Lílo oògùn Sniper fún ìtọ́jú oúnjẹ leè yọrí sí ikú àìtọ́jọ́ - NAFDAC kìlọ̀

Oríṣun àwòrán, @DailyPostNGR
Ajọ to n mojuto ipese ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, ti kilọ fun awọn eeyan lati ṣora fun lilo oogun "Sniper" atawọn oogun miran to wa labẹ "Dichlorvos," DDVP, fun ṣiṣe itọju ounjẹ.
NAFDAC sọ pe lilo awọn oogun wọnyii fun itọju ounjẹ lewu gidi nitori o lee yọri si iku.
Adari agba NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye ni kii ṣe ohun to bojumu ki awọn oniṣowo maa fi Sniper ati DDVP ṣetọju awọn ounjẹ bii agbado, ẹwa ati ẹja gbigbẹ.
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ní Oyigbo lẹ́yìn tí ọlọ́páà mẹ́ta àti sọ́jà kú nínú rògbòdìyàn EndSARS
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni to ba ti to akoko kan ti awọn eeyan n fi awọn oogun yii ṣetọju ounjẹ o lee yọri si awọn aisan bii ara rirẹ, ori fifọ, igbẹburu, eébì, ati bẹẹ lọ.
O ni awọn aisan naa ti kan nipa fun ajọ NAFDAC lati gbẹsẹle ipese ati kiko awọn oogun ọhun wọ Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @TimiBlaze
Adeyeye fi kun ope NAFDAC ti fofin de aṣilo oogun naa atawọn oniṣowo to maa n kiri rẹ laarin ọja.
- Ènìyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abúlé Ẹ̀gbá, ní ìpínlẹ̀ Eko
- Ẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Adelé Ọba Alade Idanre ló rí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín òun àti Ọba Aroloye
- Oluwo ti ìlú Iwó kìí ṣe ẹgbẹ́ Àtaọjà Osogbo - Alaafin ìlú Ọ̀yọ́
- Ẹ̀yin ọlọ́pàá, ẹnikẹ́ni tó bá fi ọwọ́ kàn yín, ẹ dojú ìjà kọ ọ́ padà- Ọ̀gá Àgbá Ọlọ́pàá
O ni ajọ naa ti bẹrẹ ilanilọyẹ kaakiri Naijiria pẹlu ajọṣepọ awọn ileeṣẹ ti ọrọ kan lori ọna ti awọn eeyan le maa fi tọju ounjẹ ati ọja wọn lọna ti ko ni mu ewu lọwọ.
Adeyeye ṣalaye pe oogun apakokoro ti awọn ile nla ti wọn n ko ounjẹ pamọ sati awọn ohu ọsin si ni DDVP jẹ.
Ṣugbọn kii ṣe fun itọju gbogbo awọn ounjẹ ti wọn n ta nigboro ti awọn eeyan nb ra.













