US election results: Wo ìdí márùn-ún tí Biden fi bórí nínú ìdìbò ààrẹ America

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lẹyin bi aadọta ọdun to ti lo nipo iṣakoso, to si ti n dafun tolo si ipo aarẹ America, ọwọ Jmoe Biden ti tẹ nkan to n wa.
Ipolongo ibo rẹ waye lọna ti ẹnikẹni ko fi ọkan si i, nitori ajakalẹ aarun Covid-19 to wa l'ode.
Amọ ni Biden ati igbimọ rẹ wa ọna lati bori awọn ipenija oṣelu, wọn si jawe olubori.
Nkan marun-un lo mu ki Biden, ọmọ alagbata ọkọ, lati Delaware, papa jawe olubori si ipo aarẹ
1. Covid, Covid, Covid
O ṣe e ṣe ko jẹ pe nkan gboogi to mu Biden bori , jẹ nkan to kọja agbara rẹ.
Ọrọ coronavirus , to pa eeyan to le ni 230,000, lo mu ayipada ba igbeaye ni America ati ọrọ oṣelu lọdun 2020. Koda, Donald Trump paapaa sọ pe bẹ ẹ ni nkan ri, lasiko to ku diẹ ki ipolongo ibo gbogboogbo wa sopin.
Ajakalẹ aarun naa, ati ipa to ni lara ọrọ aje, gbe Trump ṣubu lori ileri idagbasoke ati ọrọ to fi n polongo ibo.
O tun tu aṣiri iha ti ọpọ ọmọ ilẹ America kọ si iṣejọba rẹ, to kun fun aini afojusun, aibikita fun imọ sayẹnsi, fifi ọwọ yẹpẹrẹ mu eto ilu, ati gbigbe ọrọ osẹlu ga ju bo ṣe yẹ.
Alafo yii si ni ipolongo ibo Biden ṣe amulo rẹ.
2. Ipolongo ibo ti ko mu ariwo dani
Lati igba ti Biden ti n ṣe oṣelu, ni ọrọ ẹnu rẹ ti ma n ko si iyọnu, koda o ṣe akoba fun nigba to kọkọ gbegba ibo aarẹ lọdun 1987, ati ọdun 2007.
Bo tilẹ jẹ pe o tun sọ awọn ọrọkọrọ, lasiko yii, igbimọ ipolongo rẹ ri i daju pe ko kọja bo ṣe yẹ.
Wọn ri i daju pe ifarahan rẹ ni gbangba ko pọju, wọn fi alafo diẹdiẹ si ipolongo ibo, eyi to mu ki adinku ba aarẹ tabi isọkusọ to le fa wahala.
Ilana ti wọn lo yii mu ko jẹ pe Trump nikan ni ẹnu rẹ ṣe akoba fun - eyi to pada pé Biden.
3. Ko si ẹni ti wọn ko fẹ ẹ, yatọ si Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Koko ọrọ to gbajumọ ninu ipolongo Biden ni pe idibo naa wa fun "ijakadi fun ọkàn ilẹ America", ati anfaani lati mu opin ba rogbodiyan ati ipinya, to ti wa lati ọdun mẹrin.
Aṣiri to fi ara pamọ sinu kókó naa ni pe Biden fi ipilẹ aṣeyọri rẹ lelẹ lori pe ọwọ lile ni Trump fi n ṣe iṣakoso, nkan ti awọn eeyan ilẹ America si n wa ni adari ti yoo ma a ṣe jẹẹjẹ.
4. Ko ṣeku, ko ṣẹyẹ
Lasiko ipolongo lati di oludije fun ẹgbẹ osẹlu Democrat, awọn alatako Biden wa lati igun apa osi, pẹlu Bernie Sanders ati Elizabeth Warren. Ipolongo ibo wọn mi gbogbo ilu titi.
Amọ, lai fi ti bi awọn to faramọ ṣe n fun ogun mọ ọ lọrun lati dabi awọn alatako rẹ, Biden ko yi ilana rẹ pada - ko polongo eto ilera ti ijọba n gbọ bukaata rẹ, ẹkọ ọfẹ, tabi owo ori lori ọrọ ti eeyan ba ni.
Eyi mu ko lo anfaani ẹbẹ rẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Republican ti inu n bi, lasiko idibo gbogboogbo.
Ọna kan to ti ṣe bi awọn alatako rẹ, Sanders ati Warren, ni lori ọrọ ayika ati ayipada oju ọjọ - boya nitori a ti ri ibo lati ọdọ awọn ọdọ ti ọrọ naa jẹ logun, lai bikita fun pipadanu ibo ni awọn ipinlẹ ti ileeṣẹ pọ si.
5. Owo rẹpẹtẹ, iṣoro diẹ
Ni ibẹrẹ ọdun yii, owo ti fẹ ẹ tan ni apo ikọ ipolongo Biden.
O wọ inu ipolongo ibo aarẹ lai ni anfaani to Trump, to ti lo gbogbo asiko to fi wa nipo aarẹ lati gbaradi fun ipolongo saa keji.
Koda, o na to biliọnu kan dọla.
Amọ lati oṣu Kẹrin, ikọ ipolongo Biden yipada di eyi to n bẹbẹ fun ikowojọ - o si pada ni owo l'apo ju ikọ Trump lọ - boya nitori pe ikọ Trump n na owo ni inakuna.
Nigba ti yoo fi di ibẹrẹ oṣu Kẹwaa, ikọ ipolongo Biden ti ni to miliọnu mẹrinlelogoje dọla, $144m, ju ti Trump lọ.
Eyi si mu ko ṣe e ṣe fun lati fi ikede ori amohunmaworan bori Trump ni awọn ipinlẹ ti ijakade ti ma n waye.
Owo to wa lọwọ Biden mu ki ipolongo rẹ de ọdọ awọn oludibo daadaa, paapaa nitori pe coronavirus mu ki bi awọn eeyan ṣe n wo amohunmaworan ninu ile wọn o pọ si i.
US Election 2020: Nígbà wo laó mọ èsì ìdìbò àti pé ṣé ó ṣeé figagbága?

