Rivers Police:wọ́ ọlọ́pàá ti tẹ àwọn afurasí tó lọ gbin ǹkan abúgbàmù sí ṣọ́ọ̀ṣì bàbá gómìnà Wike

River State church bombing

Ijọba ipinlẹ Rivers ti fi panpẹ ofin mu eeyan meji kan toripe wọn lọ gbe nkan oloro abugbamu si ijọ baba gomina ipinlẹ naa, Nyesome Wike iyẹn Christian Church International.

Ijọ naa wa ni agbegbe Azikiwe, opopona Mile 2 Diobu niluu Port Harcourt.

Nigba ti ile iṣẹ iroyin BBC ṣebẹwo si agbegbe naa, ikọ ọlọpaa to nimọ nipa ado oloro yẹ ayika ṣọọṣi naa wo bẹẹ si ni awọn ẹṣọ alaabo wa nibẹ wamuwamu.

Àkọlé fídíò, Ọkùnrin tó fẹ́ fipábámilòpọ̀ fín ǹkan sí mi lójú ló ṣe rọ́nà wọlé sí mi lára

Gẹg bi iroyin to tẹ wa lọwọ, iṣẹlẹ naa waye lalẹ ọjọ Abamẹta, ṣe ni awọn ọmọ ijọ sa asala fun ẹmi wọn ti ẹnikẹni ko si farapa.

Awọn ọdọ adugbo naa lo wa gba ọdọ meji, afurasi ti wọn ni gbe ohun abugbamu naa kalẹ ki awọn ọlọpaa to de.

Nibayii, ikọ alaabo ti gba gbogbo agbegbe naa kan ti wọn ko si fun eeyan tabi ọkọ kankan laye lati gba ibi ti nkan ti ṣẹlẹ yii kọja.

Àkọlé fídíò, Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Èmi kọ́ ló pàṣẹ fún àwọn sọ́jà láti máa pa èèyàn ní Oyigbo - Nyesom Wike

Wike

Oríṣun àwòrán, @Wike

Gomina Nyesom Wike sọ pé òun kọ́ ló rán àwọn sọ́jà láti má a pàáyàn ni Oyigbo

Gomina ipinlẹ Rivers, Nyesom Wike, sọ pe oun kọ lo ran awọn sọja láti lọ paayan ni Oyigbo.

Lori amohunmaworan ileesẹ kan l'abẹle, lo ti sọ bẹ ẹ, nitori bi iroyin ṣe n lọ kaakiri pe awọn sọja n pa araalu nijọba ibilẹ Oyigbo, ti gomina kede àṣẹ konile-o-gbele fun, lati ọjọ mejila sẹyin.

Ikede naa waye lẹyin ti àwọn afurasi ọmọ ẹgbẹ to n polongo fun idasilẹ orilẹ-ede Biafra, IPOB, já iwọde EndSars gba, eyi to yọri si iku sọja mẹfa, ati ọlọpaa mẹta.

Koda, wọn dana sun agọ ọlọpaa mẹta ni agbegbe naa.

Saaju ni Wike ti buwọlu àṣẹ kan, to fi fofin de ẹgbẹ IPOB nipinlẹ Rivers, to si pasẹ fun awọn alaga ijọba ibilẹ, ati awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati wa gbogbo ọmọ ẹgbẹ IPOB nipinlẹ naa jade, lati fi oju wina ofin nile ẹjọ.

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa lórí BBC Yorùbá: Mọ̀ síi nípa ẹ̀kún ìyàwó níbí

Gomina Wike ni nkan ti oun sọ ni pe ki awọn eleto aabo ri i daju pe wọn fidi ofin to de IPOB mulẹ, ati lati ri i pe ko si ikorajọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Rivers.

Wike sọ pe o rọrun fun wọn lati fi Oyigbo boju ṣe ikọlu, nitori pe o sunmọ ipinlẹ Abia.

"Isọkusọ ni bi awọn eeyan ṣe n sọ pe mo ran awọn sọja jade lati pa awọn eeyan ẹ̀yà Igbo.

Ṣe emi ti mi o l'agbara lati pasẹ fun ọlọpaa, ni ma a pasẹ fun sọja?

Bakan naa ni ileesẹ ologun ti ṣẹ́ lori iroyin to sọ pe awọn sọja n lọ lati ojule si ojule, lati pa eeyan.

Agbenusọ fun ìpín Kẹfa ileesẹ ologun to wa nilu Port Harcourt, Ọgagun Charles Ekeocha, sọ fun ileesẹ Radio Nigeria pe lootọ ni oun mọ pe awọn ni àkànṣe isẹ ni Oyigbo, sugbọn irọ ni pe awọn kọlu awọn

eeyan.

