2021 Budget: Wo ìgbà márùnn ún tí Buhari ti rìnrin àjò lọ sókè òkun fún ìtọ́jú ara rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/Bashir Ahmad
Ẹ tun ile iwosan Aso Rock ṣe ki Aarẹ Muhammadu Buhari ye lọ soke okun lọ gbatọju mọ.
Igbimọ aṣofin agba l'Abuja to n ri ọrọ pinpin ipo ati ohun ini ijọba lai ṣegbe lẹyin ẹya kan lo sọrọ yii nigba ti wọn n jiroro lori eto iṣuna to le ni biliọnu kan naira ti ijọba ya sọtọ fun ile iwosan ileeṣẹ aarẹ.
Igbimọ naa ni ohun yoo buwọlu aba eto iṣuna naa ṣugbọn aarẹ Buhari ko gbọdọ lọ si oke okun lọ gba itọju mọ.
Wọn yii ni igba marun un ti Aarẹ Buhari ti lọ gba itọju nilẹ okeere.
- A kò ní gba ẹnikẹ́ni láàyè láti ṣe ìfẹ̀hónúhàn kankan mọ́ ní ìpínlẹ̀ Eko- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá kìlọ̀
- Nítorí pọpọ́ọ̀fù #200 ní Alaba ilé Sàlámàlékù ṣe da òróró gbígbóná sórí mi- Qudus
- A ó ṣèrànwọ́ fáwọn ẹbí ọlọ́pàá tó bá rògbòdìyàn EndSARS lọ láti inú N500m tí a yà sọ́tọ̀- Makinde
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- Sunny Ade (KSA) máa ń bá Orlando Owoh kó "Gloves" tó fi ń ja ẹ̀ṣẹ́ dání nígbà ayé rẹ̀- Folarin, àbúrò Orlando Owoh
Ọjọ karun un oṣu keji, ọdun 2016
Ni bi oṣu mẹjọ to bẹrẹ ijọba gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria, Aarẹ Buhari rinrin ajo lọ si ilu London lọjọ karun un oṣu keji ọdun 2016.
Atẹjade lati ileeṣẹ ijọba ṣalaye pe ọrọ ara Buhari lo mu gunle irinajo naa.
O pada si Naijiria lati irinajo naa lọjọ kẹwaa oṣu keji ọdun 2016.
Ọjọ kọkandinlogun oṣu kinni, ọdun 2017
Aarẹ Buhari mori le ilẹ Gẹẹsi lọjọ kọkandinlogun oṣu kinni, ọdun 2017.
Ileeṣẹ aarẹ sọ pe itọju ara rẹ lo mu ki aarẹ Buhari gunle irinajo ọhun si ilu Oba.
Ọjọ kẹwaa oṣu kẹta ọdun 2017 ni Buhari pada si Naijiria lẹyin to lo ọjọ mọkanlelaadọta lorilẹede UK.
Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an, ọdun 2017
Ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an ọdun 2017 ni Aarẹ Buhari gbera lati ilu London lọ si orilẹede Amẹrika.
Aarẹ rinrin ajo naa lati lọ gba itọju fun agọ ara rẹ.
Ọjọ mẹrin ni Buhari lo nilẹ Amẹrika ko to pada si ilu Abuja lọjọ kẹẹdọgbvọn oṣu kẹsan an ọdun 2017 .
Ọjọ kẹsan an oṣu kẹrin, ọdun 2018
Buhari fi orilẹede Naijiria silẹ lọ si ilẹ Gẹẹsi lọjọ kẹsan an oṣu kẹrin ọdun 2018.
Ọjọ mẹtala gbako ni Buhari nilẹ Uk ki o to pada wale lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹsan an ọdun 2018.
Ijọba ni isinmi ọlọdọọdun ni Aarẹ Buhari lọ fun nilẹ Gẹẹsi.
Buhari kopa ninu ipade awọn orilẹede to gbominira lati ọdọ ilẹ Gẹẹsi, bakan naa lo ṣe ipade pẹlu Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi Theresa May nigba naa.
Ọjọ kẹjọ oṣu karun un ọdun 2018
Aarẹ Buhari tun gbera lọ si ilẹ Uk lọjọ kẹjọ oṣu karun un ọdun 2018.
Iroyin to jade lati ileeṣẹ ṣalaye pe itọju ara lo mu ki Buhari rinrin ajo lọ si ilẹ okeere.
Ọjọ kọkanla oṣu karun ọdun 2018 ni Buhari pada si Naijiria lẹyin to gba itọju tan niluu London.

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR
Buhari, dẹ́kun à ti máa lọ sókè òkun fún ìtọ́jú, tún ilé ìwòsàn Aso Rock ṣe- Sẹ́nátọ̀
Ọmọ ile igbimọ aṣofin kan lati ipinlẹ Kaduna, Danjuma La'ah, ti rọ awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba lati sọ fun Aarẹ Muhammadu Buhari pe ko dẹkun ati maa lọ si oke okun fun itọju.
Aṣofin naa ni ki Aarẹ bẹrẹ si n lo ile ile iwosan to wa ni ile rẹ, iyẹn ni Aso Rock, to wa niluu Abuja to jẹ olu ilu Naijiria.
La'ah lo sọ ọrọ naa nigba ti akọwe ile Aarẹ, Tijani Umar gbe eto iṣuna ọdun 2021 lọ siwaju ile aṣofin naa.
- Mo ṣetán láti dojú ìjà kọ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bá ọ̀rọ̀ ajé Eko jẹ́- Sanwo Olu
- Bí àwọn kan tí ń ní àtimọ̀lé tí wọ́n sọ olorin Nazir sí ní Kano ni ọwọ́ kan òṣèlù ní àwọn mii ní...
- Wo àwọn ọmọ Naijiria mẹ́ta tó jáwé olúborí nínú ìdìbò sílé aṣòfin ilẹ̀ Amẹrika
- Sanwo-Olu buwọ́lu ìgbésẹ̀ ìjọba láti tún Eko ṣe lẹ́yìn rògbòdìyàn EndSARS
Ninu eto iṣuna ti Umar gbe lọ siwaju ile ọhun, ₦1.3 biliọnu ni wọn ya sọtọ fun ile iwossan to wa nile Aarẹ ninu eto iṣuna ọdun 2021 ti iye rẹ jẹ ₦19.7 biliọnu.
Nigba to n sọrọ lori eto iṣuna ọhun, ọgbẹni La'ah sọ pe ti Aarẹ atawọn oṣiṣẹ rẹ ba dẹkun ati maa lọ gba itọju loke okun, yoo rọrun lati tun ile iwosan to wa ni Aso Rock ṣe.
O ni igbimọ to n ri si eto iṣuna ọhun yoo buwọlu eto iṣuna ile iweosan to wa nile Aarẹ, ṣugbọn Aarẹ atawọn to sun mọ ọ gbọdọ dẹkun irinajo oke okun fun itọju.

Oríṣun àwòrán, @NGAuthentic
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni "Aarẹ wa kii ṣe ẹni to yẹ ki wọn maa gbe lọ soke ni gbogbo igba to ba n ṣaisan."
"O gbọgbọ maa gba itọju nilẹ yii, a si ni lati ri daju pe ijọba tun awọn ile iwosan wa ṣe."
Aṣofin naa fi kun pe awọn yoo maa ṣayẹwo ile iwosan Aarẹ ọhun lati ri pe gbogbo ohun to yẹ ko wa nibẹ ni wọn pese.
















