EndSARS: Makinde kéde ìrànwọ́ fáwọn ẹbí ọlọ́pàá tó bá rògbòdìyàn EndSARS lọ láti inú N500m tí a yà sọ́tọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde
Gbogbo awọn ẹbi ọlọpaa to ba rogbodiyan iwọde EndSARS lọ ni ipinlẹ Oyo la o ṣeranwọ owo fun.
Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo lo ṣeleri bẹẹ nigba to ṣabẹwo si olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa to wa niluu Ibadan lọjọ Aje.
Makinde sọ pe ninu ẹẹdẹgbẹta miliọnu naria ti ijọba Oyo ya sọtọ fawọn to fara kaasa ninu rogbodiyan ifẹhonuhan EndSARS ni ijọba yoo ti mu ṣe iranwọ fawọn ẹbi awọn ọlọpaa naa.
- Kàyééfì! Tọkọ taya kú lọ́jọ́ kan náà l'Abeokuta lẹ́yìn ìgbéyàwó ọdún méjìléláàdọ́rin 72
- Remilekun Fatolu bú sẹ́kún fún ohun tó ti pàdánù láyé torí ọyàn ńla rẹ̀.
- Èèyàn mọ́kànléláádọta ló wá láti ìpínlẹ̀ Eko nínú èèyàn 72 tó kó ààrùn covid-19 lọ́jọ́ Ajé
- 'Ṣọ́ọ́ṣì ni mọ ti ń bọ̀ kí n tó pàdé àwọn sójà tó fi abẹ gẹ irun fún mi'
- EndSARS, EndSWAT Protests: Òbí agbábọ́ọ̀lù Kazim Tiamiyu Kaka àtàwọn míì tí ọlọ́pàá pa sọ̀rọ̀, omijé bọ́ lójú
Gomina ipinlẹ Oyo rọ awọn ọlọpaa lati gbagbe ohun gbogbo to ṣẹlẹ ki wọn ṣiṣẹ pọ pẹlu ijọba lati rii wi pe alaafia jọba pada kaakiri ipinlẹ Oyo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
''Mi o fẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa ri iwọde EndSARS gẹgẹ bi ọna lati tako awọn agbofinro bi ko ṣe ọna lati rii pe awujọ wa dun un gbe ju ti bi o ti wa lọ,'' Makinde lo sọ bẹẹ.
Makinde ni ọna kan gbogi lati jẹ ki awọn araalu mọ pe ọrẹ ni ọlọpaa jẹ si wọn ni nipa ihuwa ọmọluabi lẹni iṣẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Gomina Makinde kẹdun pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa lori ọlọpaa marun un to ba iṣẹlẹ naa lọ ati ọlọpaa mejila to farapa nipinlẹ Oyo.
O ni ijọba ko ni da ọrọ naa dawọn ọlọpaa papaa julọ lori bi awọn janduku kan tun ti dana sun agọ ọlọpaa marun un.
Makinde ni ajumọṣe ijọba atawọn araalu ni idagbasoke awujọ.
Ninu ọrọ tiẹ, igbakeji ọga ọlọpaa agba, DIG Leye Oyebade to n ṣakoso iwọ oorun gusu rọ awọn ọlọpaa lati wa lojufo, ki wọn si ri pe alaafia jọba pada nipinlẹ Oyo.
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- US Election 2020: Ṣé èsì ìdìbò Ààrẹ Amẹrika yóò jáde lálẹ́ ọjọ́ ìdìbò?
- Ẹ dẹ̀kun lílo Sniper àti Dichlorvos fún ìtọ́jú oúnjẹ- NAFDAC kìlọ̀