O ni "Ko ṣe e ṣe fun wa lati deede kọlu awọn eeyan. Nigba ti ẹ ba de ibẹ lẹ o mọ boya irọ tabi òótọ́ ni iroyin tẹ n gbọ nita"

Àkọlé fídíò, EndSars, EndSwat Protest: Òbí agbábọ̀ọ̀lù Gbenga Tiamiyu Kaka àtàwọn míì tí ọlapàá pa sọ̀r

Sugbọn awọn eeyan kan to n gbe ni Oyigbo ti sa kuro nibẹ, nitori ibẹru pe ewu wa fun ẹ̀mí awọn, ati nitori isede ti ko jẹ ki wọn o raaye jade ṣe ohunkohun lati ọsẹ kan sẹyin.

Monday Bakor, to n gbe ni Oyigbo, sọ fun BBC Pidgin pe ọwọ rẹ ni iyawo afẹsọna rẹ, Queen Nwazuo kú si, lẹyin ti ọta ìbọn fọ́ ilẹkun irin to wa lẹnu ọna sọọbu wọn, ti wọn ti pa mọ ara wọn nitori bi ìbọn ṣe n

dun.

O sọ pe oju ẹsẹ lo ku.

Ẹlòmíì, Bani Jackreece sọ pe ni nkan bi aago mẹrin idaji ni oun raaye salọ lọjọ Aiku, ọjọ kinni, oṣu Kọkanla, nitori ibẹru ẹ̀mí oun, ati bi oun ko ṣe raaye ra oúnjẹ tabi gba owo ni banki.

Ọpọlọpọ awọn ẹgbẹ lo si ti kesi ipinlẹ Rivers, lati fi opin si isede ni Oyigbo, ki awọn eeyan le jade ra oúnjẹ.

Ọkọ ti wọn jo ni Oyigbo, Port Harcourt

Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ní Oyigbo lẹ́yìn tí ọlọ́páà mẹ́ta àti sọ́jà kú nínú rògbòdìyàn EndSARS

Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ní Oyigbo lẹ́yìn tí ọlọ́páà àti sọ́jà kú nínú rògbòdìyàn EndSARS

Ninu ibẹru lawọn eeyan to n gbe ni ijọba ibilẹ Oyigbo nipinlẹ Rivers atawọn olokowo nibẹ wa bayii lẹyin eto aabo to mẹhẹ nibẹ.

Lọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa to lọ yii ni ijọba ipinlẹ kede ofin konle o gbele nijọba ibilẹ Oyigbo atawọn ibomiiran niluu Port Harcourt lẹyin tawọn afurasi ọmọ ẹgbẹ IPOB da rogbodiyan silẹ nibi iwọde EndSARS.

Agọ ọlọpaa meta ni wọn dana sun, koda awọn janduku ọhun tun sọ ina si ileẹjọ to wa ni Oyigbo.

Ọlọpaa mẹta atawọn sọja ṣagbako iku ninu rogbodiyan naa.

Gomina ipinlẹ Rivers, Nysome Wike wọgile ofin isede lawọn agbegbe kan niluu Port Harcourt lọjọ kejidinlọgbọn oṣu kẹwaa ṣugbọn eyi ko kan ijọba ibilẹ Oyigbo.

Àkọlé fídíò, John Amanam: Ìfẹ́ tí mo ní sí àbúrò mi ló sọ mi dí ẹni tó ń ṣe 'Prosthetic' báyìí

Ṣugbọn lati Ọjọru ọsẹ to lọ ni ọpọ araalu ti n kuro ni Oyigbo lẹyin tawọn agbofinro bẹrẹ si ni kaakiri lati rii pe ofin konle-o-gbele to wa lode mulẹ.

Charles Akah to n gbe ni Oyigbo sọ pe inu ile loun wa lati ọjọ kọkanlelogun oṣu kẹwaa ti ijọba ti kede ofin konle-o-gbele nipinlẹ Rivers.

Awọn ero ni ibudokọ Port Harcourt

O ṣalaye pe awọn n sọja n mu awọn ọdọ kaakiri, eyi lo jẹ ki ọpọ maa bẹru lati jade nile.

''A o le lọ gbowo nita tabi ra ohun kankan, a n bẹ ijọba pe ki o wa nkan ṣe si ọrọ yii,'' Akah lo sọ bẹẹ.

Bani Jackreece ti oun naa n gbe lagbegbe Oyigbo sọ fun BBC pe laago mẹrin idaji loun sa kuro nile nitori ẹru n ba oun lori eto aabo to mẹhẹ nibẹ.

Ọkọ ọlọpaa ti wọn dana sun ni Oyigbo, Port Harcourt

Amọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, Nnamdi Omoni sọ fun BBC pe oun ko gbọ pe awọn agbofinro n mu awọn eeyan kan ni Oyigbo.

Omoni ṣalaye pe awọn agbofinro to n wọde ni ijọba ibilẹ naa lo jẹ ki alaafia maa jọba diẹdiẹ nibẹ bayii.

Akitiyan lati gbọrọ lẹnu Ọgagun agba Charles Ekeocha to jẹ olori ileeṣẹ olọgun 6 Division Nigerian Army ni Port Harcourt lori ẹsun pe awọn sọja n mu awọn araalu ni Oyigbo ja si pabo.