Lẹyin ti idibo aarẹ ba ti pari nilẹ Amẹrika, o lee to ọpọlọpọ ọjọ koda o lee to ọsẹ melo kan lati wadii boya Donald Trump tabi Joe Biden lo jawe olubori.
Ninu idibo yii, ọgọọrọ awọn ọmọ Amẹrika ti n dibo nitori arun coronavirus eyi to tumọ si pe o ṣeeṣe ki idiwọ wa ninu kika ibo naa.
Igba wo la maa n saba ri esi idibo Amẹrika?
Alẹ ọjọ idibo ni wọn maa n saba kede eyi to si jẹ pe ti ọdun yii, ọjọ Isegun ọjọ kẹta oṣu kọkanla ọdun 2020.
Asiko ọtọọtọ lawọn oniruuru ipinlẹ ma n pari idibo wọn.
Ibudo idibo akọkọ si maa n pari idibo wọn ni aago meje.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gbogbo kika ibo ko tii le pe tan lalẹ ọjọ idibo ṣugbọn dede ibo to to lati mọ ajaweolubori lo wa nibẹ.
Ẹwẹ ni ipele yii nigba ti wọn ba ti fẹẹ ka gbogbo ibo tan, iwoye ṣi ni ko tii di abajade esi gangan.
Ṣugbọn awọn ipinlẹ mii bii Pennysylvania ati Wisconcin kii gba ki wọn ka awọn ibo ti wọn ba tete di afi ni ọjọ idibo gangan.
Awọn ipinlẹ yii lee ṣe pataki to bẹẹ ti awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ti ni kika rẹ le to ọjọ melo kan.

Njẹ idibo alatẹjiṣẹ imeeli maa n ṣokunfa iwa ole ninu idibo?
O ṣeeṣe ki bi awọn ipinlẹ kan ṣe n ṣe eto idibo jẹ ki kika idibo naa ya.
Lawọn ipinlẹ to maa n duro de ọjọ idibo ki wọn to ka awọn idibo oni imeeli, o ṣeeṣe ko gbe aarẹ Trump tori ireti wa pe ọpọ ọmọ ẹgbẹ Republican yoo dibo lọlọdani lọjọ idibo.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bawo ni wọn ṣe n ka ibo?
Ọpọlọpọ iwe itẹka ibo yala loju koroju tabi lori ayelujara ni wọn maa n fi ẹrọ ka. Ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ni lati ka eyi ti ẹrọ o ba ri ka.
Bi idibo ba ti tan, o ni ibudo kan ṣoṣo ti wọn yoo ko gbogbo ẹ lọ. Kete ti gbogbo ibo ati kika ba ti le bara mu, yoo bẹrẹ si ni farahan loju opo eyi to jẹ ti orilẹede gangan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ki ni yoo ṣẹlẹ to ba di pe wọn o gba esi idibo yii tọwọ tẹsẹ?
Ajakalẹ arun Covid-19 ti baba fọwọ fa iṣẹlẹ ti wọn n fi ofin idibo to le ni irinwo yanju ẹ dani lawọn ipinlẹ mẹrinlelogoji.
Ẹwẹ, aarẹ Trump ti ni o ṣeeṣe ki esi idibo naa pada wọ ile ẹjọ giga julọ nilẹ Amẹrika.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lọdun 2000, oludije ẹgbẹ Democrat, Al Gore fidirẹmi ninu idibo aarẹ lẹyin eyi si ni gbọnmi si omi o to bẹ silẹ to le ni oṣu kan - ile ẹjọ giga julọ lo si pada dajọ ọhun to fi pada gbe lẹyin oludije ti ẹgbẹ Republic, George W Bush.
- Mọ̀ sí i nípa àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́sàn-án tó ń díje nínú ìdìbò ilẹ America lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun
- Wo ǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Joe Biden, tó ń kojú Trump nínú ìbò America
- Ǹkan tí a mọ̀ nípa kọ́lẹ̀jì olùdìbò tó ń fìdì ẹni ti yóò jẹ ààrẹ ilẹ̀ Amérika múlẹ̀
- Wo iye owó tí ìjọba Amẹrika ń na sí ìdìbò Ààrẹ àti ibi tí owó náà ti ń wá















