọ pe awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ogun lo ṣiṣẹ ibi naa, ṣugbọn ileeṣẹ ologun ti ni oun ko mọwọ mẹsẹ ninu iṣẹlẹ ọhun.

Jiji ounjẹ iranwọ Covid-19 ko

Lẹyin ti iwọde EndSARS gbọna mii yọ ni awọn janduku ja iwọde naa gba, ti wọn si bẹrẹ sii kọlu awọn ile ti ijọba ko ounjẹ iranwọ Covid-19 pamọ si.

Wọn ni o yẹ ki ijọba ti pin awọn ounjẹ naa, ṣugbọn wọn ko pa lati lu ni gbanjo.

EndSARS

Oríṣun àwòrán, @CDDWestAfrica

Awọn miran tun ṣakọlu si ọpọ agọ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko tilẹ sọ fun BBC pe ko din ni agọ ọlọpaa marundinlogun ti awọn janduku naa dana sun.

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat Protest: Òbí agbábọ̀ọ̀lù Gbenga Tiamiyu Kaka àtàwọn míì tí ọlapàá pa sọ̀r

Ikọlu gomina ipinlẹ Osun

Ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹwaa yii kan naa ni awọn janduku kan ṣakọlu si gomina ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola, nibi iwọde EndSARS ni ilu Osogbo.

Awọn janduku ọhun sọ oko, kondo atawọn ohun ija miran si gomina ọhun, ti awọn eeyan si farapa.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa lórí BBC Yorùbá: Mọ̀ síi nípa ẹ̀kún ìyàwó níbí

Awọn ẹlẹwọn salọ ni Edo

Igba ti iwọde EndSARS n lọwọ ni awọn janduku kọlu ọgba ẹwọn to wa ni opopona Sapele, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn silẹ.

Nnkan bi ẹgbẹrun meji ẹlẹwọn ni awọn janduku naa fun ni ominira, eyii to mu ki gomina Godwin Obaaseki kede igbele oni wakati mẹrinlelogun.

Igbohunsafẹfẹ Aarẹ Muhammadu Buhari

Lẹyin ti iwọde EndSARS ti bẹrẹ lọpọ eeyan kaakiri Naijiria ti n reti ki Aarẹ Muhammadu Buhari sọrọ soke ṣugbọn ko wi nnkan.

Ẹwẹ, lẹyin ti awọn ṣọja yinbọ fun awọn oluwọde ni iloro Lekki, ti gbogbo ọrọ si dojuru ni Aarẹ to sọrọ soke.

Àkọlé fídíò, Orlando Owoh: Èmí àti Oladipupo Owomoyela jọ lọ ẹ̀wọ̀n Alágbọn- Caroline Owoh, aya Orlando

Ṣugbọn o ṣeni laanu pe igbohunsafẹfẹ naa ko tẹ awọn ọmọ Naijiria lọrun nitori wọn ni ọkọ Aisha ko mẹnuba ohun ti wọn reti ko sọ.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ifakoko ṣofo lasan ni igbohunsafẹfẹ naa lawọn miran n sọ pe ki ṣe Aarẹ lo ṣe igbohunsafẹfẹ ọhun.